“Oyè-àlùfáà Náà Jẹ́ Agbára Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́jọ 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù, Làìhónà Oṣù Kẹ́jọ 2021
Oyè-àlùfáà Náà Jẹ́ Agbára Ọlọ́run
Ọlọ́run nbùkún wa nípasẹ̀ agbára oyè-àlùfáà náà. Àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà wà fún gbogbo ènìyàn.
Oyè-àlùfáà jẹ́ agbára Ọlọ́run. Ó nlo agbára yi láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ àti láti rànwọ́nlọ́wọ́ láti padà lọ gbé pẹ̀lú Rẹ. Ọlọ́run ti fi agbára oyè-àlùfáà fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé. Pẹ̀lú agbára yí, àwọn olórí oyè-àlùfáà lè darí Ìjọ, àti pé àwọn olùdìmú oyè-àlùfáà lè ṣe àwọn ìlànà mímọ́, bíi ìrìbọmi, tí ó nrànwálọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọlọ́run síi. Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n fi yíyẹ gba àwọn ìlànà oyè-àlùfáà tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú mọ (àwọn ìlérí mímọ́) ní ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run.
A Fi Agbára Oyè-àlùfáà Fún Joseph Smith
Nígbàtí Jésù Krístì wà ní ayé, Ó darí Ìjọ Rẹ̀ pẹ̀lú agbára oyè-àlùfáà Ó fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ ní agbára yi pẹ̀lú. Ní àwọn ọgọrun ọdún lẹ́hìn tí wọ́n kú, ọ̀pọlọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ṣubú kúrò ní Ìjọ. Wọ́n yí ìhìnrere àti ọ̀nà tí Ìjọ fi ṣiṣẹ́ padà ní àìtọ́. Oyè-àlùfáà Ọlọ́run kò sí ní orí ilẹ̀ ayé mọ. Ní 1829, Jésù rán Jòhánnù onìrìbọmi àti àwọn Àpọ́stélì Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù láti fún Joseph Smith ní oyè-àlùfáà. Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ àkójọ kanṣoṣo ní orí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú àṣẹ yi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà
Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà jẹ́ àṣẹ láti darí ìlò oyè-àlùfáà, bíi irú fífúnni ní ìgbaniláyè láti ṣe àwọn ìlànà. Jésù Krístì di gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mu. Ààrẹ Ìjọ ni ẹ̀nikan ṣoṣo ní orí ilẹ̀ ayé tí o lè lo àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà láti darí gbogbo Ìjọ. Lábẹ́ ìdarí rẹ̀, àwọn míràn lè lo àwọn kọ́kọ́rọ́ kan pàtó láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn olórí bíi àwọn bíṣọ̀ọ̀pù àti ààrẹ èèkàn nlo kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà láti darí ní àwọn wọ́ọ̀dù àti èèkàn wọn. Nítorípé àwọn ìpè láti sìn nwá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ó nsìn ní àwọn ìpè nlo àṣẹ oyè-àlùfáà bí wọ́n ti nṣe àwọn ojúṣe wọn.
Oyè-àlùfáà Mẹ́lkìsédékì àti Oyè-àlùfáà Áárọ́nì
Oyè-àlùfáà pín si ipa méjì: Oyè-àlùfáà Mẹ́lkìsédékì àti oyè-àlùfáà Áárọ́nì. Nípasẹ̀ Oyè-àlùfáà Mẹ́lkìsédékì, àwọn olórí ìjọ ndarí gbogbo iṣẹ́ ti ẹ̀mí nínú Ìjọ, bíi iṣẹ́ ìhìnrere àti ti tẹ́mpìlì. Oyè-àlùfáà Áárónì nṣiṣẹ́ lábẹ́ àṣẹ Oyè-àlùfáà Mẹ́lkìsédékì. A nlo ó láti ṣe àwọn ìlànà bíi ìrìbọ́mi àti oúnjẹ Olúwa.
Àwọn Ìbùkún ti Oyè-àlùfáà
Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà, Ọlọ́run mú kí àwọn ìbùkùn oyè-àlùfáà wa ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí pẹ̀lú ìrìbọmi, ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́, oúnjẹ Olúwa, àti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì. Àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n ti gba ẹ̀bùn nínú tẹ́mpìlì gba ẹ̀bùn kan ti agbára oyè-àlùfáà Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wọn. Bákannáà a lè gba àwọn ìbùkùn oyè-àlùfáà ti ìmúláradá, ìtùnú, àti ìtọ́sọ́nà.
Kínni Àwọn Ìwé Mímọ́ Sọ nípa Oyè-àlúfàá?
Oyè-àlúfàá tí ó wà ní àwọn ọjọ́ wọnnì jẹ́ bákanáà pẹ̀lú èyí tí ó wà nísisìyí (wo Mósè 6:7).
Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlúfàá nṣèrànwọ láti ri dájú pé a ṣe àṣeparí iṣẹ́ Olúwa létòletò (wo Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:11).
Àwọn ọkùnrin tí wọ́n di oyè-àlúfàá mú lè lò ó “lórí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ òdodo nìkan” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:36).
Díẹ̀ nínu àwọn ojúṣe ti àwọn wọnnì tí wọ́n di oyè-àlúfàá mú ni a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:38–67.
© 2021 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀pada-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọrọ Oṣoòṣù Lìàhónà, Oṣù kẹrin 2021. Yoruba. 97925 779