Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 1


Ìwé ti Étérì

Àkọsílẹ̀ àwọn ara Járẹ́dì, èyítí a mú láti inú àwọn àwo mẹ́rìnlélogun tí àwọn ènìyàn Límháì ri ní ìgbà ọba Mòsáíàh.

Orí 1

Mórónì ṣe àkékúrú àwọn ohun tí Étérì kọ—A tò ìtàn ìdílé Etérì lẹ́sẹlẹ́sẹ—A kò da èdè àwọn ara Járẹ́dì rú ni Ile-ìṣọ́ Bábélì—Olúwa ṣe ìlérí láti siwaju wọn dé ilẹ̀ daradara, yíò sì ṣe wọn ní orílẹ̀-èdè nlá.

1 Àti nísisìyí emí, Mórónì, tẹ̀síwájú láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn olugbe àtijọ nnì tí a parun nípa ọwọ́ Oluwa nínú orílè-èdè apá àríwá yĩ.

2 Emí sì mu ọ̀rọ̀ mi láti inú àwọn àwo mẹ́rìnlélógún nnì ti àwọn ènìyàn Límháì rí, èyítí wọn pè ni Ìwé ti Étérì.

3 Bí mo sì ti lero pé apá kinni akọsile yĩ, èyítí ó sọ̀ nípa ìdásílẹ̀ ayé, àti nipa ti Ádámù, àti ọ̀rọ̀ láti ìgbà nã àní titi ó fi de ti ile-ìṣọ́ nla nã, àti ọ̀rọ̀ nipa ohunkóhun tí ó ṣẹ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn titi di igba nnì, ní o kọ lãrín àwọn Jũ—

4 Nitorinã, emí kò kọ àwọn ohun wọnnì tí ó ti ṣẹ̀ láti ìgbà Ádámù títí de ìgbà nnì; ṣùgbọ́n a kọ wọn lé ori àwọn àwo; ẹnikẹ́ni ti o bá sì rí wọn, oun nã ni yíò ní agbára láti gbà àkọsílẹ̀ ọrọ nã lẹ́kùnrẹ́rẹ́.

5 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi kò kọ àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ nã lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ nã ni èmi kọ, láti àkókò kíkọ́ ile-ìṣọ́ nnì titi dé àkókò tí a fi pa wọ́n run.

6 Ni ti ọ̀nà yĩ sì ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ nã. Ẹniti ó kọ àkọsílẹ̀ yĩ ni Étérì, ó sì jẹ́ ìran Koriántórì.

7 Koriántórì ni ọmọ Mórọ̀n.

8 Mórọ̀n sì ni ọmọ Étémù.

9 Étémù sì ni ọmọ Áháhì.

10 Áháhì sì ni ọmọ Sétì.

11 Sétì sì ni ọmọ Ṣíblọ́nì.

12 Ṣíblọ́nì sì ni ọmọ Kọ́mù.

13 Kọ́mù sì ni ọmọ Koríántúmù.

14 Koríántúmù sì ni ọmọ Ámnígádà.

15 Ámnígádà sì ni ọmọ Áárọ́nì.

16 Áárọ́nì sì jé ìran Hẹ́tì, ẹnití í ṣe ọmọ Héátómì.

17 Héátómì sì ni ọmọ Líbù.

18 Líbù sì ni ọmọ Kíṣì.

19 Kíṣì sì ni ọmọ Kórómù.

20 Kórómù sì ni ọmọ Léfì.

21 Léfì sì ni ọmọ Kímù.

22 Kímù sì ni ọmọ Moríántọ́nì.

23 Moríántọ́nì sì jẹ́ ìran Ríplákíṣì.

24 Ríplákíṣì sì ni ọmọ Ṣẹ́sì.

25 Ṣẹ́sì sì ni ọmọ Hẹ́tì.

26 Hẹ́tì sì ni ọmọ Kọ́mù.

27 Kọ́mù sì ni ọmọ Koríántúmù.

28 Koríántúmù sì ni ọmọ Émérì.

29 Émérì sì ni ọmọ Ómérì.

30 Ómérì sì ni ọmọ Ṣúlè.

31 Ṣúlè sì ni ọmọ Kíbù.

32 Kíbù sì ni ọmọ Òríhà, ẹniti í ṣe ọmọ Járẹ́dì;

33 Járẹ́dì èyítí ó jáde wá pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn míràn àti àwọn ìdílé wọn, láti ile-ìṣọ́ nla nnì, ní àkókò ti Olúwa dà èdè àwọn ènìyàn nã rú, tí ó sì búra nínú ìbínú rẹ̀ pé oun yíò fọn wọn ká kiri orí ilẹ̀ ayé; àti gẹ́gẹ́bí ọrọ Olúwa, a sì fọ́n àwọn ènìyàn nã ká.

34 Àti pe arákùnrin Járẹ́dì nítorípé o jẹ ènìyàn títóbí tí ó sì lágbára, àti ẹniti o rí oju rere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀, Járẹ́dì, arákùnrin rẹ̀, wí fún ún pé: Kígbe pé Olúwa, kí ó máṣe dà èdè wa rú kí àwa o sì ṣe àìgbọ́ ọ̀rọ̀ ara wa.

35 O sì ṣe tí arákùnrin Járẹ́dì kígbe pe Olúwa, Olúwa sì ṣãnú fún Járẹ́dì; nitorinã ni òun kò sì dà èdè Járẹ́dì rú; òun kò sì dà Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ rú.

36 Nígbànã ni Járẹ́dì wi fun arákùnrin rẹ̀ pé: Tún kígbe pè Olúwa bí yíò bá mú ìbínú rẹ̀ kúrò lórí àwọn tí wọn jẹ ọ̀rẹ́ wa, kí ó má sì dà èdè wọn rú.

37 O sì ṣe ti arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa, Olúwa sì ṣãnú fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú, tí òun kò sì dà wọ́n rú.

38 O sì ṣe ti Járẹ́dì tún bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀, tí ó wípé: Lọ kí ó sì bẽrè lọ́wọ́ Olúwa bóyá òun yíò lé wa kuro nínú ilẹ nã, bí òun yíò bá sì lé wa kúrò nínú ilẹ̀ nã, kígbe pè é nípa ibití àwa yíò lọ. Tani ó sì lè mọ̀ bóyá Olúwa yíò gbe wa lọ sínú ilẹ̀ èyítí ó dára jù lórí gbogbo ilẹ tí ó wà nínú ayé? Bí ó bá sì rí bẹ̃, ẹ jẹ́ kí àwa ó jẹ́ olótĩtọ́ sí Olúwa, kí àwa ó lè rí í gbà fún ìní wa.

39 O sì ṣe ti arákùnrin Járẹ́dì kígbe pè Olúwa gẹ́gẹ́bí èyítí Járẹ́dì ti sọ fún un kí ó ṣe.

40 O sì ṣe tí Olúwa gbọ́ arákùnrin Járẹ́dì, ó sì ṣãnú fún un, ó sì wi fún un pe:

41 Lọ, kí o sì kó àwọn ọ̀wọ́ ẹ́ran rẹ jọ, àti akọ àti abo, kí ó sì mú lára gbogbo wọn ní onírúurú, àti pẹ̀lú nínú àwọn èso ayé gbogbo ni onírúurú; àti àwọn ìdílé rẹ; àti pẹ̀lú Járẹ́dì arákùnrin rẹ àti ìdílé rẹ̀; àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn ìdile wọn; àti àwọn ọ̀rẹ́ Járẹ́dì àti àwọn ìdílé wọn.

42 Nígbàtí ìwọ bá sì ti ṣe báyĩ, ìwọ yíò lọ níwájú wọn, kọjá lọ sínú àfonífojì èyítí o wà ní ìhà apá àríwá. Níbẹ̀ ni èmi yíò sì pàdé rẹ, èmi yíò sì lọ níwájú rẹ sí inú ilẹ̀ èyítí ó dára jù gbogbo ilẹ̀ tí ó wà nínú ayé.

43 Níbẹ̀ ni èmi yíò sì bùkún fún ọ àti irú ọmọ rẹ, emí ó sì gbé orílẹ̀ èdè nla soke si mi nínú irú ọmọ rẹ, àti nínú irú ọmọ arákùnrin rẹ, àti àwọn tí wọn yíò lọ pẹ̀lú rẹ. Kì yíò sì sí èyítí yíò tobi jù orilẹ ede tí emí yíò gbé dide fún èlò mi láti inú irú ọmọ rẹ, lórí ilẹ̀ ayé gbogbo. Báyĩ sí ni èmi yíò ṣe sí ọ nítorípé fun ìgbà pípẹ́ yĩ ni ìwọ́ fi kígbe pè mí.