Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 4


Orí 4

Àwọn tí ó ti yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì láti mú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà—Ìṣubú bá àwọn ará Nífáì nítorí ìwà búburú nwọn—Ìjọ nã sì nrẹ̀hìn, àwọn ènìyàn nã sì di aláìlágbára gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 38 sí 30 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìnlélãdọ́ta tí ìyapa púpọ̀ wà nínú ìjọ nã, asọ̀ sì wà lãrín àwọn ènìyàn nã pẹ̀lú, tóbẹ̃ tí ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ fi wà.

2 A sì pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn nã a sì lé nwọn jáde kuro lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì tọ ọba àwọn ará Lámánì lọ.

3 Ó sì ṣe tí nwọ́n sì gbìyànjú láti ru àwọn ará Lámánì sókè láti kọlũ àwọn ará Nífáì nínú ogun; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì bẹ̀rù gidigidi, tóbẹ̃ tí nwọn kò fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn olùyapa nã.

4 Ṣubọ́n ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn olùyapa tí ó kúrò lára àwọn ará Nífáì lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì ní àṣeyọrí pẹ̀lú àwọn míràn nì láti ru nwọn sókè ní ìbínú sí àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì fi gbogbo ọdún nã ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun.

5 Àti ní ọdún kẹtàdínlọ́gọ́ta nwọn sì sọ̀kalẹ̀ wá láti bá àwọn ará Nífáì jagun, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ṣí ípa ènìyàn; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé ní ọdún kejìdínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ nwọ́n ní àṣeyọrí láti mú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; bẹ̃ni, àti ilẹ̀ gbogbo, àní títí dé ilẹ̀ èyítí ó wà nítòsí ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀.

6 Nwọ́n sì lé àwọn ará Nífáì àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Móróníhà àní sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀;

7 Níbẹ̀ ni nwọ́n sì dãbò bò ará nwọn lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, láti apá òkun ti apá ìwọ oòrùn, àní títí dé ti apá ìlà-oòrùn; èyítí í ṣe ìrìnàjò ọjọ́ kan fún ará Nífáì láti rìn, ní ãlà tí nwọ́n ti mọdisí tí nwọ́n sì ti fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sí láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn tí ó wà ní apá àríwá.

8 Báyĩ sì ni àwọn olùyapa-kúrò lára àwọn ará Nífáì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, gba gbogbo ohun ìní àwọn ará Nífáì tí ó wà nínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù. Gbogbo èyíi ni nwọ́n sì ṣe nínú ọdún kejìdínlọ́gọ́ta àti ọdún kọkàndínlọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

9 Ó sì ṣe nínú ọgọ́ta ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí Móróníhà sì ní àṣeyọrí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, nwọ́n gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá padà èyítí ó ti bọ́ sí ọwọ́ àwọn ará Lámánì tẹ́lẹ̀.

10 Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ tí nwọ́n ní àṣeyọrí láti gbà àní ìdajì ìní nwọn padà.

11 Nísisìyí àdánù nlá àwọn ará Nífáì yĩ, àti ìpànìyàn nlá èyítí ó wà lãrín nwọn, kì bá ti rí bẹ̃ bí kò bá ṣe nítorí ìwà búburú àti ìwà ẹ̀gbin èyítí ó wà lãrín nwọn; bẹ̃ni, ó sì wà lãrín àwọn tí ó njẹ́wọ́ pé àwọn wà nínú ìjọ Ọlọ́run.

12 Àti pé nítorípé nwọ́n ní ìgbéraga nínú ọkàn nwọn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn, bẹ̃ni, nítorí ìfìyàjẹ àwọn tálákà, tí nwọ́n sì háwọ́ oúnjẹ mọ́ ẹnití ebi npa, tí nwọ́n sì háwọ́ aṣọ mọ́ ẹnití ó wà ní ìhòhò, tí nwọ́n sì gbá àwọn arákùnrin nwọn tí í ṣe onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, tí nwọ́n sì fi àwọn ohun mímọ́ ṣe ẹlẹ́yà, tí nwọ́n sì sẹ́ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn, tí nwọ́n sì npaniyan, tí nwọ́n sì nṣe ìkógun, irọ́ pípa, olè jíjà, tí nwọ́n sì nṣe àgbèrè, tí nwọ́n sì nru sókè nínú asọ̀ nlá, tí nwọ́n sì nsá jáde bọ́ sínú ilẹ̀ Nífáì, lãrín àwọn ará Lámánì—

13 Àti nítorí ìwà búburú nwọn nlá yĩ, àti lílérí nínú agbára nwọn, a sì fi nwọ́n sílẹ̀ nínú agbára nwọn; nítorínã ni nwọn kò ṣe ní ìlọsíwájú, ṣùgbọ́n tí a nfìyàjẹ nwọn, tí a sì lù nwọ́n, tí àwọn ará Lámánì sì lé nwọn, títí nwọ́n fi pàdánù púpọ̀ nínú gbogbo ilẹ̀ nwọn.

14 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Móróníhà wãsù nípa ohun púpọ̀ fún àwọn ènìyàn nã nítorí àìṣedẽdé nwọn, àti Nífáì àti Léhì pẹ̀lú, tí nwọn í ṣe ọmọ Hẹ́lámánì, sì wãsù ohun púpọ̀ sí àwọn ènìyàn nã, bẹ̃ni nwọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nípa ohun púpọ̀ sí nwọn nípa àìṣedẽdé nwọn, àti ohun tí yíò dé bá nwọn bí nwọn kò bá ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

15 Ó sì ṣe tí nwọ́n sì ronúpìwàdà, níwọ̀n ìgbàtí nwọ́n ronúpìwàdà nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú.

16 Nigbàtí Móróníhà ríi pé nwọ́n ronúpìwàdà ó sì nṣíwájú nwọn ní lílọ láti ibì kan dé èkejì, àti láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àní títí nwọ́n fi gba ìdajì ohun ìní nwọn padà àti ìdajì àwọn ilẹ̀ nwọn gbogbo.

17 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gọ́ta parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

18 Ó sì ṣe ní ọdún kejìlélọ́gọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí Móróníhà kò lè gba ohun ìní àwọn ará Lámánì mọ́.

19 Nítorínã nwọ́n pa èrò nwọn láti gba àwọn ilẹ̀ wọn tí ó kù tì, nítorípé àwọn ará Lámánì pọ̀ tóbẹ̃ tí ó fi ṣòro fún àwọn ará Nífáì láti ni agbara síi lórí nwọn; nítorínã ni Móróníhà ṣe lo gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti dãbò bò àwọn ibi tí ó ti gbà.

20 Ó sì ṣe, nítorí bí àwọn ará Lámánì ti pọ̀ tó, àwọn ará Nífáì wà ní ìbẹ̀rù nlá, kí nwọn ó má bã borí nwọn, ki nwọn si tẹ̀ nwọ́n mọ́lẹ̀, kí nwọn ó pa nwọ́n, kí nwọn ó sì pa nwọ́n run.

21 Bẹ̃ni, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Álmà, àti àwọn ọ̀rọ̀ Mósíàh; nwọ́n sì ríi pé àwọn ti jẹ́ ọlọ́runlíle ènìyàn, àti tí nwọn kò sì ka òfin Ọlọ́run sí;

22 Àti pé nwọ́n ti yí òfin Mòsíà padà nwọn sì ti tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ nwọn, tàbí èyítí Olúwa ti paláṣẹ kí ó fún àwọn ènìyàn nã; nwọ́n sì ríi pé àwọn òfin nwọ́n ti díbàjẹ́, nwọ́n sì ti di ènìyàn búburú, tóbẹ̃ tí nwọn nṣe búburú àní gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì.

23 Àti nítorí àìṣedẽdé nwọn ìjọ nã ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ̀hìn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti nínú ẹ̀mí ìfihàn; ìdájọ́ Ọlọ́run sì súnmọ́ itòsí fún nwọn.

24 Nwọ́n sì ríi pé nwọn kò lágbára mọ́, bí àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, àti pé Ẹ̀mí Olúwa kò sì dãbò bò nwọ́n mọ́; bẹ̃ni, ó ti kúrò lọ́dọ̀ nwọn nítorí pé Ẹ̀mí Olúwa kò lè gbé nínú àwọn tẹ́mpìlì àìmọ́—

25 Nítorínã ni Olúwa ṣe dáwọ́dúró láti má pa nwọ́n mọ́ nípa ìyanu agbára rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, nítorípé nwọ́n ti ṣubú sínú ipò àìgbàgbọ́ àti ìwà tí ó burú jùlọ; nwọ́n sì ríi pé àwọn ará Lámánì pọ̀ jù nwọ́n lọ lọ́pọ̀lọpọ̀, àti pé àfi bí nwọn ó bá dìrọ́ mọ́ Olúwa Ọlọ́run nwọn, nwọn yíò ṣègbé ní dandan.

26 Nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ríi pé agbára àwọn ará Lámánì pọ̀ tó agbára tiwọn, àní ni ẹnikan sí ẹnikan. Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe bọ́ sí ipò ìwà ìrékọjá nlá yĩ; bẹ̃ni, báyĩ ni nwọ́n ṣe di aláìlágbára, nítorí ìwà ìrékọjá nwọn, lãrín ìwọ̀n ọdún tí kò pọ̀.