Orí 13
Étérì sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù Titun kan èyítí irú ọmọ Jósẹ́fù yíò kọ́ sí Amẹ́ríkà—O sọ àsọtẹ́lẹ̀, wọn lé e jáde, o kọ ìtàn àwọn ara Járẹ́dì, ó sì sọ àsọtélẹ̀ níti iparun àwọn ara Járẹ́dì—Ogun jà lórí gbogbo ilẹ̀ nã.
1 Àti nísisìyí èmi, Mórónì, tẹ̀síwájú láti pari àkọsílẹ̀ èyítí èmi nkọ nípa ìparun àwọn ènìyàn nã tí mo ti nkọ nípa wọn.
2 Nítorí ẹ kíyèsĩ, wọ́n ṣá gbogbo ọ̀rọ̀ Étérì tì; nítorítí ó sọ fún wọn nítõtọ́ nípa ohun gbogbo, láti ìbẹ̀rẹ̀ ènìyàn; àti pé lẹ́hìn tí àwọn omi ti fà sẹ́hìn kúrò lórí ilẹ̀ yĩ ó di ilẹ̀ tí ó dárajù gbogbo ilẹ̀ míràn lọ, ilẹ̀ tí Olúwa yàn; nítorí èyí Olúwa nfẹ́ kí gbogbo ènìyàn tí ngbé orí ilẹ̀ nã ó sìn òun;
3 Àti pé ó jẹ́ ibití Jerúsálẹ́mù Titun nã yíò wà, èyítí yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, àti pé yíò jẹ́ ibi mímọ́ Olúwa.
4 Sì kíyèsĩ, Étérì rí àwọn ọjọ́ Krístì, ó sì sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù Titun kan lórí ilẹ̀ yĩ.
5 Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa ìdílé Ísráélì, àti Jerúsálẹ́mù nnì nínú èyítí Léhì yíò jáde wá—lẹ́hìn tí a bá sì ti pa á run a ó tún padà tún un kọ́, ìlú mímọ́ sí Olúwa; nítorí èyí, kò lè jẹ́ Jerúsálẹ́mù àkọ̀tun nítorítí ó ti wà tẹ́lẹ̀rí ní ìgbà àtijọ́; sùgbọ́n a ó tún padà tún un kọ́, yíò sì di ìlú mímọ́ tí í ṣe ti Olúwa; a ó sì kọ́ ọ fún ìdílé Isráẹ́lì—
6 Àti pé a ó kọ́ Jerúsálẹ́mù Titun kán sí órí ilẹ̀ yĩ, sí ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù, àwọn ohun ti irú rẹ̀ ti wà rí.
7 Nítorí gẹ́gẹ́bí Jósẹ́fù ti mú bàbá rẹ̀ jáde wá sínú ilẹ̀ Égíptì, àní tí ó kú sí ibẹ̀; nítorí èyí, Olúwa mú ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, kí ó lè fi ãnú hàn sí irú-ọmọ Jósẹ́fù kí wọn ó má bã ṣègbé, gẹ́gẹ́bí ó ti fí ãnú hàn sí bàbá Jósẹ́fù kí ó ma bã ṣègbé.
8 Nítorí èyí, ìyókù ìdílé Jósẹ́fù ni a ó kọ́ lórí ilẹ̀ yĩ, yíò sì jẹ́ ilẹ̀ ìní wọn; wọn yíò sì kọ ìlú mímọ́ kan sí Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jerúsálẹ́mù ti ìgbà àtijọ́; a kì yíò sì fọ́n wọn ká mọ, títí òpin yíò dé nígbàtí ayé yíò kọjá lọ.
9 Ọ̀run titún kan yíò sì wà àti ayé titun; wọn yíò sì rí bí ti ìgbà àtijọ́, àfi pé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, ohun gbogbo sì ti di titun.
10 Nígbànã ni Jerúsálẹ́mù Titun yíò dé; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ngbé inú rẹ̀, nítorípé àwọn ni ẹnití aṣọ wọn di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn sì ní àwọn tí a ó kà mọ́ àwọn ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù, tí wọn jẹ́ ara ìdílé Ísráẹ́lì.
11 Nígbànã pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù ìgbà àtijọ́ yíò dé; ti àwọn tí ngbé inú rẹ̀, yíò jẹ́ alábùkún-fún, nítorítí a ti wẹ̀ wọ́n nínú èjẹ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn sì ni ẹnití Olúwa fọnká tí ó sì kójọ papọ̀ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé, àti láti àwọn orilè-èdè apá àríwá, tí wọ́n sì jẹ́ alábãpín nítí ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú bàbá wọn, Ábráhámù.
12 Àti nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá dé, ìwé-mímọ́ yíò sì di mímúṣẹ èyítí ó wípé àwọn kan wà tí ó jẹ ẹni-àkọ́kọ́, tí yíò si di ẹni-ikẹhìn; àwọn kan sì wà tí ó jẹ́ ẹni ìkẹhìn, tí yíò sì jẹ́ ẹni-àkọ́kọ́.
13 Èmi sì múra láti kọ síi, ṣùgbọ́n a dá mi lẹ́kun; sùgbọ́n títóbi àti ìyanu ni àwọn ìsọtẹ́lẹ́ Étérì jẹ́; ṣùgbọ́n wọn kã sí ẹni-asán, wọ́n sì lée jáde; ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ nínú ihò inú àpáta kan ní ọ̀sán, àti ní àṣálẹ́ ó jáde sí ìta ó sì nwò àwọn ohun tí yíò débá àwọn èníyàn nã.
14 Bí ó sì ti ngbé inú ihò inu àpáta nã ó kọ ìyókù àwọn àkọsílẹ̀ yĩ, tí ó sì nwò àwọn ìparun tí ó débá àwọn ènìyàn nã, ní àsálẹ́.
15 Ó sì ṣe nínú ọdún kannã nínú èyítí a lée jáde kúrò lãrín àwọn ènìyàn nã, ogun nlá kan bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ó jáde wá, tí wọn jẹ alágbára ènìyàn, tí wọ́n sì nlepa láti pa Kóríántúmúrì run nípa àwọn ète òkùnkùn ìwà búburú wọn, nípa èyítí a ti sọ.
16 Àti nísisìyí Kóríántúmúrì, nítorítí òun tìkárarẹ̀ kọ́ nípa gbogbo àwọn ìmọ̀ nípa ogun jíjà àti gbogbo ọgbọ́n àrekérekè ayé, nítori èyí ó gbé ogun tì àwọn tí wọn lépa láti pã run.
17 Ṣùgbọ́n kò sì ronúpìwàdà, bẹ̃ nã ni àwọn arẹwà ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀; tàbí àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Kóhọ̀; tàbí àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Kóríhọ̀; àti ní kúkúrú, kò sí èyíkéyí nínú àwọn arẹwà ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin lórí ilẹ̀ ayé gbogbo tí ó ronúpìwàdà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
18 Nítorí èyí, ó sì ṣe nínú ọdún kíni tí Étérì gbé inú ihò àpáta, àwọn ènìyàn púpọ̀ sì ni àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn fi idà pa, tí wọ́n nbá Kóríántúmúrì jà láti lè gba ìjọba nã.
19 Ó sì ṣe àwọn ọmọ Kóríántúmúrì ja púpọ̀ wọn sì fi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò púpọ̀.
20 Àti nínú ọdun kejì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ Étérì wá, pé kí ó lọ kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Kóríántúmúrì pe, bí ó bá ronúpìwàdà, àti gbogbo ilé rẹ̀, Olúwa yíò fi gbogbo ìjọba rẹ̀ fún un yíò sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ sí—
21 Bíkòjẹ́bẹ̃ a ó pa wọ́n run, àti gbogbo ilé rẹ̀ àfi òun nìkan. Àti pé òun yíò wà lãyè kí ó lè rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nã èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ níti àwọn ènìyàn míràn tí yíò gbà ilẹ̀ nã ní ìní; àti pé àwọn ni yíò sin òkú Kóríantúmúrì; àti pé gbogbo ẹ̀mí ni a ó parun àfi Kóríántúmúrì.
22 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì kò ronúpìwàdà, bẹ̃ nã ni ìdílé rẹ̀, tàbí àwọn ènìyàn nã; àwọn ogun kò sì dá dúró; wọn sì nwa ọ̀na láti pa Étérì, ṣùgbọ́n ó sá kúrò níwájú wọn ó sì tún sápamọ́ sínú ihò àpáta.
23 Ó si ṣe tí Ṣárẹ́dì dìde, òun pẹ̀lú sì gbógun tì Kóríántúmúrì; ó sì nã, tóbẹ̃ tí ó sì múu sínú ìgbèkùn ní ọdún kẹta.
24 Àwọn ọmọ Kóríántúmùrì, nínú ọdún kẹrin, sì nà Ṣárẹ́dì, wọ́n sì gbà ìjọba nã padà fún bàbá wọn.
25 Nísisìyí ogun bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã gbogbo, olukúlùkù pẹ̀lú ẹgbẹ́ rẹ̀ sì njà fún èyítí ó wù ú.
26 Àwọn ọlọ́sà sì wà, àti ní kúkúrú, onírúurú ìwà búburú wà lórí ilẹ̀ nã.
27 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì bínú sí Ṣárẹ́dì gidigidi, ó sì jáde lọ kọlũ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ̀; wọ́n sì bá ara wọn pàdé nínú ìbínú nlá, wọ́n sì pàdé nínú àfonífojì Gílgálì; ogun nã sì gbóná gidigidi.
28 O sì ṣe tí Ṣárẹ́dì bá a jà fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta. O sì ṣe tí Kóríántúmúrì nã, ó sì lée títí ó fi wọ̀ àwọn ilẹ̀ títẹ́jú ti Hẹ́ṣlọ́nì.
29 O sì ṣe tí Ṣárẹ́dì tún jagun pẹ̀lú rẹ̀ lórí àwọn ilẹ̀ tí ó tẹ́jú nã; ẹ sì kíyèsĩ, ó sì nà Kóríántúmúrì, ó sì tún lée padà sínú àfonífojì Gílgálì.
30 Kóríántúmúrì sì tún bá Ṣárẹ́dì jagun nínú àfonífojì Gílgálì, nínú èyítí ó nà Ṣárẹ́dì tí ó sì pã.
31 Ṣárẹ́dì sì ṣa Kóríántúmúrì lọ́gbẹ́ ní itan rẹ̀, tí o jẹ wípé kò jáde lọ jagun mọ́ fún ìwọ̀n ọdún méjì, nínú àkókò tí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã nta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ti kò sì sí ẹnití yíò dá wọn lẹ́kun.