Àwọn Ìwé Mímọ́
Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú


Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú

Píálì Olówó Iyebíye jẹ́ ìṣàyàn àwọn ohun ààyò tí ó fi ara kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abala pàtàkì ti ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwọn nkan wọnyí ni a ṣe àyípadà èdè rẹ̀ tí a sì pèsè láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith, tí a sì tẹ̀ ọ̀pọ̀ wọ́n jade nínú àwọn ìwé ìròhìn àtìgbà-dégbà Ìjọ ti àwọn ọjọ́ ayé rẹ̀.

Àkójọpọ̀ àkọ́kọ́ ti àwọn ohun èlò tí ó gbé àkòrí Píálì Olówó Iyebíye jẹ́ ṣíṣe ní 1851 láti ọwọ́ Alàgbà Franklin D. Richards, ọmọ Ìgbìmọ̀ àwọn Méjìlá àti ààrẹ ẹkùn Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbànáà. Èrò rẹ̀ ni láti mú kí àwọn àtẹ̀jáde pàtàkì kan tí wọn kò lọ káàkiri tó ní àkókò Joseph Smith kí ó túbọ̀ dé àrọ́wọ́tó àwọn ènìyàn síi. Bí àwọn ọmọ Ìjọ ṣe npọ̀ síi jákèjádò Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, ó di ohun tí a nílò láti mú àwọn ohun wọ̀nyí wà ní àrọ̀wọ́tó. Píálì Olówó Iyebíye náà ṣe ìtẹ́wọ́gbà káàkiri fún lílò àti ní àyọrísí, ó di òṣùnwọ̀n iṣẹ́ kan ti Ìjọ nípa iṣẹ́ ṣíṣe ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti ìpàdé gbogbogbò ní Ìlú Nlá Salt Lake ní 10 Oṣù Kẹwã 1880.

Onírúurú àwọn àtúnyẹ̀wò ni a ti ṣe nínú àwọn àkóonú rẹ̀ bí àwọn àìní Ìjọ ṣe ti béèré fún. Ní 1878 àwọn apákan ìwé Mósè tí kò sí nínú àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ní a fi kún un. Ní 1902 àwọn apákan Píálì Olówó Iyebíye tí àwọn ẹ̀dà rẹ̀ tún jẹ́ títẹ̀ jade bákannáà nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ní a fi sílẹ̀. Ètò ṣíṣe sí àwọn orí àti àwọn ẹsẹ, pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ ní ìsàlẹ̀ ìwé, ni a ṣe ní 1902. Àkọ́kọ́ tẹ̀ jade ní àwọn ojú ewé onílà méjì, pẹ̀lú atọ́ka, jẹ́ ní 1921. Kò sí àwọn àtúnṣe mĩràn tí a ṣe títí di Oṣù Kẹrin 1976, nígbàtí àwọn ohun méjì ti ìfihàn di fífi kún un. Ní 1979 àwọn ohun méjì wọ̀nyí di yíyọ kúrò nínú Píálì Olówó Iyebíye, a sì fi sínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, níbití wọ́n wà báyìí bíi ìpín 137 àti 138. Nínú àtẹ̀jáde ti ìsisìyí àwọn àtúnṣe díẹ̀ ni a ti ṣe láti mú ìwé náà wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìwé tí wọ́n ti wà ṣaájú.

Àtẹ̀lé wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ìṣaájú ní ṣókí sí àwọn àkóónú ti ìsisìyí:

  1. Àwọn àṣàyàn láti inú Ìwé ti Mósè. Àyọkà láti inú ìwé Gẹnẹ́sísì ti ìyírọ̀padà Bíbélì ti Joseph Smith, èyítí ó bẹ̀rẹ̀ ní Oṣù Kẹfà 1830.

  2. Ìwé ti Ábráhámù. Ìyírọ̀padà kan pẹ̀lú ìmísí ti àwọn ohun kíkọ Abrahámù. Joseph Smith bẹ̀rẹ̀ ìyírọ̀padà náà ní 1835 lẹ́hìn gbígbà pápírì ti àwọn ará Égíptì. Ìyírọ̀padà náà ni a tẹ̀ jade ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé nínú ìwé àtìgbàdégbà “Times and Seasons” bẹ̀rẹ̀ ní 1 Oṣù Kẹta 1842, ní Nauvoo, Illinois.

  3. Joseph Smith—Máttéù. Àyọkà láti inú ẹ̀rí ti Matteu nínú ìyírọ̀padà Bíbélì ti Joseph Smith (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:60–61 fún àṣẹ àtọ̀runwá láti bẹ̀rẹ̀ ìyírọ̀padà ti Májẹ̀mú Titun).

  4. Joseph Smith—Ìtàn. Àwọn àyọkà láti inú ẹ̀rí àti ìtàn Joseph Smith lábẹ́ àṣẹ, èyítí òun àti àwọn akọ̀wé rẹ̀ pèsè ní 1838–1839 àti èyítí a tẹ̀ jade ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé nínú ìwé àtìgbàdégbà “Times and Seasons” ní Nauvoo, Illinois, bẹ̀rẹ̀ ní 15 Oṣù Kẹta 1842.

  5. Àwọn Ohun Ìgbàgbọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ọ̀rọ̀ kan láti ọwọ́ Joseph Smith tí a tẹ̀ jade nínú ìwé àtìgbàdégbà “Times and Seasons” 1 Oṣù Kejì 1842, ní àjọṣe pẹ̀lú ìtan Ìjọ ní kúkúrú èyí tí ó jẹ́ mímọ̀ káàkiri bíi Lẹ́tà Wentworth.

Tẹ̀