“A Pè Wá láti Ṣe Rere,” Làìhónà, Oṣù Kẹfà 2024.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹfà 2024
A Pè Wá láti Ṣe Rere
À ngbé ìjọba Ọlọ̀run ga láti sin àwọn ẹlòmíràn, di ìmọ́lẹ̀ wa mú, kí a sì dúró fún òmìnira ẹ̀sìn.
Gideon mọ ẹ̀kọ́ èké nígbàtí ó gbọ́ ọ. Ó ti gbọ́ rí láti ẹnu Ọba Noah àti àwọn àlùfáà rẹ̀—àwọn àlùfáà tí “ọkàn wọ́n rú sókè nínú ìgbéraga” tí a sì “ntì wọ́n lẹ́hìn nínú ìwà ọ̀lẹ wọn, àti nínú ìwà ìbọ̀rìṣà, àti nínú ìwà àgbèrè wọn, nípasẹ̀ owó-òde ọba Noah ti a yàn lé orí àwọn ènìyàn rẹ̀” (Mòsíà 11:5–6).
Búburújáì, Ọba Noah ti pa wòlíì Abinadi ó sì wá láti pa Álmà àtì àwọn olùyípadà ọkàn rẹ̀ (wo Mòsíà 17; 18:33–34). Láti fi òpin sí irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀, Gideon búra láti dá ọba dúró, enití òhùn dá sí nítorí ìkógun ará Lámánì (wo Mòsíà 19:4–8).
Lẹ́hìnnáà, Gideon dá àwọn àlùfáà Noah lẹ́bi déedé fún gbígbé àwọn ọmọbìnrin Lámánì lọ. Ó ṣe àkíyèsí pé àsọtẹ́lẹ̀ Abinadi ní ìlòdì sí àwọn ènìyàn náà ti wá sí ìmúṣẹ nítorí wọ́n ti kọ̀ láti ronúpìwàdà. (wo Mòsíà 20:17–22.) Ó ṣèrànwọ́ láti gba àwọn ènìyàn Limhi là, tí wọ́n wà nínú ìgbèkùn sí àwọn ará Lámánì (wo Mòsíà 22:3–9).
Ní dídàgbàsi nísisìyí, Gideon dojúkọ ìgbéraga àti ìwà búburú papọ̀ nígbàkan bí òun ti dúró níwájú Nehor, enití ó mú àlùfáà àrekérekè wá sí àárín àwọn ènìyàn. Nehor tí “ó nṣe àtakò ìjọ-Ọlọ́run” tí ó sì ngbìyànjú láti darí àwọn ènìyàn náà ṣìnà. (Wo Álmà 1:3, 7, 12; bákannáà wo 2 Néfì 26:29.)
Lílo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí ohun ìjà rẹ̀, akọni Gideon kìlọ̀ fún Nehor fún ìwà ìkà rẹ̀. Ní ìbínú, Nehor kọlù ó sì pa Gideon pẹ̀lú idà rẹ̀. (Wo Álmà 1:7–9.) Báyìí ni àwọn ọjọ́ ti “ọkùnrin olódodo kan” tí ó ti “ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun dáradára ní àárín àwọn ènìyàn yí” (Álmà 1:13).
Àwọn ọjọ́ ìkẹhìn nínú èyí tí à ngbé fún wa ní àwọn ànfàní púpọ̀ láti bá Gideon dọ́gba bí “ohun-èlò kan ní ọwọ́ Ọlọ́run” (Álmà 1:8) nípa wíwà “nínú iṣẹ́ ìsìn” (Mòsíà 22:4) sí àwọn ẹlòmíràn, ní dídúró fún òdodo, àti kíkojú àwọn ẹ̀rù sí òmìnira wa láti jọ́sìn àti láti sin Ọlọ́run. Bí a ti ntẹ̀lé àpẹrẹ òtítọ́ ti Gideon, bákannáà a lè ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ìrẹ́pọ̀ nínú Ìṣẹ́-ìsìn
“Bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn [Olùgbàlà], à nwá láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn aladugbo wa káàkiri àgbáyé,” ni Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti wí. “Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ̀ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ìtara láti bùkún àwọn ẹlòmíràn àti láti ran àwọn wọnnì nínú àìní lọ́wọ́. A di alábùkún láti ní okun, ohun èlò, àti àwọn ìsopọ̀ káríayé tí a gbẹ́kẹ̀lé láti ṣe ojúṣe mímọ́ yí.”1
Mo dúpẹ́ fún iṣẹ́-ìsìn àìmọtaraẹni-nìkan àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí àwọn ọmọ Ìjọ nfúnní nínú àwọn tẹ́mpìlì wa àti nínú àwọn wọ́ọ̀dù, ẹ̀ka, àti eèkàn wọn. Mo dúpẹ́ bákánnáà pé àwọn ọmọ Ìjọ nsìn ní àìlónkà ìleto, ilé-ẹ̀kọ́, àti àwọn ìṣètò àánú àti pé wọ́n nṣiṣẹ́ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún iṣẹ́ arannilọ́wọ́ lọ́dọọdún, àwọn mílíọ́nù olùyọ̀nda ti àwọn wákàtí ní ó súnmọ́ igba àwọn orílẹ̀-èdè àti agbègbè.2
Ọ̀nà kan tí Ìjọ fi nmú àwọn ànfàní iṣẹ́ ìsìn gbòòrò ní onírurú àwọn orílẹ̀-èdè ni nípasẹ̀ JustServe.org. Olùgbọ̀wọ́ nípasẹ̀ Ìjọ ṣùgbọ́n ó wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti bùkún àwọn míràn, JustServe.org “so àwọn àìní olùyọ̀nda ìletò pẹ̀lú àwọn olùyọ̀ndà” tí ó “nmú ìwà ìgbésí ayé nínú ìletò ga si.”3
Ìjọ àti àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀ bákannáà gbárajọ pẹ̀lú àwọn ìṣètò iṣẹ́-ìsìn káàkiri àgbáyé. Ìjọ, ní ìdúpẹ́ sí àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀, ni “Red Cross títóbijùlọ ìdási ẹ̀jẹ̀ nìkàn ní 2022.” Ní àfikún, láìpẹ́ Ìjọ ṣe 8.7 mílíọ̀nùdọ́là ìdáwó sí Red Cross.4
Bákannáà Ìjọ darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò láti mú àwọn iṣẹ́ omi mímọ́ àti ìmọ̀ ìtọ́jú ìlera wá sí àwọn agbègbè kààkiri àgbáyé. Ní 2022, Ìjọ kópa nínú 156 irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.5 Bákannáà a sopọ̀ pẹ̀lú a sì dáwó sí àwọn ibi ìṣojúẹni míràn tí ó nmú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n njìyà.6
“Nígbàtí a bá sowọ́pọ̀ láti sin àwọn ènìyàn nínú àìní,” ni Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní wí, “Olúwa nfi ìrẹ́pọ̀ fún ọkàn wa.”7
Ẹ Di Ìmọ́lẹ̀ Yín Mú Sókè
Bí àwọn ọmọlẹ́hìn Olùgbàlà, bákannáà a nbùkún àwọn aladugbo wa bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ tí a sì ndarí àwọn ìgbé ayé bíiti Krístì. Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé “àwọn ènìyàn ìjọ” kò gbúdọ̀ yan òdodo nìkàn ṣùgbọ́n kí wọ́n mú kí a gbọ́ àwọn ohùn òdodo wọn bí wọ́n bá fẹ́ kí Olúwa dá ààbò bò kí ó sì mú wọn ṣerere (wo Álmà 2:3–7; bákannáà wo Mòsíà 29:27). Olúwa nretí wa láti pín ìgbàgbọ́ àti gbígbàgbọ́ wa kí a sì di ìmọ́lẹ̀ wá mú sókè. “Kíyèsi èmi ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí ẹ̀yin ó máa gbé sókè” (3 Néfì 18:24).
“A kò sìn Olùgbàlà wa dáradára bí a bá bẹ̀rù ènìyàn ju Ọlọ́run lọ,” ni Ààrẹ Dallin H. Oaks, Olùdámọ̀ràn Ìkínní nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní wí. Ó fikun, “A pè wá láti gbé òṣùwọ̀n Olúwa kalẹ̀, kí a máṣe tẹ̀lé ti ayé.”8
Bóyá ní ilé-ìwé, ibi iṣẹ́, tàbí eré, níbi ìsinmi, tàbí ní dídọ́rẹ̀, tàbí lórí ayélujára, àwọn ọmọlẹ́hìn Olúwa kìí “tijú láti gbé orúkọ Krístì lé orí wọn” (Álmà 46:21). Nípa àwọn ọ̀rọ̀ wa àti iṣẹ́ wa, à njẹri pé Ọlọ́run wà láàyè àti pé à ntẹ̀lé Ọmọ Rẹ̀.
“Ìgbàgbọ́ wa kìì ṣe ìpín-àyè, tàbí dájúdájú kò gbúdọ̀ jẹ́ bẹ́. Ìgbàgbọ́ kìí ṣe fún ìjọ lásán, kìí ṣe fún ilé lásán, kìí ṣe fún [ilé-ìwé] lásán,” Paul Lambert, amòye ènìyàn mímọ́ kan lórí ẹ̀sìn ṣe àkíyèsí. “Ó wà fún gbogbo ohun tí ẹ̀ nṣe.”9
A kò mọ ipa tí ẹ̀rí, àpẹrẹ rere, àti àwọn ìṣe rere wa lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí a ṣe ndúró fún òtítọ́ tí a sì ndi ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà mú sókè, àwọn ènìyàn yíò kíyèsí wa àti pé ọ̀run yíòfi wá múlẹ̀.
Dúró fún Òmìnira Ẹ̀sìn
Àlùfáà àrékérekè òní, pẹ̀lú àníkún òyè àwùjọ tí ó ntako àwọn ènìyàn onígbàgbọ́, kò yàtọ̀ rárá sí àwọn ìgbà Ìwé ti Mọ́mọ́ni. Ohùn àwọn wọnnì tí wọ́n tako ojúṣe pàtàkì ẹ̀sìn ní gbangba àti àwọn àrẹnà òṣèlú ndàgbà sì. Àwọn amòye àti ìjọba, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé-ìwé àti unifásítì, nfi agbára ṣe àti aláwọ̀ṣe ìwà èérí, àìgbàgbọ́, àti ìwà iyèkan.
Àwọn ìkọlù lórí òmìnira ẹ̀sìn yíò yege bí a kò bá dúró fún àwọn ẹ̀tọ́ ẹ̀sìn wa. “Bí ìjọ kan,” mo kọ́ni láìpẹ́, “a darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn míràn ní dídá ààbò bo àwọn ènìyàn ti gbogbo ìgbàgbọ́ àti ìyílọ́kànpadà àti ẹ̀tọ́ wọn láti sọ̀rọ̀ ìdánilójú wọn.”10
A ja ogun kan ní ọ̀run lórí ìwà agbára òmìnira—òmìnira wa láti yàn. Láti tọ́jú agbára òmìnira wa bèèrè fún pé kí a ní ìtara ní dídá ààbò bo òmìnira ẹ̀sìn wa.
Gbígbọ̀n ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn nfi okun àti ààbò fún àwọn ẹbí, ìletò, àti orílẹ̀-èdè. Ó nmú ìgbọràn fún òfin wá, ó nfi ọ̀wọ̀ fún ìgbésí ayé àti ohun ìní, ó sì nkọni ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìṣòtítọ́, àti ìwà—mímọ́ tí a nílò làti mú òtítọ́, ìjọlá, àti ọ̀làjú àwùjọ wá. A kò nílò láti bẹ̀bẹ̀ fún ìgbàgbọ́ wa láéláé.
Àwọn ìtiraka ojíṣẹ́ ìhìnrere wa, iṣẹ́ arọ́pò wa nínú àwọn tẹ́mpìlì, àwọn ìtiraka wa láti gbé ìjọba Ọlọ́run ga, àti ìdùnnú wa gan bèèrè fún pé kí a dúró fún ìgbàgbọ́ àti òmìnira ẹ̀sìn. A kò lè sọ òmìnira nù láìsí sísọ àwọn òmìnira míràn nù.
Wòlíì Joseph Smith, “Ójẹ́ ìfẹ́ òmìnira èyítí ó nmí sí ẹ̀mí mi—òmìnira ìlú àti ẹ̀sìn sí gbogbo ẹ̀yà ẹlẹ́ran ara.”5 Ẹ̀sìn òmìnira nmí sí ẹ̀mí wa bí a ti ntẹ̀lé àmọ̀ràn láti ẹnu àwọn olórí Ìjọ:
-
“Dúró ní mímọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn pàtàkì ìlú, àti nígbànáà kí a sọ̀rọ̀ jáde pẹ̀lú ìgboyà àti ọ̀làjú.”12
-
“Ẹ damọ̀ pé àgbàrá òmìnira ẹ̀sìn yíò ní ipá pàtàkì lórí àwọn ànfàní láti dàgbà nínú okun àti ìmọ̀ ìhìnrere, láti di alábùkún nípasẹ̀ àwọn ìlànà mímọ́, àti láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa láti darí Ìjọ Rẹ̀.”13
-
“Ẹ dìde kí ẹ sì sọ̀rọ̀ sókè láti tẹnumọ pé Ọlọ́run wà àti pé àwọn òtítọ́ pàtàkì ni àwọn òfin rẹ̀ gbékalẹ̀.”14
-
“Pe àwọn òfin tí yíò pa òmìnira wa lára láti ṣe ìṣe ìgbàgbọ́ wa níjà.”15
-
“Ẹ lọ sínú ayé láti ṣe rere, láti gbé ìgbàgbọ́ ga nínú Ọlọ́run Elédùmarè, àti láti ṣèrànwọ́ láti mú àwọn ẹlòmíràn wá sí ibi ìdùnnú jùlọ.”16
-
Ẹ ṣe àṣàrò ohun-èlò ní religiousfreedom.ChurchofJesusChrist.org àti ní religiousfreedomlibrary.org/documents.
À ngbé ìjọba Ọlọ̀run ga bí a ti nsìn, di ìmọ́lẹ̀ wa mú, tí a sì dúró fún òmìnira ẹ̀sìn. Njẹ́ kí Ọlọ́run bùkún wa nínú àwọn ìtiraka wa láti ṣe “rere púpọ̀” ní àárín àwọn ẹbí wa, ìletò, àti àwọn orílẹ̀-èdè.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹta 2024. Yoruba. 19347 779