Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 7


Ìsọtẹ́lẹ̀ Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì—Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn ará Nífáì pé òun yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú rẹ̀, sí ìparun nwọn pátápátá àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú nwọn. Ọlọ́run fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ènìyàn Nífáì jà; nwọ́n ronúpìwàdà nwọn sì yípadà sọ́dọ̀ rẹ̀. Sámúẹ́lì, tí í ṣe ará Lámánì, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ará Nífáì.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 7 titi ó fi dé 16 ní àkópọ̀.

Orí 7

Nwọn kọ Nífáì ní apá àríwá ó sì padà sí Sarahẹ́múlà—Ó gbàdúrà lórí ilé ìṣọ́ tí ó wà nínú ọgbà rẹ̀ ó sì ké pe àwọn ènìyàn nã pé kí nwọn ó ronúpìwàdà àbí kí nwọ́n ó parun. Ní ìwọ̀n ọdún 23–21 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlãdọ́rin nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn ará Nífáì, tí Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

2 Nítorítí ó ti jáde lọ sí ãrin àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá, ó sì wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nwọn, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun púpọ̀ fún nwọn;

3 Nwọ́n sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, tóbẹ̃ tí kò lè dúró lãrín nwọn, ṣùgbọ́n ó tún padà sí ilẹ̀ ibití a ti bĩ.

4 Nígbàtí ó sì rí àwọn ènìyàn nã nínú ipò tí ó burú jùlọ yĩ, àti tí àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì sì wà lórí ìtẹ́-ìdájọ́—tí nwọn sì ti fi ipá gba agbára àti àṣẹ lórí ilẹ̀ nã; tí nwọ́n sì pa òfin Ọlọ́run tì, tí nwọn kò sì ṣe èyítí ó tọ́ rárá níwájú rẹ̀; tí nwọn kò sì hùwà àìṣègbè kankan sí àwọn ọmọ ènìyàn;

5 Tí nwọ́n sì ndá àwọn olódodo lẹ́bi nítorí ìwà òdodo nwọn; tí nwọn jẹ́ kí àwọn tí ó ṣẹ̀ àti àwọn oníwà búburú lọ láìjìyà nítorí owó tí nwọ́n ní; ju gbogbo rẹ̀ lọ tí nwọ́n sì fi nwọ́n sí ipò láti ṣe àkóso ìjọba, láti darí àti láti ṣe èyítí ó wù nwọ́n, kí nwọn ó lè rí èrè àti ògo ayé, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí nwọ́n lè máa hùwà àgbèrè ní ìrọ̀rùn, kí nwọn ó sì jalè, àti kí nwọn ó pànìyàn, àti kí nwọn ó ṣe ìfẹ́ inú nwọn gbogbo—

6 Nísisìyí ìwà búburú nlá yĩ ti dé bá àwọn ará Nífáì, lãrín ìwọ̀n ọdún kúkúrú; nígbàtí Nífáì sì ríi, ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ nínú àyà rẹ̀; ó sì kígbe nínú ìrora ọkàn rẹ̀ wípé:

7 Èmi ìbá ti gbé ìgbé ayé mi nígbàtí bàbá mi Nífáì kọ́kọ́ jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí èmi ìbá ti yọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilẹ̀ ìlérí nã; nígbànã tí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù ènìyàn, tí nwọ́n wà ní ìdúróṣinṣin ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́, tí nwọ́n sì lọ́ra láti gbà kí a mú nwọn ṣe àìṣedẽdé; nwọ́n sì yára láti tẹtisi ọrọ Olúwa—

8 Bẹ̃ni, bí ọjọ́ ayé mi bá lè wà ní ìgbà nnì, ìgbà nã ni ẹ̀mí mi yíò láyọ̀ nínú ìwà òdodo àwọn arákùnrin mi.

9 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìpín mi ni ó jẹ́ láti gbé ayé mi ní àkokò yĩ, àti pé ẹ̀mí mi yíò kún fún ìbànújẹ́ nítorí ìwà búburú yĩ tí àwọn arákùnrin mi nhù.

10 Ẹ sì kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí í ṣe lórí ilé ìṣọ́ kan, èyítí ó wà nínú ọgbà Nífáì, tí ó wà lẹba ọ̀nà gbõrò tí ó lọ sí ọjà nla, tí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; nítorínã, Nífáì wólẹ̀ nínú ilé ìṣọ́ nã tí ó wà nínú ọgbà rẹ̀, ilè ìṣọ́ nã sì wà lẹba ẹnu ọ̀nà, tí ọ̀nà gbõrò nã sì gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

11 Ó sì ṣe tí àwọn ọkùnrin kan tí nkọjá lọ rí Nífáì bí ó ti ntú ọkàn rẹ jáde sí Ọlọ́run lórí ilé ìṣọ́ nã; nwọ́n sì sáré lọ láti lọ sọ fún àwọn ènìyàn nã nípa ohun tí nwọ́n ti rí, àwọn ènìyàn nã sì péjọ ní ọ̀gọ̃rọ̀ láti lè mọ́ ohun tí ó fa irú ìkẹdùn tí ó tó èyí fún ìwà búburú àwọn ènìyàn.

12 Àti nísisìyí, nígbàtí Nífáì dìde ó rí àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn tí nwọ́n ti péjọ.

13 Ó sì ṣe tí ó la ẹnu rẹ̀ tí ó sì wí fún nwọn pe: Ẹ kíyèsĩ, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi péjọ? Kí èmi o ha lè sọ nípa àìṣedẽdé nyín fún nyín bí?

14 Bẹ̃ni, nítorítí èmi gun orí ilé-ìṣọ́ mi lọ láti lè gbàdúrà tọkàn-tọkàn sí Ọlọ́run mi, nitorí ọkàn mi tí ó bàjẹ́ gidigidi, ti o si jẹ wipe nitori àìṣedẽdé yin!

15 Àti nítorí ìkẹdùn àti ohùn-réré-ẹkún mi ẹ̀yin péjọ, ẹnu sì yà nyín; bẹ̃ni, ẹ̀yin ní ìdí tí ó pọ̀ láti yanu; bẹ̃ni, ẹnu níláti yà nyín nítorípé ẹ̀yin ti jọwọ́ ara nyín sílẹ̀ tí èṣù sì ti lágbára tí ó tóbi lórí ọkàn nyín.

16 Bẹ̃ni, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti fi ara nyín sílẹ̀ fún ẹ̀tàn ẹnití nwá ọ̀nà ìpàdánù ẹ̀mí nyín sínú ìrora ayérayé àti ìbànújẹ́ aláìlópin?

17 A! ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà! Ẹ̀yin ó ha ṣe ku? Ẹ yípadà, ẹ yípadà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nyín. Kíni ìdí rẹ̀ tí ó fi kọ̀ nyín sílẹ̀?

18 Èyí rí bẹ̃ nítorípé ẹ̀yin sé ọkàn nyín le; bẹ̃ni ẹ̀yin sì kọ̀ láti fi eti si ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere nnì; bẹ̃ni, ẹ̀yin ruú sókè lati ìbínú sí nyín.

19 Ẹ sì kíyèsĩ, kàkà kí ó kó nyín jọ, àfi bí ẹ̀yin yíò bá ronúpìwàdà, ẹ kíyèsĩ, yíò fọ́n nyín ká tí ẹ̀yin yíò sì di oúnjẹ fún ajá àti àwọn ẹranko ti o npẹran jẹ.

20 A! báwo ni ẹ̀yin ha ṣe gbàgbé Ọlọ́run nyín ní ọjọ́ nã tí ó ti gbà nyín?

21 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, láti rí èrè gbà ni, láti gba ìyìn láti ọwọ́ ọmọ ènìyàn, bẹ̃ni, àti kí ẹ̀yin lè rí wúrà àti fàdákà gbà. Ẹ̀yin sì ti kó ọkàn nyín lé àwọn ọrọ̀ àti ohun asán ayé yĩ, nítorí èyítí ẹ̀yin nṣe ìpànìyàn, àti ìkógun, àti olè jíjà, tí ẹ sì njẹ́rĩ èké sí aládũgbò nyín, tí ẹ sì nṣe onírurú àìṣedẽdé.

22 Àti nítorí ìdí èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe ṣègbé àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà. Nítorítí bí ẹ̀yin kò bá ní ronúpìwàdà, ẹ kíyèsĩ, ìlú-nlá yĩ, àti gbogbo àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní àyíká, tí ó wà nínú ilẹ̀ ìní wa, ni nwọn yíò gbà, tí ẹ̀yin kò sì ní ní àyè nínú nwọn; nítorítí ẹ kíyèsĩ, Olúwa kò ní fún nyín lágbára, gẹ́gẹ́bí òun ti ṣe títí dé àkokò yĩ, láti lè dojúkọ àwọn ọ̀tá nyín.

23 Nítorí ẹ kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wi: Èmi kò ní fifún ènìyàn búburú nínú agbára mi, fún ọ̀kan ju òmíràn lọ, àfi fún àwọn tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì tẹ́tísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi. Nítorínã nísisìyí, èmi rọ̀ nyín láti kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé yíò sàn fún àwọn ará Lámánì jù nyín lọ àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà.

24 Nítorí ẹ kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ olódodo jù nyín lọ, nítorítí nwọ́n kò ṣẹ̀ sí ìmọ̀ nlá nì èyítí ẹ̀yin ti rí gbà; nítorínã ni Ọlọ́run yíò fi ṣãnú fún nwọn; bẹ̃ni, yíò mú kí ọjọ́ nwọn gùn yíò sì mú kí iní-ọmọ nwọn ó pọ̀ síi, àní nígbàtí a ó pa nyín run pátápátá àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà.

25 Bẹ̃ni, ègbé ni fún nyín nítorí ìwà ìríra nnì èyítí ó ti wọ ãrín nyín; tí ẹ̀yin sì ti fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú rẹ, bẹ̃ni nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn nnì èyítí Gádíátónì dá sílẹ̀!

26 Bẹ̃ni, ègbé yio wa si ori yin nítorí ìwà ìgbéraga nnì èyítí ẹ̀yin ti gba lãyè láti wọnú ọkàn nyin, èyítí ó ti ru nyín sókè kọjá èyítí ó dára nítorí ọrọ̀ nyín tí ó pọ̀ púpọ̀ jùlọ!

27 Bẹ̃ni, ègbé ni fún nyín nítorí ìwà búburú àti ìwà ìríra nyín!

28 Àti wípé àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà ẹ̀yin yíò parun; bẹ̃ni, nwọn yíò gba ilẹ̀ nyín pãpã lọ́wọ́ nyín, nwọn yíò sì pa nyín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

29 Ẹ kíyèsĩ nísisìyí, èmi kò sọ àwọn ohun yĩ nípa ìmọ̀ ara mi, nítorípé kĩ ṣe tìkarami ni èmi ṣe mọ́ àwọn ohun yĩ; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, mo mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí í ṣe nítorípé Olúwa Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di mímọ̀ fún mi, nítorínã ni èmi ṣe jẹ́rĩ pé nwọn yíò rí bẹ̃.