Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 10


Orí 10

Olúwa fún Nífáì ní agbára èdìdì—A fún un lágbára láti lè dè àti láti lè tú sílẹ̀ láyé àti lọ́run—Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn nã láti ronúpìwàdà tàbí kí nwọ́n ṣègbé—Ẹ̀mi gbé e láti ọ̀pọ̀ ènìyàn dé ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọ́dun 21 sí 20 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí ìyapa wà lãrín àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n pín ara nwọn síhin àti sọ́hun tí nwọ́n sì pínyà, tí nwọ́n sì fi Nífáì sílẹ̀, bí ó ṣe dúró lãrín nwọn.

2 Ó sì ṣe tí Nífáì bá tirẹ̀ lọ sí ọ̀nà ilé rẹ̀, tí ó nṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tí Olúwa ti fi hàn síi.

3 Ó sì ṣe bí ó ti nṣe àṣàrò yĩ—ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn ará Nífáì nã, àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ ti òkùnkùn nwọn, àti ìpànìyàn nwọn, àti ìkógun tí nwọn nṣe, àti onírurú àìṣedẽdé—ó sì ṣe bí ó ti nṣe àṣàrò ní ọkàn rẹ̀ báyĩ, ẹ kíyèsĩ, ohùn kan tọ̃ wá tí ó wípé:

4 Ìbùkún ni fún ọ, Nífáì, nítorí àwọn ohun nì tí ìwọ ti ṣe; nítorítí èmi ti rí bí ìwọ ti nsọ ọ̀rọ̀ mi jáde láìkãrẹ̀, èyítí mo fi fún ọ, fún àwọn ènìyàn yĩ. Ìwọ kò sì bẹ̀rù nwọn, ìwọ kò sì wá ìpamọ́ fún ẹ̀mí ti ara rẹ, ṣùgbọ́n ó lépa ìfẹ́ mi, àti láti pa òfin mi mọ́.

5 Àti nísisìyí, nítorípé ìwọ ṣe eleyĩ láìkãrẹ̀, kíyèsĩ, èmi yíò bùkún fún ọ títí láé; èmi yíò sì fún ọ ní agbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, ní ìgbàgbọ́ àti nínú iṣẹ́; bẹ̃ni àní tí ohun gbogbo yíò di ṣíṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ; nítorítí ìwọ kì yíò bẽrè èyítí ó tako ìfẹ mi.

6 Kíyèsĩ, ìwọ ni Nífáì, èmi sì ni Ọlọ́run. Kíyèsĩ, èmi sọ̃ jáde sí ọ níwájú àwọn ángẹ́lì mi, pé ìwọ yíò lágbára lórí àwọn ènìyàn yĩ, ìwọ yíò sì fi ìyàn bá ilẹ̀ nã jà, àti pẹ̀lú àrùn, àti ìparun, gẹ́gẹ́bí ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ.

7 Kíyèsĩ, mo fi agbára fún ọ, pé ohunkóhun tí ìwọ yíò fi èdìdì dì ní ayé ni a ó fi èdìdì dì ní ọ̀run; àti ohunkóhun tí ìwọ yíò tú sílẹ̀ ní ayé ni a ó tú sílẹ̀ ní ọ̀run; báyĩ ni ìwọ yíò sì ní agbára lãrín àwọn ènìyàn yĩ.

8 Àti báyĩ, bí ìwọ yíò bá wí fún tẹ́mpìlì yĩ pé kí ó ya sí méjì, yíò sì rí bẹ̃.

9 Àti bí ìwọ yíò bá wí fún òkè yĩ, Wó lulẹ̀ kí ó sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀, yíò sì rí bẹ̃.

10 Sì kíyèsĩ, bí ìwọ yíò bá wípé kí Ọlọ́run kí ó kọlũ àwọn ènìyàn yĩ, yíò sì rí bẹ̃.

11 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, mo p láṣẹ fún ọ, pé kí o lọ kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yĩ, pé báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí, ẹnití tí íṣe Olódùmarè: Afi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà a ó kọlũ nyín, àní sí ìparun.

12 Ẹ sì kíyèsĩ, ó sì ṣe nígbàtí Olúwa ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Nífáì, ó dúró kò sì lọ sínú ilé ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ó padà sí ọ́dọ̀ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí nwọ́n ti túká lórí ilẹ̀ nã, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyítí a ti sọ fún un fún nwọn, nípa ìparun nwọn bí nwọn kò bá ronúpìwàdà.

13 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, l’áìṣírò Nífáì ṣe ohun ìyanu níti sísọ fún nwọn nípa ikú onidajọ-àgbà, nwọ́n sì sé àyà nwọn le nwọn kò sì tẹ́tísí sí ọ̀rọ̀ Olúwa.

14 Nítorínã Nífáì sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún nwọn, wípé: Afi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, báyĩ ni Olúwa wí, a ó kọlũ nyín àní sí ìparun.

15 Ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ ọ̀rọ̀ nã fún nwọn tán, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n sì tún sé àyà nwọn le nwọn kò sì tẹ́tísí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọ́n nkẹ́gàn rẹ̀, nwọ́n sì nwá ọ̀nà tí nwọn ó fi múu, tí nwọn ó sì jũ sínú túbú.

16 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, nwọ́n kò sì lè múu láti jù ú sínú tũbú, nítorítí Ẹ̀mí múu lọ tí ó sì gbée kúrò lãrín nwọn.

17 Ó sì ṣe pé báyĩ ni ó nlọ nínú Ẹ̀mí, láti ọ̀pọ̀ ènìyàn dé ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí ó nsọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àní títí ó fi sọọ́ fún gbogbo nwọn, tàbí tí ó fi ránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã gbogbo.

18 Ó sì ṣe tí nwọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; asọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí wà, tóbẹ̃ tí ìpinyà fi wà lãrín nwọn tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa ara nwọn pẹ̀lú idà.

19 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlé-lãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí.