Orí 11
Nífáì rọ Olúwa kí ó fi ìyàn rọ́pò ogun jíjà lãrín nwọn—Ọ̀pọ̀ ènìyàn parun—Wọ́n ronúpìwàdà, Nífáì sì bẹ Olúwa láìsinmi fún òjò—Nífáì àti Léhì gba ìfihàn púpọ̀—Àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ilẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 20 sí 16 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kejìlélãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ tí àwọn asọ̀ nã pọ̀ síi, tóbẹ̃ tí ogun wà jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì.
2 Àwọn ọlọ́ṣà ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ sì ni ó nṣe iṣẹ́ ìparun àti ìwà búburú yĩ. Ogun yĩ sì wà ní gbogbo ọdún nã; àti nínú ọdún kẹtàlélãdọ́rin ni ó wà pẹ̀lú.
3 Ó sì ṣe nínú ọdún yĩ tí Nífáì kígbe pe Ọlọ́run wípé:
4 A! Olúwa, máṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn yĩ ó parun nípasẹ̀ idà ṣùgbọ́n A! Olúwa, dípò èyí jẹ́ kí ìyàn kí ó wà lórí ilẹ̀ nã, láti ta nwọ́n jí sí ìrántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, bóyá nwọn yíò ronúpìwàdà kí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀dọ̀ rẹ.
5 Ó sì rí bẹ̃, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Nífáì. Ìyàn nlá sì wà lórí ilẹ̀ nã, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì. Àti báyĩ nínú ọdún kẹrìnlélãdọ́rin ìyàn nã tẹ̀síwájú, iṣẹ́ ìparun sì dópin ṣùgbọ́n ó pọ̀ nípasẹ̀ ìyàn.
6 Iṣẹ́ ìparun yĩ sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú nínú ọdún karundinlọgọrin. Nítorítí a kọlũ ilẹ̀ tí ó sì gbẹ, tí kò sì mú irúgbìn jáde ní àkokò irúgbìn gbogbo ilẹ̀ ni a sì kọlù, àní lãrín àwọn ará Lámánì àti lãrín àwọn ará Nífáì, tí a sì kọlù nwọ́n tí nwọ́n sì parun ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ní àwọn apá ilẹ̀ nã níbití àwọn ènìyàn nã ti ṣe búburú jùlọ.
7 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã ríi pé ìyàn fẹ́rẹ̀ pa nwọ́n run, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì.
8 Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn adájọ́-àgbà nwọn àti àwọn olórí nwọn, pé wọn yíò wí fún Nífáì pe: Kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé ẹni Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe, nítorínã ké pe Olúwa Ọlọ́run wa kí ó mú ìyàn yĩ kúrò lọ́dọ̀ wa kí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ ti sọ nípa ìparun wa má bã di mímú ṣẹ.
9 Ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã sì wí fún Nífáì ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí nwọ́n fẹ́. Ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ríi pé àwọn ènìyàn nã ti ronúpìwàdà tí nwọ́n sì rẹ̀ ara nwọn sílẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó tún kígbe pe Olúwa, wípé:
10 A! Olúwa, kíyèsĩ àwọn ènìyàn yìi ti ronúpìwàdà; nwọ́n sì ti mú àwọn ẹgbẹ́ Gádíátónì kúrò lãrín nwọn tóbẹ̃ tí nwọn kò sí mọ́, nwọ́n sì ti ri àwọn ìlànà iṣẹ́ òkùnkùn nwọn bọlẹ̀.
11 Nísisìyí, A! Olúwa, nítorí ìwà ìtẹríba nwọn yĩ kí ìwọ kí ó mú ìbínú rẹ̀ kúrò, kí o sì ni ìtùnù nínú ìparun àwọn ènìyàn búburú nnì tí ìwọ ti parun.
12 A! Olúwa, kí ìwọ kí ó mú ìbínú rẹ kúrò, bẹ̃ni, gbígbóná ìbínú rẹ̀, kí ó sì mú kí ìyàn yĩ ó dáwọ́dúró lórí ilẹ̀ yĩ.
13 A! Olúwa, kí ìwọ ó fetísílẹ̀ sí mi, kí o sì mú kí ó rí bẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi, kí o sì mú kí òjò kí ó rọ̀ sí órí ilẹ̀ ayé kí ó lè mú èso jáde, àti àwọn irúwó rẹ̀ ní àkokò irúwó.
14 A! Olúwa, ìwọ fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi nígbàtí mo wípé, Jẹ́ kí ìyàn kí ó wa, kí ìparun nípasẹ̀ idà ó dáwọ́dúró; èmi sì mọ̀ wípé ìwọ yíò ṣẽ àní ní ìgbà yĩ, fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, nítorítí ìwọ wípé: Bí àwọn ènìyàn yĩ bá ronúpìwàdà èmi yio dá nwọn sí.
15 Bẹ̃ni, A! Olúwa, ìwọ sì ríi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà, nítorí ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn àti ìparun tí ó ti bá nwọn.
16 Àti nísisìyí, A! Olúwa ìwọ kì yíò ha mú ìbínú rẹ kúrò, kí o sì tún dán nwọn wò bóyá nwọn yíò sìn ọ́ bí? Bí ó bá sì rí bẹ̃, A! Olúwa, ìwọ lè bùkún nwọn gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ ti sọ.
17 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gọ́rin Olúwa sì mú ìbínú rẹ kúrò lórí àwọn ènìyàn nã, tí ó sì mú kí òjò ó rọ̀ sí órí ilẹ̀, tóbẹ̃ tí ó mú èso rẹ̀ jáde ní àkokò rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó mú irúwó rẹ̀ jáde ní àkókò irúwó rẹ̀.
18 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã yọ̀ nwọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run, gbogbo orí ilẹ̀ nã sì kún fún ayọ̀; nwọn kò sì lépa lati pa Nífáì mọ́, ṣùgbọ́n nwọ́n kã kún wòlĩ nlá, àti ẹni Ọlọ́run, tí ó ní agbára nlá àti àṣẹ tí Ọlọ́run fi fún un.
19 Ẹ sì kíyèsĩ, Léhì arákùnrin rẹ̀ kò gbẹ́hìn rárá níti ohun tíi ṣe ti òdodo.
20 Báyĩ ni ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí tún àwọn ibi ahoro nwọn kọ́, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi tí nwọn sì ntànkálẹ̀, àní títí nwọn fi borí gbogbo ilẹ̀ nã, ní apã ríwá, áti ní apá gũsù, láti òkun apá ìwọ̀-oòrùn títí dé òkun apá ìlà-oòrùn.
21 Ó sì ṣe tí ọdún kẹrìndínlọ́gọ́rin parí ní àlãfíà. Ọdún kẹtàdínlọ́gọ́rin sì bẹ̀rẹ̀ ní àlãfíà; ìjọ nã sì tànkálẹ̀ jákè-jádò orí ilẹ̀ nã gbogbo; èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã, nínú àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, ni ó sì wà nínú ìjọ nã; nwọ́n sì ní àlãfíà èyítí ó pọ̀ púpọ̀ ní ilẹ̀ nã; báyĩ sì ni ọdún kẹtàdínlọ́gọ́rin parí.
22 Àti pẹ̀lú nwọn ni àlãfíà nínú ọdún kejìdínlọ́gọ́rin, àfi fún asọ̀ díẹ̀díẹ̀ tí ó wà nípa àwọn ẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èyítí àwọn wòlĩ ti fi lélẹ̀.
23 Àti nínú ọdún kọkàndínlọ́gọ́rin ni asọ̀ púpọ̀ bẹ̀rẹ̀sí wà. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì, àti púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn tí ó mọ̀ nípa àwọn ẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nwọn, nítorípé nwọ́n ngba ìfihàn púpọ̀púpọ̀ lójojúmọ́, nítorínã nwọ́n sì nwãsù sí àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi òpin sí àwọn asọ̀ nwọn nínú ọdún kannã.
24 Ó sì ṣe nínú ọgọ́rin ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, àwọn olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì kan, tí nwọ́n ti lọ bá àwọn ará Lámánì ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, tí nwọ́n sì ti fún ara nwọn ní orúkọ àwọn ará Lámánì, àti pẹ̀lú àwọn kan tí irú ọmọ àwọn ará Lámánì nítorípé nwọ́n ru nwọn sókè ní ìbínú, àtí pé àwọn olùyapa-kúrò nnì ru nwọn sókè ní ìbínú, nítorínã nwọ́n bẹ̀rẹ̀ ogun jíjà pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn.
25 Nwọ́n sì nṣe ìpànìyàn àti ìkógun; nwọ́n ó sì sá padà sínú àwọn òkè gíga, àti sínú aginjù àti àwọn ibi kọ́lọ́fín, nwọn ó sì fi ara pamọ́ tí nwọn kò sì lè rí nwọn, nwọ́n sì nfikún ara nwọn lójojúmọ́, ní ìwọ̀n ìgbàtí àwọn olùyapa-kúrò wà tí nwọn ntọ̀ nwọ́n lọ.
26 Àti báyĩ láìpẹ́, bẹ̃ni, àní lãrín ìwọ̀n ọdún díẹ̀, nwọ́n di ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà tí ó tóbi púpọ̀; nwọ́n sì ṣe àwárí gbogbo àwọn ìmọ̀ òkùnkùn Gádíátónì; báyĩ ni nwọ́n sì di ọlọ́ṣà Gádíátónì.
27 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn ọlọ́ṣà yĩ ṣe ohun ibi púpọ̀, bẹ̃ni, àní ìparun púpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, àti lãrín àwọn ènìyàn ará Lámánì pẹ̀lú.
28 Ó sì ṣe tí ó di ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe láti fi òpin sí iṣẹ́ ìparun yìi; nítorínã nwọ́n rán ẹgbẹ́ ọmọ ogun alágbára ọkùnrin sí ínú aginjù àti sí ínú àwọn òkè gíga nã láti wá àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà nã rí, àti láti pa nwọ́n run.
29 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe nínú ọdún kannã nwọ́n lé nwọn padà àní sínú ilẹ̀ nwọn. Báyĩ sì ni ọgọ́rin ọdún parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.
30 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkànlélọ́gọ́rin nwọ́n sì tún kọjá lọ láti kọlu àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ, nwọ́n sì pa púpọ̀; àwọn nã sì fi ara bá àdánú tí ó pọ̀.
31 Ó sì tún di dandan fún nwọn láti padà kúrò nínú aginjù nã àti kúrò nínú àwọn òkè gíga nã lọ sínú ilẹ̀ nwọn, nítorí púpọ̀ tí àwọn ọlọ́ṣà nã pọ̀ tí nwọ́n ti gba inú gbogbo àwọn òkè gíga àti aginjù nã tán.
32 Ó sì ṣe tí ọdún yĩ parí báyĩ. Àwọn ọlọ́ṣà nã sì npọ̀ síi nwọ́n sì ntẹ̀síwájú nínú agbára, tóbẹ̃ tí nwọn kò ka gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sí, àti ti àwọn ará Lámánì pẹ̀lú; nwọ́n sì mú kí ẹ̀rù nlá ó bá àwọn ènìyàn nã lórí gbogbo ilẹ̀ nã.
33 Bẹ̃ni, nítorítí nwọ́n bẹ àwọn ibi púpọ̀ wò lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì ṣe ìparun nlá níbẹ̀; bẹ̃ni, nwọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì mú àwọn yókù lọ ní ìgbẹ̀kùn sínú aginjù, bẹ̃ni, àti pãpã àwọn obìnrin nwọn àti àwọn ọmọ nwọn.
34 Nísisìyí ohun búburú nlá yĩ, èyítí ó dé bá àwọn ènìyàn nã nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn, sì tún ta nwọ́n jí sí ìrántí Olúwa Ọlọ́run nwọn.
35 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ parí.
36 Àti nínú ọdún kejìlélọ́gọ́rin nwọ́n tún bẹ̀rẹ̀sí gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn. Àti nínú ọdún kẹtàlélọ́gọ́rin nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí tẹ̀síwájú nínú àìṣedẽdé. Àti nínú ọdún kẹrìnlélọ́gọ́rin nwọ́n kò tún ọ̀nà nwọn ṣe.
37 Ó sì ṣe nínú ọdún karundinlãdọrun nwọ́n sí nní agbára síi nínú ìwà ìgbéraga, àti nínú ìwà búburú nwọn; báyĩ nwọ́n sì nmúrasílẹ̀ fún ìparun.
38 Báyĩ sì ni ọdún karundinlãdọrun parí.