2021
Wíwá Okun láti Dáríjì
Oṣù Kẹfà 2021


“Wíwá Okun láti dáríjì,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2021, 10–11.

Wá, Tẹ̀lé Mi

Wíwá Okun láti Dáríjì

Olúwa ti pàṣẹ fún wa pé kí á dáríji àwọn ẹlòmíràn. Òun yíò ràn wá lọ́wọ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, pẹ̀lú èyí náà.

Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:10

Àwòrán
obìnrin ń wo ẹnìkan tó ńna ọwọ́ sí i

Àpéjúwe láti ọwọ́ James Madsen

Ǹjẹ́ àwọn òfin kan le láti pamọ́ ju àwọn míràn lọ?

Èyí ni ó ńdẹ́rùbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn: “Èmi, Olúwa, yíò dáríji ẹnití èmi yíò dáríjì, ṣùgbọ́n ní tiyín ó jẹ́ dandan láti dáríji gbogbo ènìyàn” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:10).

Dúró. A nílò láti dáríji gbogbo ènìyàn tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? Njẹ́ ìyẹn tilẹ̀ ṣeéṣe?!

Òhun kan ni láti dáríji ẹnìkan fún sísọ ohun àrífín sí yín tàbí fún gbígba ipò ìgbẹ̀hìn lórí tábìlì oúnjẹ alẹ́. Ṣùgbọ́n báwo niti àwọn ọgbẹ́ tó jìn? Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle tí ó lè dènà tàbí kí ó yí ọ̀nà ìgbésí ayé wa padà?

Nígbàmíràn àgbára làti dáríjì ẹnìkan tí ó ti pa wa lára gidi lè nímọ̀ kọjá okun wa.

Nihin ni ìròhìn ayọ̀ náà: Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jésù Krístì, kò sí òpin ní ohun tí a lè ṣe fúnra wa.

Ìrànlọ́wọ́ tí Ó nílò

Olùfọkànsìn Krìstẹ́nì kan láti Netherlands tí ó ńjẹ́ Corrie ten Boom kọ́kọ́ ṣe àwárí agbára ìbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti dáríjì ẹnìkan.

Wọ́n ti òun àti arábìnrin rẹ Besty mọ́lé ní àwọn ibùdó ìfọkànsíbìkan nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Corrie àti àwọn míràn farada ìlòkulò tó buru jáì láti ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Naṣi. Àní arábìnrin rẹ̀ Besty kú látàrí ìlòkulò. Corrie yè.

Lẹ́hìn ogun, Corrie ṣe àwárí agbára ìwòsàn ti dídáríji àwọn míràn. Ó má ńsábàá pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àwọn àgbékalẹ̀ gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ kan ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba àdánwò ìgbẹ̀hìn.

Títẹ̀lé ọ̀rọ̀ gbangba kan, ọ̀kan tó burú jù lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹ̀wọ̀n láti inú àwọn ibùdó kojú Corrie.

Ó sọ fún Corrie pé òun ti di Krísténì látì ìgbà ogun òun sì ti ronúpìwàdà kúrò nínú gbogbo ohun tí òun ti ṣe gẹgẹ bí olùsọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Ó nawọ́ rẹ̀ si ó sì wípé, “Ǹjẹ́ ìwọ ó dáríjì mí?”

Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ti kọ́ àti ohun tí ó ti pín nípa dídáríji ẹlòmíràn, síbẹ̀ Corrie kò lè gba ọwọ́ arákùnrin yìí kó sì dáríjì í—kò lè ṣe é fúnra rẹ̀, lọ́nàkọnà.

Lẹ́hìnnáà ó kọ wípé, “Àní bí ìrunú, èrò ẹ̀san ti ńgbóná nínú mi, mo rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. … Jésù Olúwa, mo gbàdúrà, dáríjì mí kí O sì rànmí lọ́wọ́ láti dáríjì í.

“Mo gbìyànjú láti rẹ́rìn, [àti] pé mo tiraka láti gbé ọwọ́ mi sókè. Èmi kò lè ṣe é. Èmi kò nímọ̀lára kankan, kódà kò sí àpẹrẹ ọ̀yàyà tàbí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ bí ó tiwù ó mọ. Àti pé lẹ́ẹ̀kansi mo mí èémí àdúrà ìdákẹ́jẹ́ kan. Jésù, èmi kò lè dáríjì í. Fún mi ní idáríjì Rẹ.

“Bí mo ṣe mú ọwọ́ rẹ̀ dání ohun alámì kan ṣẹlẹ̀. Láti èjìká mi lọ sí apá mi àti nípasẹ̀ ọwọ́ mi ni ohun kan kọjá láti ara mi lọ sí ara rẹ̀, nígbàtí ìfẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀ wọnú ọkàn mi fún àjèjì yí.

“Mo wá ri wípé kì í ṣe lórí ìdáríjì wa mọ́ ju lórí ìnúrere wa ni ìwòsàn ayé dúró lé, ṣùgbọ́n lórí Tirẹ̀. Nígbàtí Ó sọ́ fún wa pé kí á ní ìfẹ́ àwọn ọ̀tá wa, Ó fúnní, lẹgbẹ pẹ̀lú àṣẹ, ti ìfẹ́ fúnra rẹ̀.”1

Ọlọ́run wà níbẹ̀ láti rànwá lọ́wọ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, pẹ̀lú òfin láti dáríjì—àní nígbà tí ó sòro. Ó lè ràn yín lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ran Corrie ten Boom lọ́wọ́.

Ìwòsàn tí ó Tọ́ Síi Yín

Ayé jẹ́ ẹ̀tàn. Ó dọ̀tí. Ó sì tún kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìṣojúẹni tí Ọlọ́run fúnni.

Ní àwọn àkókò wọnnì nígbàtí ẹnìkan bá ṣe àṣàyàn tí ó fa ìrora lílé fún yín—tàbí àní tí wọ́n ṣèèṣì ṣe bẹ́ẹ̀—ẹ lè gba agbára ìwòsàn bí ẹ ṣe ńgbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtiraka láti dáríjì.

Dídáríji àwọn ẹlòmíràn nmú ìwòsàn bá ọkàn yín. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, bí ẹ ṣe ndáríji ẹnìkan tí ó ti ṣẹ̀ yín, ẹ ngbé àjàgà búburú kalẹ̀ tí ó lè máa dí yín lọ́nà kúrò ní èjìká yín. Àní nígbàtí ìpa ọ̀nà sí ìwòsàn òtítọ́ bá fẹ́ le, pẹ̀lú Ọlọ̀run, ẹ kò ní láti dá rìn ín láéláé.

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Corrie ten Boom, Ibi Ìfarapamọ́ (1971), 215.

  2. Jeffrey R. Holland, oṣù kẹwàá 2018 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ensign tàbí Liahona, Oṣù kọkànlá, 2018, 79).

Tẹ̀