2021
Oyè-àlùfáà Náà ti Ọlọ́run
Oṣù Kẹ́jọ 2021


“Oyè-àlùfáà Náà ti Ọlọ́run,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́jọ 2021, 20–21.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Kẹ́jọ 2021

Oyè-àlùfáà Náà ti Ọlọ́run

Ẹ̀kọ́ Àti Àwọn Májẹ̀mú 84

Ohun tí gbogbo ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa oyè-àlúfáà àti ìsopọ̀ wọn pẹ̀lú rẹ̀.

Àwòrán
ọ̀dọ́

Njẹ́ o ti kíyèsí bí o ti lè rúnilójú tó nígbàtí a bá lo ọ̀rọ̀ kan ní àwọn ọ̀nà méjì? Fún àpẹrẹ, ní Gẹ̀ẹ́sì ọ̀rọ̀ náà ilẹ̀ ayé ntọ́kasí méjèjì ìpín ayé tí à ngbé lórí rẹ̀ àti erùpẹ̀ abẹ́ àwọn ẹsẹ̀ wa. Méjèjì ni ó tọ́, ṣùgbọ́n ohun tí o ní lọ́kàn nígbàtí o bá lo ọ̀rọ̀ náà dá lórí ohun tí ìwọ nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní àkokò náà. Láti jẹ́ kí ó túbọ̀ rúnilójú sii, nígbàtí ilẹ̀ ayé túmọ̀ si ìpín ayé wa, bákannáà ó tún èrò inú ti erùpẹ̀, nítorípé erùpẹ̀ wà lórí ìpín ayé.

Síṣe Àsọyé Ọrọ̀ náà Oyè-àlúfáà

Ọ̀rọ̀ kan tí a nlò nínú Ìjọ ní ọ̀nà méjì ni oyè-àlúfáà. Ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí àpapọ̀ agbára àti àṣẹ Ọlọ́run. Sùgbọ́n, bákannáà a tún nlo Oyè-àlúfáà ni ọ̀nà tí ó ní òpin díẹ̀—láti tọ́ka sí “agbára àti àṣẹ tí Ọlọ́run fifún àwọn olùdìmú oyè-àlúfáà ti a ti yàn láti ṣe ìṣe nínú ohun gbogbo tí ó ṣe dandan fún ìgbàlà àwọn ọmọ Ọlọ́run.”1

Oyè-àlùfáà náà tí a fifún ọkùnrin kìí ṣe gbogbo agbára ti Ọlọ́run. Àwòrán-atọ́ka ti o tẹ̀lé ṣe àpèjúwe kókó yii.

Nínú àwòrán-atọ́ka yí ẹ rí àwọn àpẹrẹ ti agbára Ọlọ́run, èyítí kò lópin àti tí kò ní àwọn ààlà. Nínú èyínì, ẹ tún rí àwọn àpẹrẹ ti agbára àti àṣẹ ti oyè-àlùfáà Ọlọ́run tí O fifún, tàbí tí ó fún, àwọn ọkùnrin yíyẹ láti ṣiṣẹ́ nínú Ìjọ Krístì.

Àwọn Àpẹrẹ Àṣẹ Oyè-àlùfáà ninú Ayé Rẹ

Gbogbo àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà wà ní àrọ́wọ́tó fún gbogbo àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin ti Baba Ọrun. Àtòjọ kejì nírọ̀rùn dúró fún àwọn ìbùkùn wọ̀nnì tí ó nwá sí ọ̀dọ̀ yín nípasẹ̀ ẹni náà tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú tàbí tí ó ní àṣẹ oyè-àlùfáà tí a fifún un.

Èyí ni ètò tí Ọlọ́run ti fi múlẹ̀ fún ṣíṣètò àti ṣíṣe àmójútó Ìjọ Rẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé. Àwọn àpẹrẹ míràn ti àṣẹ oyè-àlùfáà Ọlọ́run pẹ̀lú ààrẹ iyejú àwọn díákónì tàbi àwọn olùkọ tí ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ láti darí iṣẹ́ iyejú rẹ, àwọn ìbùkún ti bàbá tí a fifúnni ní ilé, àti àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì.

Àwọn Ọkùnrin, Àwọn Obìnrin, àti Oyè-àlùfáà náà

Bíotìlẹ́jẹ́pé yíyàn sí ipò iṣẹ́ oyè-àlùfáà ni a fifún àwọn ọkùnrin nìkan, Ààrẹ Dallin H. Oaks, Olùdámọ̀ràn Àkọ́kọ́ ní Àjọ Ààrẹ Kínní, ti ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì kan: “Oyè-àlùfáà náà jẹ́ agbára àti àṣẹ àtọ̀runwá tí a dìmú ní ìgbẹ́kẹ̀lé láti lo fún iṣẹ́ Ọlọ́run fún èrè ti gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Oyè-àlùfáà kìí ṣe àwọn wọnnì tí a ti yàn sí ipò iṣẹ́ oyè-àlùfáà kan tàbí àwọn wọnnì tí wọ́n nlo àṣẹ rẹ̀. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n di oyè-àlùfáà náà mú kọ́ ni oyèàlùfáà. Kí a má ṣe tọ́ka sí àwọn ọkùnrin tí a yàn bí oyè-àlùfáà náà.2

Bíotìlẹ́jẹ́pé a kò yan àwọn obìnrin sí oyè-àlùfáà, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣàlàyé pé, “nígbàtí a bá yà yín sọ́tọ̀ láti sìn ní ipè lábẹ́ ìdarí ẹnìkan tí ó di kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú … a fún yín ni àṣẹ oyè-àlùfáà láti ṣiṣẹ́ ni ipè náà.”3 Àwọn àpẹrẹ díẹ̀ yí pẹ̀lú àjọ ààrẹ kílásì Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin, àwọn arábìnrin ìránṣẹ ìhìnrere tí wọ́n nwàásù ìhìnrere, àwọn olórí ní àwọn wọ́ọ̀dù àti èèkàn tí a ti yà sọ́tọ̀ láti dárí àti láti kọ́ni, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlànà nínú tẹ́mpìlì.

Agbára Oyè-àlùfáà Nbùkún Gbogbo Ènìyàn

Àwọn ìbùkún tí ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin gba jẹ́ tiyín nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú tí ẹ ṣe nígbà ìrìbọmi àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ ó ṣe nínú tẹ́mpìlì. Àní bí ẹ kò bá tilẹ̀ ní olùdìmú oyè-àlùfáà ninu ilé yín, ẹ ṣì lè di alábùkún pẹlu agbára oyè-àlùfáà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé yín bí ẹ ti npa àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti ṣe pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́ (wo 1 Néfì14:14).

Bí a ṣe ngbé ni ìbámu si àwọn májẹ̀mú wa, a ngba àwọn ìbùkún tí ó nfún wa lókun tí ó sì nbùkún wa. A pè yín láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà nínú ìgbésí ayé yín—àwọn ìbùkún tí ó nwá nítorí agbára àìlópin oyè-àlùfáà ti Ọlọ́run àti àwọn wọnnì tí wọ́n nwá ní pàtàkì nípasẹ̀ àṣẹ oyè-àlùfáà tí a fifúnni tí a sì fi ṣe aṣojú nínú Ìjọ Ọlọ́run.

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Dale G. Renlund àti Ruth Lybbert Renlund, Oyèàlùfáà Melchizedek: Níní òye Ẹ̀kọ́ náà, Gbígbé Àwọn Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ náà (2018), 11.

  2. Dallin H. Oaks, “Oyèàlùfáà Melkisédékì àti àwọn Kọ́kọ́rọ́ Rẹ̀,” Oṣù Kẹ́rin 2020 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ensign tàbí Làìhónà, Oṣù Kárùn 2020, 69).

  3. Ààrẹ Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ẹ̀mí,” oṣù kẹwàá 2019 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ensign tàbí Làìhónà, Nov. 2019, 78).

Tẹ̀