“Ọlọ́run Yíò Tìlẹ̀hìn yíò sì Ṣaláàbò Wa,” Làìhónà, Oṣù Kẹjọ, 2024.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́jọ 2024
Ọlọ́run Yíò Tìlẹ̀hìn yíò sì Ṣaláàbò Wa
Bíiti Ọ̀gágun Mórónì, a lè gba ìrànlọ́wọ́ tọ̀run àti agbára fún àwọn ogun tí a dojúkọ ní ayé.
Nígbàtí mo kọ́kọ́ ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, mo gbádùn àkọọ́lẹ̀ ìtàn àwọn ogun ní àárín àwọn Néfì àti àwọn Lámánì. Mo ní ìfanimọ́ra nípa ìgbàgbọ́, àìṣẹ̀tàn, àti àwọn ìlànà-ìṣe tí a lò nípasẹ̀ Ọ̀gágun Mórónì, apàṣẹ ológun ẹni tí a yàn bí olórí gbogbo ogun àwọn Néfì nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún marundinlọgbọn. Ó jẹ́ ọlọgbọn, alágbára, àti onítara. Ó fi ara jì tán sí òmìnira àti àláfíà àwọn ènìyàn rẹ̀. (Wo Álmà 48:11–12.)
Dípò fífí oríyìn àṣeyege ológun fúnrarẹ̀, Mórónì gbé oríyìn àṣeyege sí Ọlọ́run àti sí àtìlẹhìn mímọ́ tí àwọn ọmọ ogun gbà látọwọ́ àwọn obìnrin àti ọmọdé tí kìí ṣe ológun. Ó wí fún olórí àwọn ọ̀tá tí a ṣẹ́gun pé: “Olúwa … ti fi yin lé wa lọ́wọ́. Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ó yé ọ pé a ṣe eleyi fún wa … nítorí ẹ̀sìn wa àti ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì.” Nígbànáà Mórónì pín ìmọ̀ye ti wòlíi yí pé : “Ọlọ́run yíò ṣe àtìlẹhìn, yíò sì pa wá mọ́, yíò sì dá ààbò bò wá, ní ìwọ̀n ìgbà tí àwa bá jẹ́ olódodo sí i, àti sí ìgbàgbọ́ wa, àti ẹ̀sìn wa” (Alma 44:3, 4).
Ní àkokò, mo ti wá damọ̀ pé Mórónì ṣe àwòṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ tí a lè múlò láti ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpènijà ti ìgbésí ayé wa òde òní. Bí a ti nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, Olùgbàlà aráyé, Òun yíò bùkún wa pẹ̀lú agbára Rẹ̀. Ṣùgbọ́n fún Un láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti fún wa láti dá àwọn ìbùkún Rẹ̀ mọ̀, a nílò láti ní òye èrèdí wa, ọgbọ́n fún àṣeyege, kí a sì múrasílẹ̀ fún àwọn ogun àfijúwe tí à nkojú, gẹ́gẹ́bí Mórónì ṣe múrasílẹ̀ fún tí ó sì dojúkọ àwọn ogun tòótọ́ nínú ayé rẹ̀. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì yíò tì wá lẹ́hìn yíò sì pa wá mọ́.
Níní Òye Èrèdí Wa
Mórónì rán àwọn ènìyàn létí ẹni tí wọ́n jẹ́ léraléra (àwọn ajogun májẹ̀mú ti Ábráhámù), àwọn tí wọ́n jẹ́ (àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run), àti ìdí fún èyí tí wọ́n fi jà (ẹbí, ìgbàgbọ́, àti òmìnira). Mórónì kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pé wọ́n njà fún yíyè wọn gan an àti fún òmìnira kúrò nínú ìninilára àti ìdè. Ní ìlòdì, àwọn ọ̀tá wọn njà fún ìgbéga araẹni àti agbára nípa títẹ àwọn ẹlòmíràn ba.
Nígbàtí àwọn Néfì kan wá láti dojú ìjọba bolẹ̀ fún èrè araẹni, Mórónì ya kóòtù rẹ̀ ó sì kọ̀wé sórí ẹ̀là kan rẹ̀ nípa kókó àwọn ohun-èlò ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Ní ìrántí Ọlọ́run wa, ẹ̀sìn wa, àti òmìnira, àti àláfíà wa, àwọn ìyàwó wa, àti ọmọ wa.” Ó gbé àsíá yí sókè, èyítí ó pè ní “àkọlé òmìnira,” ní òpin òpó ó sì lòó láti rán àwọn ènìyàn létí ohun tí ìjà náà wà nípa rẹ̀ àti láti kó wọn jọ sí ìdí náà. Wo Álmà 43:29–33, 48-50
Nínú àwọn ogun ti-ẹ̀mí ayé, “a kò jagun ní atako sí ara àti ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n sí … atako ìjọba òkùnkùn … [àti] sí ẹ̀mí ìwà burúkú” (Éfésù 6:12). Àwa, náà, nílò láti di ríránlétí nípa ohun tí ìjà náà wà nípa rẹ̀. Alàgbà Neal A. Maxwell (1926–2004), ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá tẹ́lẹ̀, fi èrò rẹ̀ hàn nínú ìsọ̀rọ̀, ránpẹ́, dídára.
Ní 2004, mo bẹ Maxwell wò ní yàrá ilé-ìwòsàn rẹ̀ láìpẹ́ kí ó tó kú. Ó ní inú rere gidi sí gbogbo ènìyàn tí ó ṣèbẹ̀wò tàbí ṣèrànwọ́ fún. Àwọn òṣìṣẹ́ olùtọ́jú-ìlera lọ sínú yàrá rẹ̀ wọ́n sì jáde ní sísọkún. Mo wí fun pé, “Alàgbà Maxwell, èyí lè nítòótọ́.” Ó rúnra ó sì wípé, “Ah, Dale, a jẹ́ ẹni ayérayé tí ó ngbé nínú ayé ikú. A jáde nínú ohun-èlò wa, bí ẹja kúrò nínú omi. Nígbà tí a bá ní ìrísí ayérayé pé eyikeyi nípa èyí yíò mú ọgbọ́n wá.”
A kò níláti sọ ìríran ọ̀pọ̀ èròjà ti ìwá-ẹ̀dá tọ̀run àti àyànmọ́ ayéráyé àti àwọn ipa èṣù tí ó ntakò wa nù. Níní òye ètò Baba Ọ̀run ní pípé yíò fún wa ní ìwúrí láti tẹramọ́ jíjà fún ìgbàlà ayérayé wa àti fún òmìnira wa kúrò nínú ìdè ti-ẹ̀mí.
Lílo Ọgbọ́n fún Àṣeyege
Nínú gbogbo àwọn ogun tí àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jà, Mórónì lo ọgbọ́n láti mu àṣeyege dájú. Ó lo àwọn alamin láti wadi àwọn ìṣe àti èrò àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó wá ìdarí láti ọ̀dọ̀ wòlíì, Álmà. Lẹ́hìnnáà Mórónì lo ìmísí fífúnni náà ní ọ̀nà rẹ̀ sí jíjagun. Ó pín àwọn ohun èlò ká gẹ́gẹ́bí wọn ti nílò, ó fi àwọn jagunjagun púpọ̀ sí inú àwọn ìlú tí kò ní odi púpọ̀. Ó fi ọgbọ́n gbé àwọn ètò ṣíṣe kalẹ̀ tí ó dá lórí ìmú-dé-ìwọ̀n àlàyé.
Níbẹ̀ ni ó jèrè ànfàní lórí àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá. Òun kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́gun àtẹ̀hìnwá rí; ṣùgbọ́n, ó tẹ̀síwájú láti mú agbára àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ dára si láti kojú àwọn ìpènijà ọjọ́ iwájú.
A lè lo irú àwọn ọ̀nà kannáà láti kojú àwọn alátakò ti ẹ̀mí. A lè bẹ̀rẹ̀ nípa dídá ohun tí Sátánì ngbìyànjú láti ṣe nínú ayé wa mọ̀. Ó ngbìyànjú láti dà wá láàmú kúrò nínú èrèdí wa. Nígbàtí a ba dojúkọ àdánwò, a níláti bèèrè lọ́wọ́ ara wa:
-
Báwo ni ìṣe èyí ní apá tèmi ṣe ntako ọ̀rọ̀ ìfihàn Ọlọ́run?
-
Kíni àwọn àyọrísí ti ṣíṣe ìṣe yí?
-
Njẹ́ ìṣe yí nràn mí lọ́wọ́ láti mú èrèdí mi lórí ilẹ̀-ayé ṣẹ?
Aní a níláti da abájáde ìgbẹ̀hìn ti yíyọ̀ọ̀dà sí àwọn àdánwò kékeré mọ bákannáà. Bí a ti nyọ̀ọ̀da sí àdánwò, a njẹ “eewọ ní ipele sí ipele” (Álmà 47:18), ọgbọ́n kan dídára jùlọ tí àwọn agbára búburú nlo tí ó lè darí sí èsì apani ti ẹ̀mí.
A le mọ odi fúnra wa ní ìlòdì sí àwọn àdánwò Sátánì nípa títẹ̀lé ìdarí tí a gbà láti ẹnu wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nrànwálọ́wọ́ láti tẹramọ́ ìrísí ayérayé nínú èyí tí a ó wọn àwọn ìṣe wa. Lílo ọgbọ́n bí a ó ti kojú àwọn àdánwò tí ó ndìde ní onírurú àwọn agbègbè ìgbésí aye wa yíò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àṣàyàn títọ́ ní àkokò náà. Ṣíṣètò ọgbọ́n àti ọ̀nà sílẹ̀ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dá ààbò bò ní ìlòdì sí ìdàmú látinú èrèdí ayérayé wa.
Apẹrẹ kan ni ti ohun ìgbàlódé. Ohun ìgbàlódé lè jẹ́ ìda olójú-méjì, méjèèjì dídara àti bíburú, dídá lórí bí a bá ṣe lò ó. Láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣàyàn ọgbọ́n nípa àwọn ẹ̀rọ wa, ọ̀dọ́ àti àgbà le tọ́kasí “Gbígba Àṣẹ Ohun Ìgbàlódé” àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn. Ìwọ̀nyí rán wa létí èrèdí wa; tọ́ wa sí Jésù Krístì, ó sì nrànwálọ́wọ́ láti pe Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ìgbésí ayé wa. Ṣíṣe ètò bí, nígbàtí, àti ibití a ó ti lo ohun ìgbàlódé yíò mọ odi yí wa ká ní ìlòdì sí ìtìlẹ̀, ẹ̀tàn ti-ayé
Mímúrasílẹ̀ fún àwọn Ogun Ìjúwe
Ní ìfojúsọ́nà sí àwọn ogun tí ó nbọ̀, Mórónì múra àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn àwo-àyà, àkọ̀, ìbòrí, àti ẹ̀wù tó nípọn. Ó múra àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ papọ̀ nípa yíyí àwọn ìlú ka pẹ̀lú odi, jíju àwọn bèbè erùpẹ̀ yíka wọn.
Níti ẹ̀mí, a múra olúkúlùkù sílẹ̀ nípa pípá àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. À nda a sì npa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó nfa agbára Jésù Krístì wá sínú ayé wa. A nṣiṣẹ́ níti araẹni, àwọn ìṣe ìfọkànsìn ìkọ̀kọ̀, bí irú gbígbàdúrà, gbígbàwẹ̀, àti wíwá àwọn ìwé-mímọ́. Bákannáà à nṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́, fífèsì sí ìdarí ti ẹ̀mí tí a gbà. À nfi taratara múrasílẹ̀ fún àti yíyẹ láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Olùgbàlà ndi òtítọ́ si nínú ayé wa, gẹ́gẹ́bí Òun ti jẹ́ òdodo sí Mórónì, ẹnití ó dúróṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Krístì. Mórónì mọ̀ pé òun lè gbáralé Olùgbàlà fún ìdarí àti ìtúsílẹ̀ (wo Álmà 48:16). Àwa, bákannáà, lè gbáralé Jésù Krístì fún ìdará àti ìtúsílẹ̀.
A lè múrasílẹ̀ síi nípa fífún àwọn ẹbí wa lókun. Baba wa Ọ̀run ṣètò wa sínú àwọn ẹbí láti ṣèrànwọ́ fún wa láti ní ìdùnnú àti láti kọ́ bí a ó ti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Àwọn ẹbí wa lè jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ fún wa. Gbogbo wa lè ní ìmọ̀làra ayọ̀ àti ìfẹ́ nípa rírántí pé a jẹ́ ara ẹbí nlá ti Ọlọ́run, láìka àwọn ipò olùkúlùkù àwọn ẹbí wa sí.
A lè jèrè okun papọ̀ kí a sì múrasílẹ̀ fún àwọn ogun ti ẹ̀mí wa bí a ti ndarapọ̀ nínú ìletò àwọn Ènìyàn Mímọ́. Àwọn èèkàn wa àti ẹ̀kùn npèsè irú ibi ààbò àti ìsádi kan. A lè ṣìkẹ́ ara wa níti ẹ̀mí, ran ara wa lọ́wọ́ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí a sì gba ara wa níyànjú láti gbáralé Krístì, nígbàgbogbo nípàtàkì ní àwọn ìgbà ìpènijà. Nígbàtí a bá kórajọ, a damọ̀ pé a kìí dá nìkan ja àwọn ogun wa. A ní àwọn ọ̀rẹ́, olùkọ́, àti àwọn olórí tí wọn lè ṣèrànwọ́ kí wọ́n sì dá ààbò bò wá. Gbogbo wa lágbára si nígbàtí a bá múrasílẹ̀ papọ̀.
Pẹ̀lú àmì, Mórónì ka gbogbo ìdùnnú ti àwọn ènìyàn rẹ̀ sí jíjẹ́ òtítọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run àti ẹ̀sìn wọn. Bíiti Mórónì, a níláti damọ̀ pé ayọ̀ nwá nítorí Baba Ọ̀run àti ètò Rẹ̀ àti nítorí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Bí a ti nwá láti ní oye èrèdí wa, lo ọgbọ́n fún àṣeyege, tí a sì múrasílẹ̀ fún àwọn ogun ìjúwe, à ngba ìrànlọ́wọ́ àti agbára tọ̀run.
Bíiti Mórónì, mo mọ̀ pé Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì nmú òmìnira ìgbẹ̀hìn wá látinú ìdè—òmìnira látinú ikú àti ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n nbùkún wa pẹ̀lú agbára Wọn nígbàtí a bá nwò Wọ́n nínú ohun gbogbo.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀pada-èdè Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹ́jọ 2024. Yoruba. 19294 779