Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 2


Orí 2

Àwọn ará Járẹ́dì múrasílẹ̀ láti rìn ìrìn àjò wọn lọ sí ilẹ ilérí kan—Ilẹ̀ daradara ni í ṣe nínú èyítí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ sìn Krístì tàbí kí a gbáwọn dànù—Olúwa bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀ fún wákàtí mẹ́ta—Àwọn ara Járẹ́dì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá—Olúwa ní kí arákùnrin Járẹ́dì ó sọ bí ìmọ́lẹ̀ yíò ṣe tàn nínú àwọn ọkọ̀ ìgbájá nã.

1 O sì ṣe tí Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ìdílé wọn, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn, sọ̀kalẹ̀ lọ sínú àfonífojì èyítí ó wà ní ìhà apá àríwá, (orúkọ àfonífojì nã sì ni Nímrọ́dù, nítorítí a sọ ọ́ ní orúkọ ọdẹ alágbára nnì) pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn tí wọn ti kójọ papọ̀, akọ àti abo, ní onírúurú.

2 Wọn sì dọdẹ pẹ̀lú láti mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn sì pèsè ohun èlò kan nínú èyítí wọn kó àwọn ẹja inú omi sí dani pẹ̀lú wọn.

3 Wọn sì kó àwọn désérẹ́tì dání, ìtumọ̀ èyítí í ṣe oyin ìgàn; bayĩ sì ni wọn kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oyin dánì, àti onírúurú àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, onirũru irúgbìn gbogbo pẹ̀lú.

4 O sì ṣe nígbàtí wọ́n tí sọ̀kalẹ̀ sínú afonifojì Nímrọ́dù tan Olúwa sọ̀kalẹ̀ wá bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀; ó sì wà nínú ìkúukũ, arákùnrin Járẹ́dì kò sì rí i.

5 O sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó lọ sínú aginjù, bẹ̃ni, sínú agbègbè ibiti ènìyàn kò dé rí. O sì ṣe tí Olúwa lọ níwájú wọn, ó sì bá wọn sọrọ bí òun ṣe dúró nínú ìkùukũ, o sì sọ fún wọn ibití wọn yio rìn ìrìnajo si.

6 O sì ṣe tí wọn rìn ìrìnàjò nínú aginjù, tí wọ́n sì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá, nínú èyítí wọ́n là ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi nlá kọjá, a sì ndari wọn títí nípa ọwọ́ Olúwa.

7 Olúwa kò sì gbà fún wọn láti dúró ní ìkọjá òkun tí ó wà nínú aginjù, sugbọn ó fẹ́ kí wọn ó jáde wá àní sínú ilẹ̀ ìlérí, èyítí ó jẹ́ àṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ, èyítí Olúwa Ọlọ́run ti fi pamọ́ dè àwọn ènìyàn olódodo.

8 O sì ti búra nínú ìbínú rẹ̀ pẹ̀lú arákùnrin Járẹ́dì, pé ẹnití yíò bá ni ilẹ̀ ìlérí yĩ ní ìní, láti igba nã lọ titi láé, gbọ́dọ̀ sìn òun, Ọlọ́run kanṣoṣo tí í ṣe otitọ, tabi kí a gbawọ́n dànù nígbàtí èkúnrẹ́rẹ́ ìbínú rẹ̀ yíò dé bá wọn.

9 Àti nísisìyí, a lè ri àwọn ìpinnu Ọlọ́run nipa ilẹ̀ yĩ, pe ilẹ̀ ìlérí ni; àti pé ọrílẹ̀ èdè èyíówù ti ó bá ní i ní ìní yíò sìn Ọlọ́run, bíkòṣebẹ̃ a ó gbáwọn dànù nígbàtí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbínú rẹ̀ yíò dé bá wọn. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbinu rẹ̀ yíò sì dé bá wọn nígbàtí wọ́n bá ti gbó nínú àìṣedẽdé.

10 Nítorí ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ yĩ jẹ́ èyítí a ṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ; nítorí èyí ẹnití ó bá ní i ní ìní yíò sìn Ọlọ́run bikosebẹ̃ a ó gbáwọn dànù; ó sì jẹ́ àṣẹ Ọlọ́run títí ayé. A kò sì ni gbáwọn dànù, bikòṣe ní àkókò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ aiṣedede lãrín àwọn ọmọ inu ilẹ̀ nã.

11 Eleyi sì tọ̀ yín wa, A! ẹyin Kèfèrí, kí ẹyin ó lè mọ̀ àṣẹ Ọlọ́run—kí ẹyin o lè ronúpìwàdà, àti láti má tẹ̀síwájú nínú àwọn àìṣedédé yín di ìgbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ yíò dé, kí ẹyin ó máṣe mú ẹkunrẹrẹ ìbínú Ọlọ́run dé bá yín gẹ́gẹ́bí àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ nã ti ṣe ní ìgbà ìṣájú.

12 Ẹ kíyèsĩ, ilẹ̀ aṣayan ni eyí jẹ́, orílè èdè èyíkéyĩ tí yíò ní i ní ìní yíò wà ní òmìnira kúrò nínú ìdè, àti kúrò nínú ìgbèkùn, àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn orilẹ ede miràn lábẹ́ ọ̀run, bí wọn yio bà sìn Ọlọ́run ilẹ nã, ẹnití í ṣe Jésù Krístì, ẹniti á ti fihàn nípa àwọn ohun tí àwa ti kọ.

13 Àti nísisìyí emí tẹ̀síwájú pẹ̀lú àkọsílẹ̀ mi; nitori kíyèsĩ, o sì ṣe tí Olúwa sì mú Járẹ́dì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde àní dé òkun nla nnì èyítí ó pín àwọn ilẹ̀ nã. Bí wọn sì ti dé ibi òkun nã wọn pàgọ́ wọn; wọ́n sì pè orukọ ibẹ̀ ni Moriánkúmérì; wọ́n sì ngbé inú àgọ́, wọ́n sì gbé inú àgọ́ leti òkun fún ìwọ̀n ọdún mẹrin.

14 O sì ṣe ni òpin ọdún mẹ́rin ni Olúwa tún wá sí ọ́dọ̀ arákùnrin Járẹ́dì, tí ó sì duro nínú ìkũkũ tí ó sì bá a sọ̀rọ. Fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta ni Olúwa bá arákùnrin Járẹ́dì sọ̀rọ̀, tí ó sì bá a wí nítorípé kò rántí láti kígbe pè orúkọ Olúwa.

15 Arákùnrin Járẹ́dì sì ronúpìwàdà ohun búburú tí ó ti ṣe, ó sì kígbe pè orukọ Olúwa nitori àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wọn wà pẹ̀lú rẹ̀. Olúwa sì wí fún un pe: Ẹmí yíò dáríjì ọ́ àti àwọn arákùnrin rẹ níti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; sùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ dẹ́ṣẹ̀ mọ́, nítorítí ìwọ gbọ́dọ̀ ranti pé Ẹ̀mí mi ki yíò bá ènìyàn jà ìjàkadì títí; nítorí eyi, bí ìwọ yíò bá dẹ́ṣẹ̀ titi ìwọ yíò fi gbó nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, a ó ké ọ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa. Àwọn wọ̀nyí sì ní èrò mi nipa ilẹ̀ tí emí yíò fi fún ọ́ fún ìní rẹ; nítorítí yíò jẹ ilẹ̀ àsàyàn jù ilẹ̀ gbogbo lọ.

16 Olúwa sì wípe: Lọ ṣiṣẹ́ kí ó sì kàn, ní ọ̀nà kannã tí ìwọ kàn àwọn okọ̀ ìgbájá ní ìgbà iṣaju. O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì sì lọ ṣiṣẹ́, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n sì kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá ní ọ̀nà kannã tí wọn tí kàn wọ́n ní igbà ìṣajú, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti fi kọ́ wọn. Wọ́n sì kéré, wọn sì fúyẹ́ lórí omi, àní bí ẹyẹ ti ifúyẹ́ lórí omi.

17 A sì kàn wọ́n lọ́nà tí omi kò lè jò jáde kúrò nínú wọn, àní ti wọ́n gbà omi dúró bí àwo; abẹ rẹ̀ kò sì lè jò omi jáde bí ti àwo; àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sí lè jò omi jáde bí ti àwo; àwọn igun rẹ̀ sì rí ṣónṣó; ori rẹ̀ kò sí lè jò omi jáde bí tí àwo; gígùn rẹ̀ sì tó gígùn igi; ilẹ̀kùn rẹ̀, nígbàtí wọn tì í, kò sì lè jò omi jáde bí ti àwo.

18 O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa, tí ó wípé: A! Olúwa, emí ti ṣe iṣẹ́ èyítí ìwọ pa láṣẹ fun mi, emí sì ti kàn àwọn ọkọ̀ ìgbájá nã gẹgẹbi ìwọ ti tọ́ mi sọ́nà.

19 Sì kíyèsĩ, A! Olúwa, kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú wọn; níbo ni àwa yio tukọ̀ lọ? Àti pẹ̀lú àwa yíò parun, nítorípé àwa kò lè mí nínú wọn, bíkòṣepé afẹ́fẹ́ wà nínú wọn; nitorinã àwa yíò parun.

20 Olúwa sì wí fún arákùnrin Járẹ́dì pe: Kíyèsĩ, ìwọ yíò dá ihò lu sí ori rẹ̀ àti pẹ̀lú ní abẹ́ rẹ; nígbàtí ìwọ bá sì ṣaláìní afẹ́fẹ́ ìwọ yíò ṣí ihò nã sílẹ̀ kí ó sì rí afẹ́fẹ́ gbà. Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí omi wọle bá yín, kíyèsĩ, ìwọ yíò dí ihò nã, kí ìwọ ó ma bã parun nínú ìró omi nã.

21 O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì ṣe bẹ̃, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pa láṣẹ.

22 O sì tún kígbe pe Olúwa wípé: A! Olúwa, kíyèsĩ emí ti ṣe é àní bí ìwọ ti pa á láṣẹ fún mi; emí sì ti pèsè àwọn ọkọ̀ nã sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi, sì kíyèsĩ kò sí ìmọ́lẹ̀ ní inú wọn. Kíyèsĩ, A! Olúwa, njẹ ìwọ ó ha jẹ́ kí àwa ó là agbami nla yĩ kọjá nínú okùnkùn bí?

23 Olúwa sì wí fún arákùnrin Járẹ́dì pe: Kíni ìwọ fẹ kí emí ó ṣe kí ìwọ́ o lè ní imọlẹ nínú àwọn ọkọ̀ rẹ? Nitori kíyèsĩ, ìwọ kò lè ní fèrèsé, nítorítí wọn ó fọ́ sí wẹ́wẹ́, bẹ̃ni iwọ́ kò gbọ́dọ̀ gbé ina lọ́wọ́ pẹlú rẹ, nítorí ìwọ kò gbọ́dọ̀ lọ niti ìmọ́lẹ́ iná.

24 Nitori kíyèsĩ ìwọ yíò rí bí erinmi lãrín òkun; nitori àwọn ìrú ìbìlù omi gíga yíò kọlũ yín. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, emí yíò padà mú ọ jáde kúrò nínú ìsàlẹ̀ okun nã; nítorítí láti ẹnu mi wá ni àwọn èfũfù ti jáde wá, àti àwọn òjò àti àwọn ìró omi, èmi ni ó rán wọn.

25 Sì kíyèsĩ, emí ti pèsè rẹ sílẹ̀ de àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí ìwọ kò lè kọjá nínú ọ̀gbun nla yĩ afi bí emí bá pèsè rẹ sílẹ̀ dè àwọn ìbìlù omi òkun, àti àwọn èfũfù tí ó ti jáde lọ, àti àwọn iro omi ti yíò wã. Nitorinã kini ìwọ fẹ́ kí emí ó pèsè fún ọ kí ìwọ ó lè ní ìmọ́lẹ̀ nígbàtí ó bá wà ni gbígbémì nínú ìsàlẹ̀ òkun?