2021
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò: Ìpàdé Ìjọ ní Gbogbo Ayé
Oṣù Kẹsan 2021


“Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò: Ìpàdé Ìjọ ní Gbogbo Ayé,” Làíhónà, Oṣù Kesan 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kesan 2021

Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò: Ìpàdé Ìjọ ní Gbogbo Ayé

A ma nfetísílẹ̀ sí àwọn wòlí àti àwọn olórí Ìjọ míràn ní ìgbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Wọ́n ma nkọ́ wa ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí a gbọ́.

Òde Gbàgede Ìpàdé

Ní Oṣù Kẹ́rin àti Ikẹwàá kọ̀ọ̀kan, Ìjọ ma nṣe àwọn ṣísẹ̀ntẹ̀lé ìpàdé kan tí à npè ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Àwọn olórí ma nkọ́ni wọ́n sì ma njẹ́ri nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ma nṣẹ́lẹ̀ ní Ìlú Salt Lake, Utah, Amẹ́ríkà, wọ́n gbé e sáfẹ́fẹ́ káàkiri gbogbo àgbáyé ní àwọn èdè tí ó lé ní ọgọ́ọ̀rin. A pe gbogbo ọmọ ìjọ àti àwọn ẹlòmíran tí ó ní ìfe síi láti wá fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ náà.

Inú Gbàgede Ìpàdé

Àwọn Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Àkọ́kọ́ ti Ìjọ

A ṣètò Ìjọ lábẹ́ àṣẹ nínú ìpàdé kan ní ọjọ́ kẹfà Oṣù Kẹ́rin, 1830 (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20). Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò àkọ́kọ́ ni a ṣe ní Ọjọ́ Kẹsàn Oṣù Kẹfà , 1830. Láti ìgbà náà, àwon ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ni a ti nṣe lábẹ́ ìdarí Àarẹ Ìjọ níbikíbi tí àwọn ọmọ ìjọ ti lè kórajọ. Ní àwọn ọdún 1840s, àwọn olórí bẹ̀rẹ̀ si ní ṣe ìpàdé àpapọ̀ lẹ́ẹ̀mejì ní ọdún.

Ààrẹ Nelson ní orí pẹpẹ

Bí A Ti Nṣe Ètò Ìpàdé Àpapọ̀ Ní Òní

Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú Àwọn Àpọ́stélí Méjìlá, àti àwọn olórí Ìjọ míràn ma nsọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ẹgbẹ́ Akọrin Àgọ́ ní Igun-mẹ́rin Tẹ́mpílì àti àwọn ẹgbẹ́ akọrin Ìjọ míràn pèsè orin. Ìpàdé àpapọ̀ kọ̀ọ̀kan ní abala ètò márun: mẹ́ta ní ọjọ́ Satidé àti méjì ní ọjọ́ Isinmi. Ní Oṣù Kẹrìn, abala kẹta wà fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ti Àlùfá Àrónì àti Mẹlkisẹ́dẹ́kì. Ní Oṣù Kẹwà, ó wà fún àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin.

Àwọn Ìkọ́ni àwọn Olórí

Ní àwọn oṣù tó ṣaájú ìpàdé àpapọ̀, àwọn olórí Ìjọ ngbàdúrà nípa ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́ni. Olúwa nmísí wọn láti mọ ohun tí ó yẹ kí wọ́n sọ. Wọ́n nkọ́ni ní òtítọ́ ìhìnrere wọ́n sì npé wá láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Bakannáà wọ́n njẹ́ri nípa Jésù Krístì wọ́n sì ngbà wá ní ìyànjú láti tẹ̀lé E.

Ìkẹ́ẹ̀kọ́ láti inú Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò

Ṣaájú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, a lè gbàdúrà láti gbọ́ ohun tí Ọlọ́run nfẹ́ kí a kọ́. Bí a ṣe nfetísílẹ̀ sí àwon ọ̀rọ̀, Ẹ̀mí yíò kọ́ wa ní àwọn ohun tí a níláti mọ̀. Lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ náà a wà lóri ChurchofJesusChrist.org, ní áàpù Ibi-Ìkowépamọ́ Ìhìnrere, àti nínu Láíhọ́nà. A lè ṣe àṣarò àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àdúrà láti kọ́ nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀.

Láti inú àwọn Ìwé-mímọ

Jésù Krístì kọ́ni pé kí a máa kórajọ papọ̀ léraléra (wo 3 Nẹ́fì 18:22).

Nigbatí àwọn ọmọ Ijọ bá jọ́sìn papọ̀, Olúwa yíò wà pẹ̀lú wọ́n. (wo Matteu 18:20).

Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọ ìjọ láti “kọ́ ara wọn kí wọ́n ó sì mú ara wọn dàgbà sókè¨ (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 43:8).

Bí àwọn ọmọ Ìjọ ṣe nfi ìgbàgbọ́ nínú Krístì hàn, Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe pàdé (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 44:2).