Àwọn Àkòrí Ìgbàgbọ́ Náà
ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn
Orí 1
1 Àwa gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
2 Àwa gbàgbọ́ pé ènìyàn yíò jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn, kìí ṣe fún ìrékọjá ti Ádámù.
3 Àwa gbàgbọ́ pé nípa Ètùtù ti Krístì, gbogbo aráyé lè di gbígbàlà, nípa ìgbọ́ràn sí àwọn òfin àti àwọn ìlànà Ìhìnrere.
4 Àwa gbàgbọ́ pé àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ àti àwọn ìlànà Ìhìnrere ni: èkínní, Ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì; èkèjì, Ìrònúpìwàdà; ẹ̀kẹta, Ìrìbọmi nípa rírìbọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀kẹrin, Gbígbé ọwọ́ léni ní orí fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.
5 Àwa gbàgbọ́ pé ènìyàn gbọ́dọ̀ gba ìpè ti Ọlọ́run, nípa ìsọtẹ́lẹ̀, àti nípa ìgbọ́wọ́léni nípasẹ̀ àwọn ẹnití ó wà ní ipò àṣẹ, láti wàásù Ìhìnrere àti láti ṣiṣẹ́ àmójútó nínú àwọn ìlànà rẹ̀.
6 Àwa gbàgbọ́ nínú ìkójọ kannáà tí ó wà nínú Ìjọ Àkọ́kọ́, ní dídárúkọ, àwọn àpóstélì, àwọn wòlíì, àwọn olùṣọ́ àgùtàn, àwọn olùkọ́, àwọn ajíhìnrere, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
7 Àwa gbàgbọ́ nínú ẹ̀bùn ti àwọn èdè, ti ìsọtẹ́lẹ̀, ti ìfihàn, ti ìran, ti ìmúláradá, ti ìtúmọ̀ èdè, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
8 Àwa gbàgbọ́ pé Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níwọ̀n bí ó bá jẹ́ títúmọ̀ ní pípé; àwá gbàgbọ́ bákannáà pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
9 Àwa gba gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti fi hàn gbọ́, gbogbo ohun tí Òun nfi hàn nísisìyí, àwà sì gbàgbọ́ pé síbẹ̀ Òun yíò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun nlá àti pàtàkì hàn nípa Ìjọba Ọlọ́run.
10 Àwa gbàgbọ́ nínú ìkójọpọ̀ tòótọ́ ti Ìsráẹ́lì àti nínú ìmúpadàbọ̀ sípò ti àwọn Ẹ̀yà Mẹ́wã; pé Síónì (Jérúsálẹ́mù Titun) yíò jẹ́ kíkọ́ sí orí ìpín ilẹ̀ ayé ti Amẹ́ríkà; pé Krístì yíò jọba fúnrarẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé; àti, pé ilẹ̀ ayé ni a ó sọ di ọ̀tun tí yíò sì gba ògo párádíse rẹ̀.
11 Àwa ní ẹ̀tọ́ ànfàní ti sísìn Ọlọ́run Alágbara Jùlọ ní ìbámu sí ìdarí ẹ̀rí ọkàn tiwa, a sì gba gbogbo ènìyàn ní ààyè irú ànfàní kannáà, jẹ́ kí wọn ó sìn bí wọ́n ti fẹ́, níbití wọ́n fẹ́, tàbí ohun tí wọ́n fẹ́.
12 Àwa gbàgbọ́ nínú títẹríba fún àwọn ọba, àwọn ààrẹ, àwọn alákóso, àwọn onídãjọ́, ní gbígbọ́ràn, bíbu ọlá fún, àti ṣíṣe ìmúdúró òfin.
13 Àwa gbàgbọ́ nínú jíjẹ́ olõtọ́, aṣòótọ́, aláìlẽrí, onínú rere, oníwà rere, àti ṣíṣe rere sí gbogbo ènìyàn; nítòótọ́, àwa lè sọ pé a tẹ̀lé ìgbani-níyànjú ti Paúlù—Àwa gbà ohun gbogbo gbọ́, àwa ní ìrètí ohun gbogbo, àwa ti fi ara da ohun púpọ̀, a sì ní ìrètí láti lè fi ara da ohun gbogbo. Bí ohunkóhun bá jẹ́ ìwà rere, yẹ ní fífẹ́, tàbí ti ìhìn rere tàbí yẹ fún yíyìn, àwa nlépa àwọn ohun wọ̀nyí.
Joseph Smith.