Làìhónà
Ọlọ́run Dá Álmà àti Amúlẹ́kì Sílẹ̀
Oṣù Kẹfà 2024


“Ọlọ́run Dá Álmà àti Amúlẹ́kì Sílẹ̀,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹfà 2024, 26–27.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Osù kẹfà 2024

Ọlọ́run Dá Álmà àti Amúlẹ́kì Sílẹ̀

Álmà àti Amúlẹ́kì nwàásù

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Álmà àti Amúlẹ́kì lọ sí ìlú kan tí à npè ní Ammoníhàh. Wọ́n kọ́ àwọn ènìyàn nípa Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n inú bí àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n nkọ́. Wọ́n fi Álmà àti Amúlẹ́kì sínú túbú.

Álmà àti Amúlẹ́kì wà ní ìdè nínú túbú

Àwọn ènìyàn pa Álmà àti Amúlẹ́kì lára. Wọ́n wà nínú túbú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

Àwọn ògiri túbú ṣubú lulẹ̀ ní àyíká Álmà àti Amúlẹ́kì

Álmà àti Amúlẹ́kì gbàdúrà wọ́n sì bèèrè fún okun. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó fún wọn ní agbára láti já okùn ní ọrùn ọwọ́ wọn.

Álmà àti Amúlẹ́kì láìsí okùn tí ó dè wọ́n dúró nínú èérún

Nígbànáà ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn ògiri túbú ṣubú lulẹ̀! Ọlọ́run Dá Álmà àti Amúlẹ́kì Sílẹ̀. Wọ́n fi Ammoníhàh sílẹ̀ láti lọ kọ́ àwọn ènìyàn míràn nípa Jésù Krístì.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Mọ̀ Pé Jésù Fẹ́ràn Mi

Àwọn ọmọ méjì tí a yíká nípasẹ̀ àdánidá, àwọn ìwé-mímọ́, àti tẹ̀mpìlì kan

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Kíní àwọn ohun tí ó nrán yín létí nípa ìfẹ́ Jésù Krístì?