Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 6


Orí 6

Afẹ́fẹ́ gbé àwọn ọkọ̀ ìgbájá àwọn ara Járẹ́dì lọ́ sì ilẹ̀-ìlérí—Àwọn ènìyan nã yìn Olúwa fún ore rẹ̀—A yàn Òríhà bí ọba lé wọn lórí—Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ kú.

1 Àti nísisìyí emí, Mórónì, tẹ̀síwájú láti sọ nípa àkọsílẹ̀ nipa Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀.

2 O sì ṣe lẹ́hìn tí Olúwa ti pèsè àwọn òkúta wẹ́wẹ́ èyítí arákùnrin Járẹ́dì ti gbé lọ sí ori òkè, arákùnrin Járẹ́dì sọ̀kalẹ̀ lọ kúrò lórí òkè nã, ó sì kó àwọn òkúta wẹ́wẹ́ nã lọ sínú àwọn ọkọ̀ nã èyítí wọ́n ti pèsè sílẹ̀, ọ̀kan ní ìpẹ̀kun kọ̃kan; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì tàn ìmọ́lẹ̀ sí inú àwọn ọkọ̀ nã.

3 Báyĩ si ni Olúwa mú kí àwọn òkúta wẹ́wẹ́ ó tàn nínú òkùnkùn láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, kí wọn ó má kọjá nínú omí nlá nã nínú òkùnkùn.

4 O sì ṣe nígbàtí wọ́n ti pèsè onírúurú onjẹ sílẹ̀, ti wọn ó jẹ nígbátí wọn bá wà lórí omi, àti onjẹ fún àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn, àti ẹranko-kẹ́ranko tàbí ẹyẹ-kẹ́yẹ tí wọn yíò kó pẹ̀lú wọn—ó sì ṣe nígbatí wọ́n ti ṣe gbogbo ohun wọ̀nyí wọn wọ̀ inú àwọn ọkọ̀ tabí àwọn ọkọ̀ ìgbájá wọn lọ, wọ́n ṣí jáde lọ sínú òkun, wọ́n sì fi ara wọn lé Olúwa Ọlọ́run wọn lọ́wọ́.

5 O sì ṣe tí Olúwa Olọ́run mú kí afẹ́fẹ́ tí ó lágbára ó fẹ́ lórí omi nã, sí apá ibití ilẹ̀-ìlérí nã wà; báyĩ sì ni a ngbá wọn kiri lórí ìbìlù-omi òkun nã níwájú afẹ́fẹ́.

6 O sì ṣe ti òkun bò wọn mọ́lẹ̀ nínú jíjìn rẹ̀ ní igba pupọ, nitori àwọn ìbìlù-omi gíga tí ó nbì jáde lórí wọn, àti àwọn ẹ̀fũfù líle nla ti nfẹ́ nítorítí afẹ́fẹ́ nã nfẹ ní lílelíle.

7 O sì ṣe nígbàtí a ti bò wọn mọ́lẹ̀ nínú jíjìn òkun nã kò sí omi ti ó lè pa wọ́n lara, nítorípé àwọn ọkọ̀ wọn kò lè jò omi jáde bí ti àwo, àti pẹ̀lú wọn kò lè jò omi àní gẹ́gẹ́bí bí ti ọkọ Nóà; nitorínã nígbàtí omi púpọ̀ yí wọn ká wọn sì kígbe pè Olúwa, òun sì mú wọn jáde padà sí órí omi nã.

8 O sì ṣe tí afẹ́fẹ́ nã kò dẹ́kun fífẹ́ sí apá íbití ilẹ̀-ìléri nã wà bí wọn ti wà lórí omi; bayĩ sì ni á ngbé wọ́n síwájú níwájú afẹ́fẹ́.

9 Wọ́n sì kọ orin ìyìn sí Olúwa; bẹ̃ni, arákùnrin Járẹ́dì sì kọ orin ìyìn sí Olúwa, ó sì dupẹ, o sì yìn Olúwa ní gbogbo ọjọ́; àti nígbati alẹ́ lẹ́, wọn kò ṣíwọ́ láti yìn Olúwa.

10 Bayĩ sì ni a gbé wọn lọ síwájú; tí kò sì sí ohun abàmì inú omi kan ti ó lè dá wọn dúró, tàbí erinmi tí ó lè pa wọ́n lára; wọ́n sì ní ìmọ́lẹ̀ títí, bóyá wọ́n wà ní orí omi ni tàbí ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.

11 Báyĩ sí ni a gbé wọn lọ síwájú, fún oji le lọ̃dunrun ọjọ́ ó lé mẹ́rin lórí omi nã.

12 Wọn sì gúnlẹ̀ ní èbúté ilẹ̀-ìlérí nã. Nígbàtí wọ́n sì ti fi ẹsẹ̀ wọn lé èbúté ilẹ̀-ìlérí nã wọn tẹ̀ orí wọn bá lórí ilẹ̀ nã, wọn sì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa, wọ́n sì sọkún fún ayọ̀ níwájú Olúwa, nitori ọ̀pọ̀ ìrọ́nú ãnú rẹ lórí wọn.

13 Ó sì ṣe tí wọn jáde lọ sí orí ilẹ̀ nã, wọn sì bẹ̀rẹ̀sí dáko.

14 Járẹ́dì sì ní àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin; a sì npè wọ́n ní Jákọ́mù, àti Gílgà, àti Máhà, àti Òríhà.

15 Arákùnrin Járẹ́dì nã sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

16 Àwọn ọrẹ Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ ènìyàn méjìlélógún; àwọn nã sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìrín kí wọn ó tó dé inú ilẹ̀-ìléri; àti nítori èyí wọ́n bẹ̀rẹ̀sí pọ̀sĩ.

17 A sì kọ́ wọn láti máa rìn nínú ìrẹ̀lẹ ọkàn níwájú Olúwa; a sì kọ́ wọn láti òkè ọrun wá.

18 O sì ṣe tí wọn bẹ̀rẹ̀sí tàn kálẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, wọn sì nbísĩ, wọn sì ndáko lórí ilẹ̀ nã; wọn sì ndi alágbára nínú ilẹ̀ nã.

19 Arákùnrin Járẹ́dì sì bẹ̀rẹ̀sí darúgbó, ó sì rí i pé òun fẹ́rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú; nítorí eyi ó wí fún Járẹ́dì pé: Jẹ́ kí àwa ó kó àwọn ènìyàn wa jọ kí àwa ó kà iye wọn, kí àwa lè mọ̀ láti ọwọ́ wọn ohun tí wọn fẹ kí àwa ó ṣe fún wọn kí a tó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú wa.

20 Bẹ̃ gẹ́gẹ́ ní wọ́n sì kó àwọn ènìyàn nã jọ. Nísisìyí iye àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin Járẹ́dì jẹ́ ènìyàn méjìlélógún; àti iye àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Járẹ́dì jẹ́ méjìla, òun sì ní ọmọkùnrin mẹ́rin.

21 O sì ṣe tí wọn kà iye àwọn ènìyàn wọ́n; àti nígbàtí wọn ti kà wọ́n tán, wọn bí wọ́n ni àwọn ohun tí wọn fẹ́ kí wọn ó ṣe ki wọn ó tó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ísà-òkú wọn.

22 O sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã fẹ́ kí wọn ó fi òróró yàn ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin wọn láti jẹ́ ọba lé wọn lórí.

23 Àti nísisìyí, èyí jẹ́ ohun tí ó bà wọ́n nínújẹ́. Arákùnrin Járẹ́dì sì wí fún wọn pé: Dájúdájú eleyĩ yíò já sí mímúni ní ìgbèkùn.

24 Sùgbọ́n Járẹ́dì wí fún arákùnrin rẹ̀ pé: Jẹ́ kí wọn ó ní ọba. Nítorínã ó sì wí fún wọn pé: Ẹ yàn láti inú àwọn ọmọkùnrin wa láti jẹ́ ọba, àní ẹniti ẹ̀yín bá fẹ́.

25 O sì ṣe tí wọ́n yàn àní àkọ́bí arákùnrin Járẹ́dì; orúkọ rẹ̀ sì ni Págágì. O sì ṣe tí ó kọ̀ tí kò sì gbà láti jẹ́ ọba wọn. Àwọn ènìyàn nã sì fẹ́ kí bàbá rẹ̀ ó rọ̀ ọ́, ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ kọ̀; ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máṣe rọ̀ ẹnikẹ́ni láti jẹ́ ọba wọn.

26 O sì ṣe tí wọn yàn gbogbo àwọn arákùnrin Págágì, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀.

27 O sì ṣe tí kò sí èyíkéyi nínú àwọn ọmọkùnrin Járẹ́dì, àní nínú gbogbo wọn, bíkòṣe ọ̀kan, a sì fi àmì òróró yàn Òríhà láti jẹ́ ọba lórí àwọn ènìyàn nã.

28 O sì bẹ̀rẹ̀sí jọba, àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú; wọn sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀ ènìyàn.

29 Ó sì ṣe tí Járẹ́dì kú, àti arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.

30 O sì ṣe ti Oríhà sì nrin nínú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn níwájú Olúwa, ó sì ranti àwọn ohun nla tí Olúwa ti ṣe fún bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú nípa àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wọn.