Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 4


Orí 4

Olúwa pàṣẹ fún Mórónì láti dì àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì kọ ní èdìdí—À kò ni fí wọ́n hàn titi àwọn ènìyàn yíò fi ní ìgbàgbọ́ àní bí ti arákùnrin Járẹ́dì—Krístì paṣẹ fún àwọn ènìyàn kí wọn ó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ gbọ—A pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà, gbà ìhìn-rere gbọ́, kí wọn ó sì di ẹni ìgbàlà.

1 Olúwa sì pàṣẹ fún arákùnrin Járẹ́dì láti sọ̀kalẹ̀ lọ kúrò lórí òkè nã kuro níwájú Olúwa, kí ó sì kọ àwọn ohun tí ó ti rí; a sì kã lẽwọ̀ láti mú wọn wá sí òdọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn titi di ẹ̀hìn ìgbà ti a ó gbé e sókè lórí àgbélebú; nítorí ìdí èyi sì ni ọba Mòsíà fi pa wọ́n mọ́, pé kí wọn ó ma jáde sí ayé titi di ẹ̀hìn ìgbà tí Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn si àwọn ènìyàn rẹ̀.

2 Àti lẹ́hìn tí Krístì sì ti fi ara rẹ̀ hàn nítõtọ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó pàṣẹ pé kí wọn ó fi wọn hàn sí wọn.

3 Àti nísisìyí, lẹ́hìn àkókò nã, gbogbo wọn ni ó ti rẹ̀hìn nínú igbàgbọ́; kò sì sí ẹnikẹ́ni afi àwọn ará Lámánì, àwọn nã ti kọ̀ ìhìn-rere Krístì; nitorinã a pa á láṣẹ fún mi pe, kí èmi ó tún gbé wọn pamọ́ sínú ilẹ̀.

4 Ẹ kíyèsĩ, mo ti kọ àwọn ohun nã sí ori àwọn àwo yĩ, àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì rí; kò sì sí ohun tí ó tóbi tó báyĩ rí tí a fihàn tó àwọn ohun tí a fíhàn sí arákùnrin Járẹ́dì.

5 Nítorí èyí Olúwa ti pa á láṣẹ fún mi láti kọ wọ́n; emí sì ti kọ wọ́n. O sì paṣẹ fún mi pé ki èmi ó dì wọn ní èdìdí; ò sì tún ti pàṣẹ pé kí èmi ó dì itumọ̀ rẹ̀ ní èdìdí; nítorí eyi ni èmi ṣe dì àwọn atúmọ̀ ní èdìdí, gẹ́gẹ́bí àṣẹ Olúwa.

6 Nítorítí Olúwa wí fún mi pé: Wọn kò ní jáde lọ si ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí titi dí ọjọ nã tí wọn yíò ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn, tí wọn ó sì di aláìléerí níwájú Olúwa.

7 Àti ní ọjọ́ nã nínú èyítí wọ̀n yíò fi ìgbàgbọ́ bá mi lò, ni Olúwa wí, àní bí arákùnrin Járẹ́dì ti ṣe, kí wọn ó lè di ìyásímímọ́ nípasẹ̀ mi, nígbànã ní emí yíò fí àwọn ohun tí arákùnrin Járẹ́dì ti rí hàn sí wọn, àní de fífihàn sí wọn gbogbo àwọn ìfihàn mi, ni Jésù Krístì wí, Ọmọ Ọlọ́run, Baba àwọn ọ̀run àti ti ayé, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn.

8 Ẹnití yíò bá sì bá ọ̀rọ̀ Olúwa jà, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú; ẹniti yíò bá sì sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú; nítorítí èmí kò ní fi ohun tí ó tóbi jù èyĩ lọ hàn sí wọn, ni Jésù Krístì wí; nítórítí emí ni ẹni nã ẹnití nsọ̀rọ̀.

9 Àti ní àṣẹ mi àwọn ọ̀run dì ṣíṣísílẹ̀ àtí pípadé; àti ní ọ̀rọ̀ mi ayé yíò mì; àti ní àṣẹ mi àwọn ẹnití ngbé inú rẹ̀ yíò kọjá lọ, àní bí ẹni pé nípasẹ̀ iná.

10 Àti ẹnití kò bá gbà àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́ kò gbà àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi gbọ́; bí ó bá sì rí bẹ̃ pé èmi kò sọ̀rọ̀, ẹ dájọ́; nítorítí ẹyin yíò mọ̀ pé èmi ní ẹninã tí ó sọ̀rọ̀, ní ọjọ́ ìkẹhìn.

11 Sugbọn ẹnití ó bá gbà àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti sọ gbọ́, òun ni emí yíò bẹ̀wò pẹ̀lú ìṣípayá Ẹmí mi, òun yíò sì mọ̀ yíò sì ṣe ìjẹ́risí rẹ̀. Nitori ti Ẹ̀mi mi ni òun yíò mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí wọn a máa yí ọkàn àwọn ènìyàn padà láti ṣe rere.

12 Ohunkóhun tí ó bá sì nyí ọkàn àwọn ènìyan padà láti ṣe rere wá láti ọwọ́ mi; nitoripe rere ko wá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni bíkòṣe láti ọwọ́ mi. Èmi kannã ni ó ndarí àwọn ènìyàn láti ṣe rere; ẹnití kò bá ní gbà àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́ kì yíò gbà mí gbọ́—pé èmi ni; ẹnití kò bá sì gbà mí gbọ́ kì yíò gbà Baba gbọ́ ẹnití ó rán mi. Nítorí kíyèsĩ, èmi ni Baba, èmi ni ìmọ́lẹ̀, àti ìyè, àti òtítọ́ ayé.

13 Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, A! ẹ̀yin Kèfèrí, emí yíò si fi àwọn ohun tí ó tóbijù hàn sí yín, imọ nã èyítí a ti gbé pamọ́ nítorí àìgbàgbọ́.

14 Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, A! ẹ̀yin ìdílé Ísráẹ́lì, a ó sì fi hàn sí ọ bí Baba ti ṣe ìpèsè àwọn ohun nlá fún ọ, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; kò sì di ìfihàn sí ọ, nitorí àìgbàgbọ́.

15 Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí ẹ̀yin bá fà ìbòjú àìgbàgbọ́ nnì ya èyítí ó mú ki ẹ̀yin ó wà nínú ipò ìwà búburú yin nnì, àti ọkàn tí ó sé le, àti ọkàn tí ó fọ́jú, nígbànã ni àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu tí a ti gbé pamọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé kúrò lọ́dọ̀ yín—bẹ̃ni, nígbàtí ẹ̀yin bá ké pé Bàbá ní orúkọ mi, pẹ̀lú ìrora ọkàn àti èmí ìròbìnújẹ́, nígbànã ní ẹ̀yin yio mọ̀ pé Bàbá ti rántí májẹ̀mú nã èyítí ó ti bá àwọn baba yín da, A! ìwọ idile Isráẹ́lì.

16 Nigbanã ni àwọn ìfihàn mi èyítí mo ti mú kí ìránṣẹ́ mi Jòhánnù ó kọ yíò si di fífihàn ní kedere sí gbogbo ènìyàn. Ẹ rántí, nígbàtí ẹ̀yin bá rí àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé àkókò nã ti dé tán tí wọn yíò di mímọ̀ nínú ìṣe tí ó lágbára.

17 Nitorinã, nígbàtí ẹ̀yin yíò gbà àkọsílẹ̀ yĩ ẹ̀yín yíò mọ̀ pé iṣẹ́ Baba ti bẹ̀rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀.

18 Nítorínã, ẹ ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, kí ẹ sì wá sí ọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì gbà ìhìn-rere mi gbọ́, kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yin ní orúkọ mi; nítorítí ẹnití ó bá gbàgbọ́ tí a sì ṣe ìrìbọmi fún ni à ó gbàlà; sùgbọ́n ẹnití kò bá gbàgbọ́ ni a ó dálẹ́bi; àwọn àmì yíò sì máa tẹ̀lé àwọn tí ó gbà orukọ mi gbọ́.

19 Alábùkún-fún sì ni ẹni nã tí ó bá wà ní ìsòtítọ́ sí orukọ mi ni ọjọ́ ìkẹhìn, nítorítí a ó gbé e sókè láti máa gbé nínú ìjọba ti a ti pèsè sílẹ̀ fún un láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Ẹ sì kíyèsĩ èmi ni ó wíi. Àmín.