2023
Ṣíṣe Ìtọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní
Oṣù Kẹsan 2023


“Ṣíṣe Ìtọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní,” Làìhónà, Oṣù Kẹsan 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kesan 2023

Ṣíṣe Ìtọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní

Àwòrán
Jésù nwo àwọn ènìyàn san

Ó Wo Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Sàn nínú Onírurú Àìsàn, láti ọwọ́ J. Kirk Richards, a kòlè ṣe ẹ̀dà

Àwa bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a ntẹ̀lé ìkọ́ni Olúwa láti ṣe ìtọ́jú àwọn wọnnì nínú àìní. À nṣe ìtọ́jú àwọn ẹlòmíràn nípa sísìn wọ́n, rírànwọ́n lọ́wọ́ láti di olùgbẹ́kẹ̀lé ara­ẹni, àti ṣíṣe àbápín ohun tí a ní.

Àpẹrẹ Jésù Krístì

Jésù Krístì fẹ́ràn, Ó tùni­nínú, Ó sì gbàdúrà fún àwọn wọnnì ní àyíká Rẹ̀. Ó “lọ káàkíri ní ṣíṣe rere” (Ìṣe àwọn Àpóstélì10:38). A lè tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa fífẹ́ràn títùni­nínú, sísìn, àti gbígbàdúrà fún àwọn wọnnì ní àyíká wa. A lè máa fi ìgbà gbogbo wá àwọn ọ̀nà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Àwòrán
ènìyán meji nrìn

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Ọ̀rọ̀ náà ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni à nlò nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nínú Ìjọ Olúwa láti júwe bí a ti nṣe ìtọ́jú ara wa. Àwọn olùdìmú Oyè-àlùfáà ni a yàn bí arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹbí nínú wọ́ọ̀dù tàbí ẹ̀ka. Àwọn arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ ni a yàn sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àgbà obìnrin. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ri dájú pé gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ ni à nrántí tí a sì ntọ́jú.

Àwòrán
Àwọn ènìyàn ngbin àwọn irúgbìn

Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Di Olùgbẹ́kẹ̀lé-Ara­ẹni

A lè ran àwọn ọmọ ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ láti di olùgbẹ́kẹ̀lé-ara­ẹni nípa gbígbà wọ́n níyànjú láti wá àwọn ojútùú ìgbà pípẹ́ títí sí àwọn wàhálà wọn. Nígbànáà a lè tì wọ́n lẹ́hìn bí wọ́n ti nṣe iṣẹ́ lórí àfojúsùn wọn. Wá ìwífúnni síi nípa ìgbẹ́kẹ̀lé-ara­ẹni nínú Làìhónà Oṣù Kẹsan 2023 Àtẹ̀kọ Àwọn Kókó Ìhìnrere.

Sísín Àwọn Ẹlòmíràn

Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà tí a fi lè sin àwọn wọnnì ní àyíká wa kí a sì ṣèrànwọ́ láti bá àwọn àìní ti-ara, ti-ẹ̀mí, àti ti ẹ̀dùn ọkàn wọn pádé. Kíkọ́ nípa àwọn ẹlòmíràn lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bí a ti le sìn wọ́n dáradára si. Bákannáà a lè gbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà láti mọ ohun tí a lè ṣe láti ṣèrànwọ́.

Àwòrán
àwọn ènìyàn nkó èso jọ

Pínpín Ohun Tí A Ní

A lè sin àwọn ẹlòmíràn nípa pípín ohun tí Ọlọ́run ti bùkún wa pẹ̀lú. Fún àpẹrẹ, a lé fúnni ní àwọn ẹbọ ọrẹ ààwẹ̀ láìṣahun tàbí kí á dáwó sínú àpò Irànlọ́wọ́ ẹ̀ka ìrannilọ́wọ́ Ìjọ. Bákannáà a lè sin nìnù ìletò wa àti àwọn ìpè nínú Ìjọ wa.

Àwọn Ojúṣe Àwọn Olórí Ìjọ

Bíṣọ́ọ̀pù nmojútó ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn wọnnì nínú àìní nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀. Ó lè lo owó láti inú àwọn ọrẹ àwẹ̀ láti ran àwọn ọmọ ìjọtí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn àìní lọ́wọ́. Àwọn olórí míràn, pẹ̀lú àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àtiti iyejú àwọn alàgba, nran àwọn ọmọ ìjọ lọ́wọ́ láti wá àwọn ohun èlò tí wọ́n lè lò láti bá àwọn àìní wọn pàdé.

Àwọn Ìtiraka Ìrannilọ́wọ́ Ìjọ

Ìjọ nran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ní gbogbo àgbáyé pẹ̀lú ìfèsí pàjàwìrì, àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìletò, áti àwọn ètò míràn bí irú omi mímọ́ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára. Láti kẹkọ síi, wo Dallin H. Oaks, “Ríran àwọn Òtòṣí àti Onírẹ̀wẹ̀sì Lọ́wọ́,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2022, 6–8.

Tẹ̀