2022
Má Bẹ̀rù—Olúwa wà pẹ̀lú Rẹ
Oṣù Kẹfà 2022


“Má Bẹ̀rù, Olúwa wà pẹ̀lú Rẹ,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Keje 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kéje 2022.

Má Bẹ̀rù—Olúwa wà pẹ̀lú Rẹ

Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2018.

Ẹrù kì í ṣe titun. Láti ìgbà àtijọ́, ẹ̀rù ti fi òdiwọ̀n sí ìwòye àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nínú Àwọn Ọba Kejì, ọba Syrià rán ọ̀wọ́ ogun kan láti mú àti lati pa wòlíì Elíṣà.

“Nígbàtí ìránṣẹ́ [Eliṣa] sì dìde ní kùtùkùtù, tí ó sì jáde lọ, wòó, ogun yí ilú náà ká pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun. Ìránṣẹ́ [Eliṣà] sì wí fún un pé, Áà, ọ̀gá mi! báwo ni àwa ó ṣe?” (2 Àwọn Ọba 6:15).

Èyí jẹ́ pé ẹ̀rù ló nsọ̀rọ̀.

“[Èlíṣà] sì dáhùn pé, “Má bẹ̀rù: nítorí àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn.”

“Eliṣa sì gbàdúrà, ó sì wípé, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, la ojú rẹ̀, kí òun le ríran. Olúwa sí la ojú ọ̀dọ́mọkùnrin náà; òun sì rí: àti, kíyèsíi, orí òkè náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun iná yíká kiri Èlíṣà.” (2 Àwọn Ọba 6:16–17).

A le ní a sì le má ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun iná ní rírán láti àwọn ẹ̀rù wa kúrò kí ó sì borí àwọn ẹ̀mí èṣù wa, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ náà ṣe kedere. Olúwa wà pẹ̀lú wa, ó nrò nípa wa, ó sì nbùkún wa ní àwọn ọ̀nà tí ó jẹ́ pé Òun nìkan ní ó le ṣeé.

Bí a bá fi ìyára ní ìgbẹkẹ̀lé nínú Olúwa àti àwọn ọ̀nà Rẹ̀, bí a bá kópa nínú iṣẹ́ Rẹ̀, a kò níi bẹ̀rù àwọn ohun ìgbàlódé ti ilé ayé tàbí kí a jẹ́ dídà láàmú nípasẹ̀ wọn. Olúwa nṣe ìṣọ́ lórí wa, Ó nṣe àníyàn fún wa, Ó sì ndúró tì wá.

Tẹ̀