2021
Jésù Krístì Fún Wa ní Oúnjẹ Olúwa
Oṣù Kẹfà 2021


“Jésù Krístì Fún Wa ní Oúnjẹ Olúwa,” Fríẹ́ndì, Osù kẹfà 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Osù kẹfà 2021

Jésù Krístì Fún Wa ní Oúnjẹ Olúwa

Lúkù 22–24

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Jésù mọ̀ wípé àkókò Òun ní ílẹ̀ ayé tí fẹ́rẹ̀ parí. Ó kó àwọn Àpóstélì Rẹ̀ jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa ó sì ní kí wọ́n má a rántí Òun nígbàgbogbo.

Jésù ní inú Ọgbà Gẹ́sthsémánì

Jésù lọ sí inú ọgbà láti gbàdúrà. A pa Á lara fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ohun ìbànújẹ́ nínú ayé gbogbo ènìyàn. Lẹ́hìnnáà Ó kú lórí àgbelèbú a sì sín sínú ibojì.

àwọn obìnrin bẹ̀ ibojì Jésù wò

Ní òwúrọ̀ Ọjọ́ ìsinmi lẹ́hìn tí Jésù kú, àwọn obìnrin kan wá sí ibojì. Wọ́n ti yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà kúrò, inú ibojì sì ṣófo! Níbo ni Jésù wà?

Jésù ńbá Màríà Magalénì sọ̀rọ̀

Ó wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi! Màríà Magalénì rí Jésù. Ó bẹ àwọn Àpóstélì Rẹ̀ wò kí wọ́n le gbáradì láti kọ́ ìhìnrere lẹ́hìn tí Ó bá ti padà lọ sí Ọ̀run.

ẹbí ńjẹ oúnjẹ Olúwa

Nígbàtí mo bá jẹ oúnjẹ Olúwa, mo nrántí Jésù. Mo rántí pé Ó wà láàyè Ó sì kú Ó sì jíǹde fún mi!

Kíkùn Ojú-ìwé

Àwọn Ẹbí Mi Ṣe Pàtàkì

àwọn ẹbí lórí tábìlì oúnjẹ alẹ́