Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 16


Orí 16

Àwọn ará Nífáì tí ó gba Sámúẹ́lì gbọ́ ni Nífáì rìbọmi—Àwọn ọfà àti àwọn òkúta wẹ́wẹ́ àwọn aláìronúpìwàdà ará Nífáì kò lè pa Sámúẹ́lì—Nínú nwọn sé ọkàn nwọn le, àwọn míràn sì rí àwọn ángẹ́lì—Àwọn aláìgbàgbọ́ sọ wípé kò bá ipa ọgbọ́n mu láti gbàgbọ́ nínú Krístì àti bíbọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ní ìwọ̀n ọdún 6 sí 1 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì, ará Lámánì pọ̀, èyítí ó sọ lórí ògiri ìlú-nlá nã. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde lọ nwọ́n sì nwá Nífáì; nígbàtí nwọ́n sì ti jáde lọ tí nwọ́n sì wáa rí nwọ́n jẹ́wọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ nwọn fún un nwọn kò sì sẹ́, nwọ́n sì fẹ́ kí a rì wọn bọmi sí Olúwa.

2 Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì gbọ́ bínú síi; nwọ́n sì sọ ọ́ ní okuta lórí ògiri nã, àti pẹ̀lú púpọ̀ ta ọfà bã bí ó ti dúró lórí ògiri nã; ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, tóbẹ̃ tí òkúta nwọn kò bã bẹ̃ nã ni ọfà nwọn.

3 Nísisìyí nígbàtí nwọ́n ríi pé àwọn ohun tí nwọ́n nsọ lù ú kò bã, àwọn tí ó sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ pọ̀ síi, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì kọjá lọ bá Nífáì kí ó lè rì nwọn bọmi.

4 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Nífáì nṣe ìrìbọmi, ó sì nsọtẹ́lẹ̀, ó sì nwãsù, tí ó nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nfi àwọn àmì àti ohun ìyanu hàn, tí ó sì nṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ènìyàn nã, pé kí nwọ́n lè mọ̀ pé Krístì nã yíò dé láìpẹ́—

5 Tí ó sì nsọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá láìpẹ́, kí nwọn ó lè mọ̀ àti kí nwọn o rántí ní ìgbà tí nwọ́n bá dé pé a ti sọ nwọ́n di mímọ̀ fún nwọn ṣãjú, láti lè mú kí nwọn ó gbàgbọ́; nítorínã gbogbo àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ Sámúẹlì gbọ́ jáde lọ bã láti ṣe ìrìbọmi, nítorítí nwọ́n wá ní ironúpìwàdà àti ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

6 Ṣùgbọ́n èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn kò gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; nítorínã nígbàtí nwọ́n ríi pé àwọn òkúta nwọn àti ọfà nwọn kò lè bã nwọn kígbe pe àwọn olórí nwọn, wípé: Ẹ mú ọkùnrin yĩ, kí ẹ sì dẽ, nítorí ẹ kíyèsĩ ó ní èṣù nínú; àti nítorí agbára èṣù tí ó wà nínú rẹ̀ àwa kò lè sọ àwọn òkúta wa àti ọfà wa bà á; nítorínã ẹ mú u kí ẹ sì dè é, kí ẹ sì múu lọ.

7 Bí nwọ́n sì ti nlọ láti mú u, ẹ kíyèsĩ, ó bẹ́ sílẹ̀ láti orí ògiri nã, ó sì sálọ kúrò nínú ilẹ̀ nwọn, bẹ̃ni, àní lọ sínú ilẹ̀ tirẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù àti láti sọtẹ́lẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

8 Sì kíyèsĩ, a kò sì gburo rẹ̀ mọ́ lãrín àwọn ará Nífáì; báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn nã rí.

9 Báyĩ sì ini ọdún kẹrìndínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí.

10 Báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ parí pẹ̀lú, tí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã wà nínú ìgbéraga àti ìwà búburú nwọn, tí díẹ̀ nínú nwọn sì nrìn ní ìkíyèsára níwájú Ọlọ́run.

11 Bí àwọn nkan ti rí sì nìyí pẹ̀lú, ní ọdún kejìdínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

12 Díẹ̀ sì ni ìyípadà tí ó wà nínú ìṣe àwọn ènìyàn nã, bíkòṣepé àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé àyà nwọn le nínú àìṣedẽdé, tí nwọ́n sì túbọ̀ nṣe-èyítí ó lòdì sí òfin Ọlọ́run, ní ọdún kọkàndínlãdọ́run nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

13 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní ãdọ́run ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí a fún àwọn ènìyàn nã ní àwọn àmì nlá, àti àwọn ohun ìyanu; tí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ sì bẹ̀rẹ̀ sí di mímúṣẹ.

14 Àwọn ángẹ́lì sì farahàn sì áwọn ènìyàn, àwọn ọlọgbọ́n ènìyàn, tí nwọ́n sì mú ìròhìn ayọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ inúdídùn wa fún nwọn; báyĩ sì ni àwọn ìwé-mímọ́ bẹ̀rẹ̀sí di mímúṣẹ nínú ọdún yĩ.

15 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí sé ọkàn nwọn lè, gbogbo nwọn bíkòṣe àwọn tí ó gbàgbọ́ jùlọ nínú nwọn, àti lára àwọn ará Nífáì àti lára àwọn ará Lámánì pẹ̀lú, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbójúlé agbára ara nwọn àti ọgbọ́n ara nwọn, wípé:

16 Àwọn ohun kan ni nwọ́n rò tí ó sì ṣe dẽdé, lãrín àwọn ohun tí ó pọ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwá mọ̀ pé gbogbo àwọn iṣẹ́ nlá àti ìyanu yĩ kò lè ṣẹ, nípa èyítí nwọ́n ti sọ.

17 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe àròyé nwọn sì njiyàn lãrín ara nwọn, wípé:

18 Pé kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí ènìyàn kan bĩ Krístì kan yíò wá; bí ó bá sì rí bẹ̃, tí í sì í ṣe Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run àti ayé, bí nwọ́n ti wíi, ẽṣe ti kò ha fi ara rẹ̀ hàn sí àwa nã gẹ́gẹ́bí yíò ti fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn tí yíò wà ní Jerúsálẹ́mù?

19 Bẹ̃ni, ẽṣe tí kò hà ní fi ara rẹ̀ hàn ní ilẹ̀ yĩ gẹ́gẹ́bí yíò ti ṣe ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù?

20 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwá mọ̀ pé àṣà búburú ni èyí, èyítí àwọn bàbá nlá wa ti fi lé wa lọ́wọ́, láti mú wa gbàgbọ́ nínú àwọn ohun nlá àti ìyanu nã èyítí nbọ̀wá, tí kĩ ṣe lãrín wa, ṣùgbọ́n nínú ilẹ̀ kan tí ó wà lókẽrè, ilẹ̀ èyítí àwa kò mọ̀; nítorínã kí nwọn lé fi wá sílẹ̀ nínú àìmọ̀, nítorítí àwa kò fi ojú ríi pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe.

21 Nwọn yíò sì ṣe ohun ìyanu nlá kan tí kò lè yé wa nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti ọ̀nà ẹni búburú nnì èyítí yíò mú wa mọ́lẹ̀ láti jẹ́ ẹrú sí ọ̀rọ̀ nwọn, àti ẹ̀rù sí nwọn, nítorítí àwa gbẹ́kẹ̀lé nwọn láti kọ́ wa ní ọ̀rọ̀ nã; báyĩ ni nwọn yíò sì fi wá sí ipò àìmọ̀ bí àwa bá jọ̀wọ́ ara wa fún wọn, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

22 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó pọ̀ síi sì ní àwọn ènìyàn nã tún rò nínú ọkàn nwọn, èyítí ó jẹ́ ti aláìgbọ́n àti ásán; nwọ́n sì dãmú púpọ̀, nítorítí Sátánì sì rú nwọn sókè láti ṣe àìṣedẽdé nígbà-gbogbo; bẹ̃ni, ó nlọ kiri láti tan irọ́ àti asọ̀ kálẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, kí ó lè sé ọkàn àwọn ènìyàn nã le sí èyítí ó dára àti sí èyítí nbọ̀wá.

23 Àti l’áìṣírò àwọn àmì àti ohun ìyanu tí nwọ́n ṣe lãrín àwọn ènìyàn Olúwa, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ tí nwọ́n ṣe, Sátánì ní agbára lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã.

24 Báyĩ sì ni ãdọ́rún ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí.

25 Báyĩ sì ni ìwé Hẹ́lámánì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ rẹ̀ parí.