Orí 15
Olúwa bá àwọn ará Nífáì wí nítorítí ó ní ìfẹ́ sí nwọn—Àwọn ará Lámánì tí a yí padà wà ní ìdúróṣinṣin àti ní ìtẹramọ́ nínú ìgbàgbọ́ nwọn—Olúwa yíò ṣãnú fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ ìkẹhìn. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín pé bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà àwọn ilé nyín yíò di ahoro fún nyín.
2 Bẹ̃ni, bíkòṣepe ẹ̀yin ronúpìwàdà, àwọn obìnrin nyín yíò ní ìdí láti ṣọ̀fọ̀ ní ọjọ́ tí nwọn nfi ọmú fún ọmọ mu; nítorí ẹ̀yin yíò gbìyànjú láti sá kò sì ní sí ibi ìsádi; bẹ̃ni, ègbé sì ni fún àwọn tí ó loyun, nítorítí nwọn yíò wúwo nwọn kò sì ní lè sá; nítorínã nwọn yíò di títẹ̀mọ́lẹ̀ tí a ó sì fi nwọ́n sílẹ̀ láti ṣègbé.
3 Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ tí nwọn npè ní àwọn ènìyàn Nífáì bíkòṣepé kí nwọn ó ronúpìwàdà, nígbàtí nwọn yíò rí gbogbo àwọn àmì àti ìyanu wọ̀nyí èyítí a ó fi hàn nwọ́n; nítorí ẹ kíyèsĩ, a ti yàn nwọ́n ní ènìyàn Olúwa; bẹ̃ni, àwọn ènìyàn Nífáì ni ó ti nífẹ sí, ó sì ti bá nwọn wí; bẹ̃ni, ní ọjọ́ ìwà àìṣedẽdé nwọn ni ó bá nwọn wí nítorítí ó nífẹ sí nwọn.
4 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin arákùnrin mi, àwọn ará Lámánì ni ó kórìra nítorítí ìṣe nwọn jẹ́ èyítí ó burú títí, èyítí ó rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé inú àṣà àwọn bàbá nwọn. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìgbàlà ti wá sí órí nwọn nípasẹ̀ ìwãsù àwọn ará Nífáì; àti nítorínã ni Olúwa ṣe mú ọjọ́ nwọn gùn.
5 Èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó rí i pé èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó ní ọ̀nà tí ó dára, tí nwọ́n sì nrìn ní ọ̀nà òtítọ́ níwájú Ọlọ́run, tí nwọ́n sì gbìyànjú láti pa àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè.
6 Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, pé èyítí ó pọ̀ jù nínú nwọn ni ó nṣe èyí, tí nwọ́n sì ngbìyànjú láìkáarẹ̀ láti mú àwọn arákùnrin nwọn yókù sínú ìmọ̀ òtítọ́; nítorínã àwọn tí ó pọ̀ sì darapọ̀ mọ́ nwọn lójojúmọ́.
7 Ẹ sì kíyèsĩ, ẹ̀yin mọ̀ fúnra nyín, nítorítí ẹ̀yin ti fi ojú ríi, pé gbogbo àwọn tí a mú sínú ìmọ̀ òtítọ́ nínú nwọn, àti lati mọ̀ nípa àṣà búburú tí ó sì jẹ́ ìríra tí àwọn bàbá nwọn, tí a sì darí nwọn láti gba àwọn ìwé-mímọ́ gbọ́, bẹ̃ni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́, èyítí a kọ, èyítí ó ndarí nwọn sí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, àti sí ìrònúpìwàdà, ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà nã sì mú ìyílọ́kànpadà sínú nwọn—
8 Nítorínã, gbogbo àwọn tí ó rí bayĩ, ẹ̀yin mọ̀ fúnra nyín pé àwọn wà ní ìdúróṣinṣin àti ní ìtẹramọ́ nínú ìgbàgbọ́ nã, àti nínú ohun nã nípasẹ̀ èyítí a ti sọ nwọ́n di òmìnira.
9 Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé nwọ́n ti ri àwọn ohun ìjà ogun nwọn mọ́lẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rù láti tún gbé nwọn pé kí nwọn ó máṣe dẹ́ṣẹ̀; bẹ̃ni, ẹ̀yin ríi pé nwọ́n bẹ̀rù láti dẹ́ṣẹ̀—nítorí ẹ kíyèsĩ nwọn yíò gbà kí àwọn ọ̀tá nwọn ó tẹ̀ nwọ́n mọ́lẹ̀ kí nwọn ó sì pa nwọ́n, nwọn kò sì ni gbe idà wọn sókè sí wọn, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì.
10 Àti nísisìyí, nítorí ìdúróṣinṣin nwọn nígbàtí nwọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ohun nã tí nwọ́n gbà gbọ́, nítorípé nítorí ìdúróṣinṣin nwọn nígbàtí nwọ́n ti rí ìmọ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, Olúwa yíò bùkúnfún nwọn yíò sì mú ọjọ́ nwọn gùn, l’áìṣírò ìwà àìṣedẽdé nwọn—
11 Bẹ̃ni, bí nwọ́n tilẹ̀ jó rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ Olúwa yíò mú ọjọ́ nwọn gùn, títí àkokò nã yíò dé èyítí àwọn bàbá nlá wa ti sọ nípa rẹ àti wòlĩ Sénọ́sì, àti àwọn wòlĩ míràn tí ó pọ̀, nípa ìdápadà sí ipò àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì lẹ̃kan síi sí ìmọ̀ òtítọ́—
12 Bẹ̃ni, mo wí fún nyín, pé ní ìgbà ìkẹhìn ìlérí Olúwa yíò de ọdọ àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì; l’áìṣírò àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú tí nwọn yíò sí ní, àti l’áìṣírò a ó lé nwọn sihin-sọhun lórí ilẹ̀ ayé, tí a ó sì dọdẹ nwọn, tí a ó sì lù nwọ́n àti fọ́n nwọn kãkiri, tí nwọn kò sì ní ní ibi ìsádi, Olúwa yíò ṣãnú fún nwọn.
13 Èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ nã, pé a ó tún mú nwọn padà sínú ìmọ̀ òtítọ́, èyítí í ṣe ìmọ̀ nípa Olùràpadà nwọn, àti Olùṣọ́-àgùtàn òtítọ́ nwọn tí ó tóbi, tí a ó sì kà nwọ́n mọ́ àwọn àgùtàn rẹ̀.
14 Nítorínã mo wí fún nyín, yíò sàn fún nwọn ju ẹ̀yin lọ bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà.
15 Nítorí ẹ kíyèsĩ, bí ó bá ṣe wípé a ti fi iṣẹ́ ìyanu nã hàn nwọ́n èyítí a ti fi hàn nyín, bẹ̃ni, han àwọn nã tí nwọ́n ti rẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nítorí àwọn àṣà àwọn bàbá nwọn, ẹ̀yin ríi fúnra nyín pé nwọn kò ní rẹ́hìn mọ́ nínú ìgbàgbọ́.
16 Nítorínã, ni Olúwa wí: Èmi kì yíò pa nwọ́n run pátápátá ṣùgbọ́n èmi yíò mú kí nwọn ó tún padà sí ọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí ó bá yẹ, ni Olúwa wí.
17 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ni Olúwa wí, nípa àwọn ará Nífáì: Bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, kí nwọ́n sì ṣe ìfẹ́ mi, èmi yíò pa nwọ́n run pátápátá, ni Olúwa wí, nítorí àìgbàgbọ́ nwọn l’áìṣírò àwọn iṣẹ́ nlá tí mo ti ṣe lãrín nwọn; bí Olúwa sì ti wà lãyè ni àwọn ohun wọ̀nyí yíò rí, ni Olúwa wí.