Làìhónà
Báwo ni a ṣe lè wà ní ìṣọ̀kan bí gbogbo wa bá yàtọ̀ síra gan?
Oṣù Kẹwa 2024


“Báwo ni a ṣe lè wà ní ìṣọ̀kan bí gbogbo wa bá yàtọ̀ síra gan?,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹwa 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹwa 2024.

Báwo ni a ṣe lè wà ní ìṣọ̀kan bí gbogbo wa bá yàtọ̀ síra gan?

Kúùbù pẹ̀lú àwọn àkọ̀ lórí wọn

Gbogbo wa yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n Olúwa nfẹ́ kí a “jẹ́ ọ̀kan” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:27). Nihin ni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ díẹ̀ ti ìṣọ̀kan tí àwọn wòlíì àti àpóstélì ti kọ́ wa:

A wà ní ìṣọ̀kan nínú Jésù Krístì, ìhìnrere Rẹ̀, àti Ìjọ Rẹ̀. “Ó jẹ́ nínú àti nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan sí àti ìfẹ́ Jésù Krístì nìkan ni a lè ní ìrètí láti jẹ́ ọ̀kan.”

Ìṣọ̀kan bèèrè fún ìfẹ́ “Àní pẹ̀lú ìyàtọ̀ àwọn èdè àti ìṣẹ̀dálẹ̀ àṣà ẹlẹ́wà, gbígbéga, a gbúdọ̀ so ọkàn wa pọ̀ nínú ìṣọ̀kan àti ìfẹ́.”

Ìṣọ̀kan kìí ṣe jíjẹ bákannáà. “Ìṣọ̀kan àti ìyàtọ̀ kìí ṣe ìdàkejì. A lè ṣe àṣeyọrí ìṣọ̀kan títóbi jùlọ bí a ṣe nmú wíwàpẹ̀lú ní àyíká wa wá àti ọ̀wọ̀ fún ìyàtọ̀. “Ìṣọ̀kan kò gba irúkannáà, ṣùgbọ́n ó gba ìbárẹ́.

Ìṣọ̀kan bèèrè fún mímú ìjà àti ẹ̀tanú kúrò. “Àyè wà fún gbogbo ènìyàn. Bákannáà, kò sí àyè kankan fún ẹ̀tanú, ìdálẹ́bi, tàbí ìjà eyikeyi.”