Orí 14
Àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, mú ègún wá sí órí ilẹ̀ nã—Kóríántúmúrì wọnú ogun lọ pẹ̀lú Gíléádì, lẹ́hìnnã Líbù, àti lẹ́hìnnã Ṣísì—Ẹjẹ̀ àti ìpakúpa ènìyàn bò ilẹ̀ nã.
1 Àti nísisìyí ègun nlá kan bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã nítorí àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, nínú èyítí bí ẹnikẹ́ni bá fi ohun èlò rẹ̀ tàbí idà rẹ̀ sílẹ̀ lórí pẹpẹ rẹ̀, tàbí lórí ibití óun nfií pamọ́ sí, ẹ kíyèsĩ, ní ọjọ́ kejì, kò ní ríi mọ́, bẹ̃ ni ègún tí ó wà lórí ilẹ̀ nã pọ̀ tó.
2 Nítorí èyí olukúlùkù dì èyítí í ṣe tirẹ̀ mú, mọ́ ọwọ ara rẹ̀, tí kò sì tọrọ lọ́wọ́ ènìyàn bẹ̃ni kò yá ènìyàn ní ohunkan; olukúlùkù sì mú èkù idà rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọwọ òtún rẹ̀, ní ìdábòbò ohun ìní rẹ̀ àtí ẹ̀mí ara rẹ̀ àti ti àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Àti nísisìyí, lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún méjì, àti lẹ́hìn ikú Ṣárẹ́dì, ẹ kíyèsĩ, arákùnrin Ṣárẹ́dì dìde ó sì gbé ogun tì Kóríántúmúrì, nínú èyítí Kóríántúmúrì nàa tí ó sì lée lọ sínú aginjù Ákíṣì.
4 Ó sì ṣe tí arákùnrin Ṣárẹ́dì sì gbe ogun tì í nínú aginjù Ákíṣì; ogun nã sì gbóná gidigidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ní wọ́n sì fi idà pa.
5 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì sì ká a mọ́ inú aginjù, arákùnrin Ṣárẹ́dì sì kọjá lọ jáde kúrò nínú aginjù ní òru, ó sì pa nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì, nítorípé wọ́n tí mutí yó.
6 Ó si wá sínú ilẹ̀ Mórọ̀n, ó sì fi ara rẹ̀ sí órí ìtẹ́ Kóríántúmúrì.
7 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì ngbé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nínú aginjù fún ìwọ̀n ọdún méjì, nínú èyítí ó rí àwọn ọmọ ogun púpọ̀ síi.
8 Nísisìyí arákùnrin Ṣárẹ́dì, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Gíléádì, pẹ̀lú rí àwọn ọmọ ogun púpọ̀ síi, nítorí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn.
9 Ó si ṣe tí olórí àlùfã rẹ̀ pã bí ó ti jóko lórí ìtẹ́ rẹ̀.
10 Ó sì ṣe tí ọ̀kan nínú àwọn egbẹ́ òkùnkùn nã pa lójú ọ̀nà kọ̀rọ̀ kan, ó sì gbà ijọba nã tìkárarẹ̀; orúkọ rẹ̀ sì ni Líbù; Líbù sì jẹ ènìyan tí ó ga púpọ̀, jù ẹnikẹ́ni lọ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn nã.
11 Ó sì ṣe nínú ọdún èkíní ìjọba Líbù, Kóríántúmúrì gòkè wá sínú ilẹ̀ Mórọ̀n, ó sì gbé ogun tì Líbù.
12 Ó sì ṣe tí ó bá Líbù jà, nínú èyítí Líbù ṣáa ní apá rẹ̀ tí ó sì gbọgbẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì tẹ̀lé Líbù, tí ó sì sálọ sí ibi agbègbè etí-ìlu ní etí òkun.
13 Ó sì ṣe ti Kóríántúmúrì sá tẹ̀lée; Líbù sì gbé ogun tĩ ní etí òkun.
14 Ó sì ṣe tí Líbù sì lù ẹgbẹ ọmọ ogun Kóríántúmúrì, tí wọ́n sì tún sá sínú aginjù Ákíṣì.
15 Ó sì ṣe tí Líbù sì sá tèlée títí ó fi dé ibi àwọn ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ti Ágọ́ṣì. Kóríántúmúrì sì ti kó gbogbo àwọn ènìyàn nã pẹ̀lú rẹ̀ bí ó ti salọ níwájú Líbù ní agbègbè ilẹ̀ tí ó sálọ sí.
16 Nígbàtí ó sì dé ibi àwọn ilẹ tí ó tẹ́jú ti Ágọ́ṣì, ó gbé ogun tì Líbù, ó sì fí idà sáa títí ó fi kú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, arákùnrin Líbù sì dojúkọ Kóríántúmúrì dípò rẹ̀, ogun nã sì dì èyítí ó gbóná gidigidi, nínú èyítí Kóríántúmúrì tún sa kúrò níwájú ọmọ ogun arákùnrin Líbù.
17 Nísisìyí orúkọ arákùnrin Líbù ni Ṣísì. Ó sì ṣe tí Ṣísì sá tẹ̀lé Kóríántúmúrì, ó sì ṣẹ́gun ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, ó sì pa àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, ó sì sun àwọn ìlú-nlá nã níná.
18 Ìbẹ̀rù fún Ṣísì sì lọ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, igbe kan tàn jákè-jádò ilẹ̀ nã pe—Tani ó lè dúró níwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì? Ẹ́ kíyèsĩ, ó gbá ilẹ̀ ayé níwájú rẹ̀!
19 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí wọ́ pọ̀ nínú agbo, jákè-jádò gbogbo orí ilẹ̀ nã.
20 Wọ́n sì pínyà; apá kan nínú wọn sì sá sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì, apá kan sì sá sínú egbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì.
21 Ogun nã sì pọ̀ ọjọ́ rẹ̀ sì pẹ́, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìpànìyàn nípakúpa nã sì wà fún ọjọ́ pípẹ́, ti ara àwọn òkú ènìyàn bò gbogbo orí ilẹ̀ nã.
22 Ogun nã sì ṣe kánkán tí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó kù láti sin àwọn òkú, sùgbón wọ́n ntẹ̀síwájú láti ìtàjẹ̀sílẹ̀ dé ìtàjẹ̀sílẹ̀, tí wọ́n sì nfi àwọn ara àti ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé sílẹ̀ ní fífọ́nká lórí ilẹ̀ nã, láti di onjẹ fún àwọn ìdin tí íjẹ ẹran ara.
23 Òórùn rẹ̀ sì tàn ká orí ilẹ̀ nã, àní ká orí gbogbo ilẹ̀ nã; nítorí èyí àwọn ènìyàn nã ní ìpọ́njú ní ọ̀san àti ní òru, nítorí õrùn rẹ̀.
24 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ṣísì kò dẹ́kun láti lé Kóríántúmúrì; nítorítí ó tí búra láti gbèsan lára Kóríántúmúrì níti ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ̀, ẹnití ó ti pa, àti ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ̀ Étérì wá pé a kò ní fi idà pa Kóríántúmúrì.
25 Àti báyĩ àwa ríi pé Olúwa bẹ̀ wọ́n wò ní ẹ̀kún ìbínú rẹ̀, àwọn ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra wọn ní ó ti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún ìparun wọn títi ayé.
26 O si ṣe tí Ṣísì sì lé Kóríántúmúrì lọ sí apá ìlà-oòrùn, àní dé ibi etí-ìlú tí ó wà ní etí-òkun, níbẹ̀ ní ó sì gbé ogun tì Ṣísì fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta.
27 Ìparun tí ó wà lãrín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì sì burú tóbẹ̃ tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sálọ níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì; wọ́n sì sálọ sínú ilẹ̀ Kóríhọ̀, wọ́n sì gbá gbogbo àwọn tí ngbé inú rẹ̀ níwájú wọn, gbogbo àwọn tí kò darapọ̀ mọ́ wọn.
28 Wọ́n sì pàgọ́ wọn sínu àfonífojì Kóríhọ̀; Kóríántúmúrì sì pàgọ́ rẹ̀ sínú àfonífoji Ṣũrì. Nísisìyí àfonífojì Ṣũrì súnmọ́ òkè Kómnórì, nítorí èyí, Kóríántúmúri sì ko àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ lórí òkè Kómnórì, ó sì fọn fèrè sí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun Ṣísì láti pè wọ́n sí ìjà.
29 Ó sì ṣe ti wọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún lé wọn padà; wọ́n sì wá ní ìgbà kejì, wọ́n sì tún lé wọn padà ní ìgbà keji. Ó sì ṣe ti wọn tún wá ní ìgbà kẹta, ogun nã sì gbóná gidigidi.
30 O si ṣe tí Ṣísì fi idà ṣá Kóríántúmúrì tí ó sì ṣá a lọ́gbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; Kóríántúmúrì nítorípé ó pàdánù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, o sì dákú, wọ́nsì gbé e lọ bí ẹnití ó kú.
31 Nísisìyí àdánù lórí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní apá méjẽjì pọ̀ púpọ̀ tí Ṣísì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó má sátẹ̀lé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì mọ́, nítorí èyí, wọ́n padà sí ibùdó wọn.