“Kíni Olórí-ọ̀run?,” Làìhónà, Oṣù kẹfà 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù kẹfà 2021
Kíni Olórí-ọ̀run Jẹ́?
Bàbá Ọ̀run, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹni mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú èrèdí kanṣoṣo.
Olùkọ̀wé ìwé ìròhìn kan bèèrè lọ́wọ́ Wòlìí Joseph Smith nipa ohun tí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù kristi ti Àwọn Èniyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gbàgbọ́. Ní ìdáhùn, Wòlíì kọ àwọn gbólóhùn mẹ́tàlá ìgbàgbọ́ tí a pè ní àwọn Nkan Ìgbàgbọ́. Gbólóhùn àkọ́kọ́ ní, “A gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Baba ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti nínú Ẹ̀mí Mímọ́” (Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:1). Àwọn mẹ́ta wọnyí ni wọ́n di ohun tí à npè ní Olórí-ọ̀run.
Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé
Ọlọ́run ní ẹ̀ran ara àti egungun tó jínde. Òun ni Baba àwọn ẹ̀mí wa. Ó fẹ́ràn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ rẹ̀ ní pípé. Ọlọ́run jẹ́ pípé, Ó ní gbogbo agbára, Ó sì mọ ohun gbogbo. Ó jẹ́ olóòótọ́, aláàánú àti onínúrere. À ńgbé bí àwọn ẹ̀mí pẹ̀lú Ọlọ́run kí á tó bí wa. Ó ránwa wá sí ilẹ̀ ayé láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti dàgbà. Ìfẹ́ Ọlọ́run títóbijùlọ ni fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀ láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ lẹ́kànsi lẹ́hìn tí a bá kú. Ọlọ́run kọ́wa pé a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé Jésù Krístì láti padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Jésù Krístì
Jésù Krístì bákannáà ní ara ẹran àti àwọn egungun tó jínde. Òun ni Àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run. Kí á tó bí wa, Ọlọ́run yàn Án láti jẹ́ Olùgbàlà wa. Èyí túmọ̀ sí pé Jésù wá sí ayé láti jẹ́ àpẹrẹ fún wa, kọ́ Ìhìnrere Rẹ̀, ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó sì gbàwá lọ́wọ́ ikú. Nítori Jésù Krístì, a lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nígbàtí a bá ronúpìwàdà. Jésù Krístì jìyà bákannáà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà kí Ó ba a le ni ìmọ̀ àti rànwálọ́wọ́. Jésù Krístì kú ó sì tún wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi, Ó nmú kó ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn láti wà láàyè lẹ́ẹ̀kansi.
Ẹ̀mí Mímọ́
Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Olórí-ọ̀run kan tí kò ní ara tí a lè fojúrí. Ó jẹ́ ẹ̀mí kan. Ẹ̀mí Mímọ́ lè sọ̀rọ̀ tààrà pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí wa. Ó jẹ́ ẹ̀rí fún wa wípé Ọlọ́run dájú àti wípé Jésù Krístì ní Olùgbàlà wa. Ẹ̀mí mímọ́ dúró gẹ́gẹ́ bí olùránṣẹ́ Ọlọ́run láti fún wa ní ìmọ̀lára ìfẹ́, ìtọ́nisọ́nà àti ìtùnù. Nígbà tí a bá ṣe ìrìbọmi tí a gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀, a gba ẹ̀bún Ẹ̀mí Mímọ́. Lẹ́hìn ìrìbọmi wa, Ẹ̀mí Mímọ́ lè dúró pẹ̀lú wa nígbàgbogbo bí a ṣe npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.
Ìran Àkọ́kọ́ Joseph Smith
Ní ìgbà pípẹ́ àwọn ènìyàn ti ní ìdàmú nípa Olórí-ọ̀run. Àwọn ènìyàn ti ṣe àìgbà nípa ohun tí Ọlọ́run, Jésù Krístì, àtí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́. Ìdí kan nìyí tí Ìran Àkọ́kọ́ tí Joseph Smith ní fi ṣe pàtàkì. Ó rí wípé Bàbá Ọ̀rún àti Jésù Krístì ní ara àti pé àwọn méjèèjì jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣùgbọ́n ní Ìṣọ̀kan
Àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòólì òdé-òní kọ́ wa wípé Ọlọ́run, Jésù Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú èrèdí kan: ayé iku àti ìyè àìnípẹ̀kun wa (wo Mósè 1:39). Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kannáà, Wọ́n nṣiṣẹ́ papọ̀ láti rànwá lọ́wọ́ lójoójúmọ́. A lè súnmọ́ Wọn nígbàtí a bá ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa tí á sì yan òótọ́.
Àwọn ìwé-mímọ́ nipa Olórí-ọ̀run
-
Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì jẹ́ ọ̀kan ní èrèdí (wo Jòhánù 10:30).
-
Ọlọ́run Baba sọ̀rọ̀ sí Ọmọ Rẹ̀ (wo Mátíù 3:16–17).
-
Jésù Krístì sọ̀rọ̀ sí Bàbá Rẹ̀ (wo Jòhánù 11:41).
-
Jésù Krísti gbàdúrà fún wa láti di ọ̀kan lọ́jọ́ kan (wo Jọ̀hánù 17:11).
-
Joseph Smith rí Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì (wo Ìtàn—Joseph Smith 1:17).
-
Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa (wo Jọ̀hánù 15:26).
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ètọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀pada-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Lìàhónà, Oṣù kẹfà 2021. Yoruba. 17470 000