2022
Àwọn Ìwé-mímọ́: Ọrọ̀ Ọlọ́run
Oṣù Kẹfà 2022


“Àwọn Ìwé-mímọ́: Ọrọ̀ Ọlọ́run.” Liahona, Oṣù Kéje 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù Kéje 2022

Àwọn Ìwé-mímọ́: Ọrọ̀ Ọlọ́run

Àwòrán
Wòlíì Májẹ̀mú Láéláé kan nkọ̀wé

Wòlíì Májẹ̀mú Láéláé, láti ọwọ́ Judith A. Mehr

Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ àwọn ìwé mímọ́ tí a kọ ní pàtàkì láti ọwọ́ àwọn wòlíì. Àwọn ìwé mímọ́ njẹ́ri nípa Jésù Krístì wọ́n sì nkọ́ni nípa ìhìnrere Rẹ̀. Àwọn ìwé mímọ́ fún ìlò Ìjọ ni Bíbélì (èyítí ó ní Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Titun nínú), Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, àti Péálí Olówó Iyebíye.

Májẹ̀mú Láéláé

Májẹ̀mú Láéláé ni àkọsílẹ̀ àwọn ìṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ ní àwọn ìgbà àtijọ́. Ó ní àwọn ìkọ́ni àwọn wòlíì nínú bíi Mosè, Jóṣúà. Isáià, Jeremíah, àti Daníẹlì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kọ ọ́ ní àwọn ọgọgọ́rũn ọdún ṣaájú ìbí Jésù Krístì, pùpọ̀ àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé kọ nípa Rẹ̀.

Májẹ̀mú Titun

Májẹ̀mú Titun ṣe àkọsílẹ̀ ìbí, àyé kíkú, àwọn ìkọ́ni, àti Ètùtù ti Jésù Krístì. Bákannáà ó ní àwọn ìkọ́ni ti àwọn Àpóstélì Krístì àti àwọn ọmọẹ̀hìn míràn nínú. Májẹ̀mú Titun nrànwá lọ́wọ́ láti ní òye bí a ti lè gbé ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì lóni.

Àwòrán
Jésù Krístì nwàásù Ìwàásùn lórí Òkè

Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹrí Míràn ti Jésù Krístì

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ àkọsílẹ̀ ti àwọn ènìyàn kan tí wọ́n gbé rí ní àwọn Amẹ́ríkà àtijọ́. Ó ní àwọn ìkọ́ni láti ọwọ́ àwọn wòlíì nínú, kókó èrèdí rẹ̀ sì ni láti fi dá gbogbo ènìyàn lójú pé Jésù ni Krístì náà. Wòlíì Joseph Smith túmọ̀ rẹ̀ láti inú àwọn àwo wúrà nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run.

Àwòrán
Joseph Smith ngba ìfihàn

Joseph Smith Kékeré Ngba Ìfihàn, láti ọwọ́ Daniel A. Lewis

Ẹ̀kọ́ Àti Àwọn Májẹ̀mú

Ẹ̀kọ́ Àti Àwọn Májẹ̀mú kó àwọn ìfihàn tí a fifún Joseph Smith àti àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn míràn sínú. Àwọn ìfihàn nṣe àpèjúwe bí Ijọ Krístì ṣe di gbígbékalẹ̀. Bákannáà wọ́n kó àwọn ìkọ́ni ìhìnrere pàtàkì sínú nípa oyè àlùfáà, àwọn ìlànà ìhìnrere, àti ohun tí yío ṣẹlẹ̀ lẹ́hìn ayé yìí.

Péálí Olówó Iyebíye

Péálí Olówó Iyebíye ní àwọn ìwé ti Mosè àti ti Abrahámù nínú, ẹ̀rí ti Joseph Smith, àti Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ ti Ìjọ. Bákannáàó ní Joseph Smith—Matteu nínú, apákan ìyírọ̀padà ti Joseph Smith ní ti Májẹ̀mú Titun.

Síṣe Àsàrò Àwọn Ìwé-mímọ

Àwọn wòlíì ti kọ́ wa láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ní ojojúmọ́. Síṣe bẹ́ẹ̀ nrànwá lọ́wọ́ láti mú ìgbàgbọ́ wa lékún tí a sì wà ní sísúnmọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì síi. Bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú àdúrà, Ẹmí Mímọ́ yío rànwá lọ́wọ́ rí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa.

Àwọn Wòlíì Òde Òní

Nígbàtí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì ọ̀jọ́ òní bá sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹmí Mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ dàbí ìwé mímọ́. Àpẹrẹ èyí kan ni ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. A le ṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni láti inú ìpàdé àpapọ̀ nínú Liahónàti Oṣù Karũn àti Oṣù Kọkànlá

Àwòrán
Mósè nborí Sátánì

Mósè Bori Sátánì, láti ọwọ́ Joseph Brickey

Tẹ̀