Làìhónà
Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun
Oṣù Kẹ́jọ 2024


“Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2024, 26–27.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́jọ 2024

Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun

Àwọn ènìyàn nri àwọn ohun-ìjà wọn mọ́lẹ̀ nínú kòtò

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Àwọn ènìyàn tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kọ́ nfẹ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Wọ́n ri àwọn ohun ìjà wọn mọ́lẹ̀ wọ́n sì ṣe ìlérí fún Ọlọ́run pé wọn kò ní jà mọ́ láéláé.

Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan dé ilé kan níbití àwọn àgbàlàgbà ti nsọ̀rọ̀

Ṣùgbọ́n láìpẹ́ wọ́n nílò láti dá ààbò bo àwọn ẹbí wọn. Àwọn baba tí wọ́n ti ri àwọn ohun ìjà wọn mọ́lẹ̀ kò fẹ́ já ìlérí wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorínáà àwọn ọmọkùnrin wọn múrasílẹ̀ láti jà ní ipò wọn. A pè wọ́n ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin jagunjagun ẹgbẹ́rún méjì. Sírípílínì túmọ̀ sí “ọ̀dọ́mọkùnrin.”

Ọ̀dọ́mọkùnrin ngbàdúrà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ nígbàtí àwọn ọ̀dọ̀mọkùnrin míràn kórajọ pẹ̀lú àwọn ohun-ìjà ogun

Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun náà kò tíì ja nínú ogun rí. Ṣùgbọ́n àwọn ìyá wọn ṣèrànwọ́ láti múra wọn sílẹ̀ wọ́n sì kọ́ wọn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run.

Hẹ́lámánì ndarí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin jagunjagun nínú yíyan kan; ọ̀dọ́mọkùnrin kan nran ọ̀dọ́mọkùnrin tí a palára láti rin lọ́wọ́

Wọ́n yan Hẹ́lámánì láti jẹ́ olórí wọn. Wọ́n jẹ́ olùgboyà, Ọlọ́run sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Gbogbo wọn ní ìpalára, ṣùgbọ́n wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́. Ọlọ́run ran ìgbàgbọ́ wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ye!

Kíkùn Ojú-ewé

Àwọn Ìwé-mímọ́ Lè Ràn Mi Lọ́wọ́ Ní Ojojúmọ́

Kíkùn ojú-ewé Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi ìjádé látinú àwọn ojú-ewé ti ìwé ṣíṣí-sílẹ̀ han

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Ìtàn ìwé-mímọ́ wo ni ẹ fẹ́ràn jùlọ?