2021
Kíkọ́ Ara Rẹ Ní Dídára Jùlọ
Oṣù Kẹsan 2021


“Kíkọ́ Ara Rẹ Ní Dídára Jùlọ,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2021, 6-7.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Oṣù Ìkẹ́san 2021.

Kíkọ́ Ara Rẹ Ní Dídára Jùlọ

Àwọn ọ̀nà márun láti kọ́ ìgbé ayé ìdùnnú àti aláyọ̀.

Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 95:13-14

Àwòrán
Àwòrán ọ̀dọ́mọbìrin, ìsàmì tẹ́mpílì

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Juliet Percival

Nígbàtí Olúwa pàṣẹ fún Joseph Smith láti kọ́ Tẹ́mpílì Kirtland, Kò fi í sílẹ̀ láti wádìí ọ̀nà láti dá ṣe gbogbo rẹ fúnrarẹ̀. O fí ètò kan hàn tó ma yórí sí àṣeyorí.

“Jẹ́ kí ilé náà ó jẹ́ kíkọ́, kìí ṣe ni ọ̀nà ti ayé” ni Olúwa wí. “Jẹ́ kí ó jẹ́ kíkọ ní ọ̀nà náà èyítí èmi yíò fi hàn” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 95:13–14). Lẹ́hìnnáa Olúwa fúnni ní àwọn ìtọ́ni lóri bí a o ṣe kọ́ tẹ́mpílì náà (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 95:15–17).

Pẹ̀lú ìdúpẹ́, Olúwa ti fi hàn wá ju bí a ṣe nkọ́ àwọn tẹ́mpílì lọ. Bákannáà Ó ti fún wa ní àwọn ìtọ́ni láti rànwa lọ́wọ́ kí a di ẹni dídára jùlọ tí a lè dà. Bi à ṣe ntẹ̀lé wọn, a ó gbé àwọn ìgbé-ayé wa “kìí ṣe bíi ti àyé¨ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe.

Ní ìhín ni ọ̀nà márun láti kọ́ ìgbé ayé ìdùnnú àti aláyọ̀ tí ó dá lórí Jésù Krístì.

Ṣe Ìpìlẹ̀ tó Dájú

Gbogbo àwọn tí ó nyàwòrán ilé tàbí tí ó nkọ́lẹ̀ yíò sọ fún ọ pé ìpilẹ̀ tó dájú ṣe pàtàkì fún èyíkéyi ilé kíkọ́. Helaman kọ́ni pé ìpilẹ̀ tó dára jùlọ fún ìgbé ayé wa ní “àpáta Olùràpadà wa, ẹnití í ṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run” (Helaman 5:12). A lè fi Krístì ṣe ìpilẹ̀ wa nípa wíwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí a sì tẹ́lé àwọn ikọ́ni Rẹ̀. Báwo ni o ṣe nní ìmọ̀lara bí ó ti nṣe tó nípa fífi Krísti ṣe ìpìlẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀?

Sin Àwọn Ẹlòmíràn

Àwòrán
àwọn ẹsẹ̀

Ọ̀nà títóbi míran láti kọ́ ìgbé ayé wa, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùmọ̀ràn Ìkejì ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní-ìgbànáà ti sọ, nwá nígbàtí “à wà ní orí ẹsẹ̀ wa ní sísin Olúwa àti sísin àwọn wọnnì ní àyíká wa.”1 Nígbàtí o bá sin àwọn ẹlòmíràn, ò nṣe ohun tí Jésù ṣe ò sì nkọ́ láti dà bíi Rẹ̀ si. Ìwọ kì yíò bùkún ìgbé ayé àwọn ènìyàn tí ò nsìn nìkan, ṣùgbọ́n ìwọ náa yíò di alábùkúnfún bákannáà.

Dá Ìlànà-ìṣe Àdúrà àti Àṣàrò Ìwé-mímọ́ Léraléra Sílẹ̀

Àwòrán
àwọn ọwọ́ tó ngbàdúrà

Ọ̀nà míràn láti kọ́ ìgbé ayé ìdùnnú ni láti kọ́ ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì. Ọ̀nà nlá kan láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní nípasẹ̀ àdúrà àti àṣàrò ìwé mímọ́.

Ààrẹ Uchtdorf wípé “Láti fún ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, a nílò àkókò tó nítumọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nìkan. Fífi jẹ́jẹ́ dojúkọ àdúra àti àṣàrò araẹni ojojúmọ́… yíò jẹ́ ìdókòwò ọlọgbọ́n ti àkokò àti àwọn akitiyan wa láti súnmọ́ Bàbá wa Ọ̀run si.”2

Àdúrà jẹ́ ànfàní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa ní Ọ̀run. Ó mọ̀ wá, fẹ́ràn wa, ó sì nfẹ́ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa! Nígbàtí a bá gbàdúrà pẹ̀lú òtítọ́, tí a dúpé, tí a sì bèèrè àwọn ohun tí a nílò, Òun nfi etísílẹ̀ Ó sì ndáhùn ní ọ̀nà àti akokò Tirẹ̀.

Nígbàtí ó bá di ṣíṣe àṣàrò iwé-mímọ́, kò sí ọ̀nà kan pàtó tí ó tọ́ láti ṣe é. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé kí o ṣe é! Àarẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé, “Ìtẹ̀bọmi ojojúmọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì fún yíyè níti ẹ̀mí.”3 Lílo àkókò ní ojojúmọ́ nínú àwọn ìwé-mímọ́ yíò ran ọ́ lọ̀wọ̀, láìṣiyèméjì, láti kọ́ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ àti okun.

Yí Ararẹ Ká Pẹ̀lú Àwọn Tí Ó Ngbà Ọ́ Níyànjú Lati Ṣe Rere.

Àwòrán
ọmọdékùnrin na àwọn apá síta

Bàbá Ọrun nfẹ́ kí a sopọ̀ kí a sì kọ́ àwọn ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn—pàápàá ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́. A má nsábà ndi títúnṣe láti ipasẹ̀ àwọn tí à nbá lo àkokò. Bóyá wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ kí o yí ara rẹ ká pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí yíò ran ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere, pa àwọn òṣùwọ̀n Olúwa mọ́, àti kí o di ẹni rere si. Bákannáà o lè ran àwọn tí ó wà ní àyíká rẹ lọ́wọ́ láti ṣé irúkannáà. Èwo nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ló nbá ọ kọ́ ìpilẹ̀ rẹ lé ori òdodo?

Rí Ayọ̀ Nínu Kíkọ́ Ìpilẹ̀ Rẹ

Àwọn ọ̀nà míràn púpọ̀ wà tí o fi lè kọ́ ìgbé ayé rẹ láti ní agbára àti ayọ níti ẹ̀mí, nínú rẹ̀ ni lílọ sí ilé-ìjọsìn àti ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́, àti títẹ̀lé àmọ̀ràn àwọn wòlí alààyè.

Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí gbà iṣẹ́ àti àkókò. Nígbàgbogbo ni kíkọ́ àti ikẹkọ wà láti ṣe, ṣùgbón o kò níláti dá ṣeé. Olúwa yío ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bí o ti nṣe ìgbìyànjú dídára jùlọ rẹ láti kọ́ ìgbé ayé tí ó lè mú ìyárí bá ìwọ àti Òun àti tí yíò mú ayọ̀ wá fún ọ.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ráńpẹ́

  1. Dieter F. Uchtdorf, “Dídúró lójú Ọ̀nà Damascus,” Oṣù Kẹ́rin. 2011 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ẹ́sáínì tàbí Làíhónà, Oṣù Karun 2011, 76).

  2. Dieter. F. Uchtdorf, “Nípa Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jùlọ,” Oṣù Kẹwa. 2010, ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ẹ̀nsáìnì tàbí Làíhónà, Oṣù Kọkànlá. 2010, 21).

  3. Russell M. Nelson, “Gbọ́ Tirẹ̀,” Oṣù Kẹwa. 2020 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò (Ẹ̀nsáìní tàbí Làìhónà, Oṣu Karun 2020, 89).

Tẹ̀