“Àwòṣe kan fún Ìrẹ́pọ̀ nínú Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa 2024.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹwa 2024
Àwòṣe kan fún Ìṣọ̀kan nínú Krístì
Bí a ti nní ìṣọ̀kan nínú Jésù Krístì bíiti àwọn ènìyàn inú 4 Nefi, ìfẹ́ wa láti jẹ́ ọ̀kan kọja àwọn ìyàtọ̀ wa yíò sì darí sí ìdùnnú.
À ngbé ní ọjọ́ kan nígbàtí ìgbì ìrúsókè asọ̀ àti àríyànjiyàn ntàn káàkiri àgbáyé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn ti di tútù ti gbàmọ́ra, àwọn ipa ìyapa wọ̀nyí nṣe ìdẹ̀rùbà láti kún ọkàn wa pẹ̀lú ẹ̀gàn àti láti ba ìbárasọ̀rọ̀ wa jẹ́ pẹ̀lú ìjà. Àwọn ìsopọ̀ ìletò njá. Àwọn ogun njà.
Ní ìlòdì sí àtẹ̀hìnwá, àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì tòótọ́ ntara fún àláfíà wọ́n sì nfi aápọn wá láti gbé irú ìyàtọ̀ àwùjọ ga—ọkan tí a gbékalẹ̀ lórì àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì. Dé òpin yí, Ọlọ́run pàṣẹ fún wa láti “jẹ́ ọ̀kan; àti pé bí ẹ kò bá jẹ́ ọ̀kàn ẹ kìí ṣe tèmi” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:27). Nítòótọ́, ìṣọ̀kan ni àmì-ìwàmímọ́ ti òtítọ́ Ìjọ Jésù Krístì.
Báwo ni a ó ti ṣiṣẹ́ ní ìlòdì sí àwọn ipa ìyapa àti ìjà? Báwo ni á ti ṣe àṣeyege ìṣọ̀kan?
Ní dídára, 4 Nefi nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún wa ní àpẹrẹ kan. Orí yí ṣe àwọn àkọsílẹ̀ ọ̀nà ránpẹ́ tí àwọn ènìyàn fi gbé lẹ́hìn tí Olùgbàlà ti bẹ̀ wọ́n wò, kọ́ wọn lẹkọ, tí ó sì gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀ ní àárín wọn. Àkọsílẹ̀ yí fihàn bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe àṣeyege ìṣọ̀kan ayọ̀-ọ̀run àti àláfíà, tí ó sì fún wọn ní àwòṣe kan tí a lè tẹ̀lé láti gba irú ìṣọ̀kan kannáà fúnra wa.
ìyípadà
Nínú 4 Nefi 1:1, a kà pé: “Àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù ti dá ìjọ ti Krístì kan sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ́ káàkiri. Àti pé [àwọn ènìyàn] wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítòótọ́.”
À nní ìṣọ̀kan ní àyíká Olúwa àti Olùgbàlà Jésù Krístì. Bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣe nkọ́ nípa Jésù Krístì, ìhìnrere Rẹ̀, àti Ìjọ Rẹ, Ẹ̀mí Mímọ́ njẹri nípa òtítọ́ náà sí ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan. Nígbànáà ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè tẹ́wọ́gba ìpè Olùgbàlà láti ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ àti láti tẹ̀lé E nípa ríronúpìwàdà.
Bayi ni ìrìnàjò ìyípadà olúkúlùkù nbẹ̀rẹ̀—kúrò nínú àwọn ìfẹ́-inú ìmọ̀tara-ẹni-nìkan àti ti-ẹ̀ṣẹ̀ àti síwájú Olùgbàlà Òun ni ìpìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa. Àti pé bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá ṣe nwò Ó ní gbogbo èrò (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 6:36), Òun ó di ipa ìṣọ̀kan kan nínú ayé wa.
Awọn májẹ̀mú
Àkọsílẹ̀ nínú 4 Nefi fihàn pé àwọn tí wọ́n wá sí Ìjọ tí wọ́n sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn “ni a rìbọmi ní orúkọ Jésù; tí wọ́n sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú” (4 Nefi 1:1). Wọ́n ti wọnú májẹ̀mú—ìsopọ̀ ìbáṣepọ̀, pàtàkì kan—pẹ̀lú Ọlọ́run.
Nígbàtí a bá dá tí a si pa àwọn májẹ̀mú mọ́, a ngbé orúkọ́ Olúwa lé orí arawa bí olúkúlùkù. Ní àfikún, à ngbé orúkọ Rẹ̀ lé orí wa bí àwọn ènìyàn kan. Gbogbo ẹni tí ó bá dá àwọn májẹ̀mú tí wọ́n sì ntiraka láti pa wọ́n mọ́ ó di àwọn ènìyàn Olúwa, ìṣúra pàtàkì Rẹ̀ (wo Eksodu 19:5). Bayi, à nrin ìrìnàjò ipa-ọ̀nà májẹ̀mú bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ pẹ̀lú. Májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run nfún wa ní èrèdí ìwọ́pọ̀ àti ìdánimọ̀ ìwọ́pọ̀. Bí a ti nso arawa mọ́ Olúwa, Òun ó ràn wá lọ́wọ́ láti ní “ọkàn sí ara wọn ní ìrẹ́pọ̀ àti ní ìfẹ́ ọ̀kan sí ara wọn” (Mòsíàh 18:21).
Dídára, Dídọ́gba, àti Ríran àwọn Òtòṣì Lọ́wọ́
Àkọsílẹ̀ nínú 4 Nefi tẹ̀síwájú: “Kò sì sí ìjà kankan àti àríyànjiyàn ní àárín wọn, wọ́n sì fi òdodo bá ara wọn lò.
“Wọn sì jùmọ̀ ní ohun gbogbo papọ̀; nítorínã kò sí olówó àti tálákà, òndè àti òmìnira, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni a sọ di òmìnira, àti alábãpín ẹ̀bùn ọ̀run nã” (4 Nefi 1:2–3).
Nínú ìbáṣe ti-ara wa, Olúwa nfẹ́ kí a ṣe dáradára àti òtítọ́ sí ara wa kí a máṣe jàlólè tàbí gba èrè ara wa (Wo 1 Thessalonians 4:6). Bí a ti ndàgbà súnmọ́ Olúwa si, a “kò sì ní ní ọkàn láti pa ara wa lára, ṣùgbọ́n láti gbé pọ̀ ní àlãfíà, àti láti fi fún ènìyàn gbogbo gẹ́gẹ́bí ó ṣe tọ́ síi” (Mòsíàh 4:13).
Bákannáà Olúwa ti pàṣẹ fún wa láti tọ́jú àwọn òtòṣì àti aláìní. A níláti “fi ohun-ìní [wa] sílẹ̀” láti ràn wọ́n lọ́wọ́, gẹ́gẹ́bí agbára wa bá ti tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, láì dá wọn lẹ́jọ́ (wo Mòsíàh 4:21–27).
Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní láti “ka arákùnrin rẹ̀ sí bí ara rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:24). Bí a bá jẹ́ àwọn ènìyàn Olúwa tí a sì ní ìrẹ́pọ̀, kìí ṣe pé a gbúdọ̀ tọ́jú ara wa bí ọ̀kannáà nìkan, ṣùgbọ́n a gbúdọ̀ wo arawà lódodo bí ọ̀kannáà kí a sì ní ìmọ̀lára nínú ọkàn wa pé ọ̀kannáà ni wá pẹ̀lú—ọ̀kannáà níwájú Ọlọ́run, yíyẹ kannáà àti ìlèṣe kannáà.
Ìgbọ́ran
Ẹ̀kọ́ tó kàn látinú 4 Nefi wá nínú ìsọ̀rọ̀ yí: “Wọ́n sì nrìn ní ti àwọn òfin tí wọ́n ti gba láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn” (4 Nefi 1:12).
Olúwa ti kọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ẹ̀kọ́ Rẹ̀, ó fún wọn ní àwọn òfin, ó sì pe àwọn ìránṣẹ́ láti ṣe ìpínfúnni sí wọn. Ọ̀kan lára àwọn èrò Rẹ̀ ní ṣíṣe èyí ni láti mu dájú pé kò ní sí àríyànjiyàn ní àárín wọn (wo 3 Nefi 11:28–29; 18:34).
Ìgbọ́ran wa sí àwọn ìkọ́ni Olúwa àti àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe kókó sí dídí ìṣọ̀kan wa. Èyí pẹ̀lú ìfarajìn wa láti gbọ́ran sí òfin láti ronúpìwàdà nígbàkugbà tí a bá kùnà àti láti ran ara wa lọ́wọ́ bí a ti ntiraka láti ṣe dídára si àti láti jẹ́ dídárasi lojojúmọ́.
Pàdé Papọ̀
Èyí tó kàn, a kẹkọ pé àwọn ènìyàn nínú 4 Nefi “[tẹ̀síwájú] nínú àwẹ̀ àti àdúrà, àti nínú ìpàdé papọ̀ léraléra láti gbàdúrà àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa pẹ̀lú” (4 Nephi 1:12).
A nílò láti pàdé papọ̀. Àwọn ìpàdé ìjọ́sìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wa jẹ́ ànfàní pàtàkì fún wa láti rí okun, lọ́kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ pẹ̀lú. À nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, nkẹkọ, nkọrin papọ̀, a sì nti arawa lẹ́hìn. Bákannáà àwọn àkójọpọ̀ míràn nṣèrànwọ́ láti mú ọgbọ́n wíwà-pẹ̀lú, ìbádọ́rẹ́, àti pípín èrò jáde wa.
Ìfẹ́
Àkọsílẹ̀ nínu 4 Nefi nígbànáà ó fún wa ní ohun tí ó jẹ́ kọ́kọ́rọ́ ọlọ́lá sí gbogbo èyí—láìsí ohun èyí tí a kò lè gba ìrẹ́pọ̀ lódodo: “Kò sì sí asọ̀ ní ilẹ̀ náà, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run èyítí ó ngbé inú ọkàn àwọn ènìyàn náà” (4 Nefi 1:15).
Àláfíà araẹni ni à ngbà nígbàtí àwà, nínú ìjuwọ́lẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀, nítòótọ́ bá nifẹ Ọlọ́run. Èyí ni èkínní àti òfin ńlá. Fífẹ́ Ọlọ́run síi ju ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míràn lọ ni ipò tí ó nmú àláfíà òtítọ́, ìtùnú, ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, àti ayọ wá. Bí a ti ngbèrú ìfẹ́ Ọlọ́run àti Jésù Krístì, ìfẹ́ ẹbí àti aladugbo yíò tẹ̀lé ní àbínibí.
Ayọ̀ títóbijùlọ tí ẹ ó ní ìrírí rẹ̀ láé ni ìgbàtí ẹ bá ní ìwọra pẹ̀lú ifẹ́ fún Ọlọ́run àti fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.
Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì, ni aporó sí ìjà. Òun ni kókó ìwà ti àtẹ̀lé òtítọ́ Jésù Krístì. Nígbàtí a bá rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run tí a sì gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn wa, Òun yíò fún wa ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ (wo Mórónì 7:48).
Bí gbogbo wa ṣe nwá kí ìfẹ́ Ọlọ́run ó gbé nínú ọkàn wa, iṣẹ́-ìyanu ìrẹ́pọ̀ yíò dàbí àṣeparí àbínibí sí wa.
Ìdánimọ̀ Àtọ̀runwá
Ní ìgbẹ̀hìn, àwọn ènìyàn nínú 4 Nefi fi àmì ìṣọ̀kan tí ó gba ìfojúsí wa hàn: “Kò sí ọlọ́ṣà, tàbí apànìyàn, bẹ́ẹ̀ni kò sí ará Lámánì, tàbí irúkírú ẹlẹ́yàmẹ̀yà; ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ ọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún ìjọba Ọlọ́run” (4 Nefi 1:17).
Àwọn ìsàmì tí ó ti pín àwọn ènìyàn níyà fún ọgọgọ́rún ọdún ṣíwájú ọ̀pọ̀ ìdánimọ̀ pípẹ́ àti ìgbéga. Wọ́n wo arawọn—àti gbogbo ẹlòmíràn—gẹ́gẹ́bí ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.
Onírurú àti ìyàtọ̀ lè jẹ́ rere àti pàtàkì sí wa. Ṣùgbọ́n àwọn ìdánimọ̀ pàtàkì jùlọ wa ni àwọn wọnnì tí ó bá àtètèkọ́ṣe àtọ̀rùnwá àti èrò wa mu.
Àkọ́kọ́ àti ìṣaájú, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ìkejì, gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ọmọ májẹ̀mú. Àti Ìkẹ́ta, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Mo rọ gbogbo wa kí a máṣe fi àyè gba eyikeyi ìfinimọ̀ láti “múkúrò, rọ́pò, tàbí gba ipò-ìṣíwájú lórí àwọn ìfúni-nípò pípẹ́ mẹ́ta wọ̀nyí.”
Jẹ́ Ọ̀kan
Ọlọ́run ti pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Àyè wà fún gbogbo ènìyàn. A lè yàtọ̀ sírà nínú ọ̀làjú, òṣèlú, ẹlẹ́yàmẹ̀yà, adùn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà míràn. Ṣùgbọ́n bí a ti nní ìrẹ́pọ̀ nínú Jésù Krístì, irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ a ṣá ní pàtàkì wọn ó sì tayọ nípa bíborí ìfẹ́ wa láti jẹ́ ọ̀kan—kí a lè jẹ́ Tirẹ̀.
Ẹ fi ẹ̀kọ́ tí a kọ́ni nínú 4 Nefi sọ́kàn. Bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe ntiraka láti fi àwọn ohun èlò ìṣọ̀kan pàtàkì wọ̀nyí sínú ayé wa, a lè sọ nípa wa, bí ó ti wà nípa wọn pé, “Dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ jù wọ́n ní àárin gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá” (4 Nefi 1:16).
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹwa 2024. Yoruba. 19359 779