Píálì Olówó Iyebíye Ojú Ewé Àkòrí Ọ̀rọ̀ ÌṣaájúPíálì Olówó Iyebíye jẹ́ ìṣàyàn àwọn ohun ààyò tí ó fi ara kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abala pàtàkì ti ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwọn nkan wọnyí ni a ṣe àyípadà èdè rẹ̀ tí a sì pèsè láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith, tí a sì tẹ̀ ọ̀pọ̀ wọ́n jade nínú àwọn ìwé ìròhìn àtìgbà-dégbà Ìjọ ti àwọn ọjọ́ ayé rẹ̀. Mósè Àwọn Àkóónú Mósè 1Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Mósè—A pa Mósè lára dà—A kò ó lójú láti ọwọ́ Sátánì—Mósè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé tí àwọ̀n ẹ̀dá ngbé—A ṣe ẹ̀dá àwọn ayé tí wọn kò ní ònkà láti ọwọ́ Ọmọ—Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ni láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ṣẹ fún ènìyàn. Mósè 2Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé—Gbogbo àwọn onírúurú ẹ̀yà ni a dá—Ọlọ́run dá ènìyàn Ó sì fún un ní ìjọba ní orí ohun gbogbo tí ó kù. Mósè 3Ọlọ́run dá ohun gbogbo ní ti ẹ̀mí ṣíwájú kí wọ́n ó tó wà ní àdánidá lorí ilẹ̀ ayé—Ó dá ọkùnrin, ẹran ara àkọ́kọ́, ní orí ilẹ̀ ayé—Obìnrin jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin. Mósè 4Bi Sátánì ṣe di èṣù—Ó dán Éfà wò—Ádámù àti Éfà ṣubú, ikú sì wọ inú ayé. Mósè 5Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ—Ádámù rú ẹbọ ó sì sin Ọlọ́run—A bí Káínì àti Ábẹ́lì—Káínì ṣe ọ̀tẹ̀, ó fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ, ó sì di Ègbé—Ìpànìyàn àti ìwa búburú tànká—Ìhìnrere ni a wàásù láti àtètèkọ́ṣe. Mósè 6Irú ọmọ Ádamù ṣe ìpamọ́ ìwé ìrántí kan—Àwọn olódodo irú ọmọ rẹ̀ wàásù ironúpìwàdà—Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Énọ́kù—Énọ́kù wàásù ìhìnrere—A fi ètò ìgbàlà hàn sí Ádámù—Òun gba ìrìbọmi àti oyè àlùfáà. Mósè 7Énọ́kù kọni, ó ṣaájú àwọn ènìyàn, ó ṣí àwọn òkè nídĩ—Ìlú nlá Síónì ni a gbé kalẹ̀—Énọ́kù ríran bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, ẹbọ-ọrẹ ètùtù Rẹ̀, àti àjínde ti àwọn Ènìyàn Mímọ́—Ó rí ìran Ìmúpadàbọ̀ sípò, Àkójọpọ̀ náà, Bíbọ̀ Èkejì, àti ìpadàbọ̀ Síónì. Mósè 8Mẹ̀túsẹlà sọ̀tẹ́lẹ̀—Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wàásù ìhìnrere—Ìwà búburú púpọ̀ tànkálẹ̀—Ìpè sí ironúpìwàdà di àìkàsí—Ọlọ́run pinnu ìparún sí gbogbo ẹran ara nípa Ìkún-omi. Abráhámù Àwọn Àkóónú Abráhámù 1Ábráhámù wá àwọn ìbùkún tí ètò pátríákì—A ṣe inúnibíni sí i láti ọwọ́ àwọn àlùfáà èké ní Káldéà—Jèhófàh gbà á là—Àwọn orísun àti ìjọba Égíptì ni a ṣe àtúnyẹ̀wò wọn. Abráhámù 2Ábráhámù kúrò ní Úrì láti lọ sí Kénáánì—Jéhófàh fi ara hàn án ní Háránì—Gbogbo àwọn ìbùkún ìhìnrere ni a ṣe ìlérí fún irú ọmọ rẹ̀ àti nípasẹ̀ irú ọmọ rẹ̀ sí gbogbo ènìyàn—Ó lọ sí Kénáánì àti síwájú sí Égíptì. Abráhámù 3Ábráhámù kọ́ nípa oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ nípasẹ̀ Úrímù àti Túmímù—Olúwa fi hàn sí i pé àwọn ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀dá ayérayé—Ó kọ́ nípa wíwà ṣaájú ilẹ̀ ayé, ìyàn tẹ́lẹ̀, Ìṣẹ̀dá, yíyàn Olùràpadà, àti ipò ẹ̀ẹ̀kejì ènìyàn. Abráhámù 4Àwọn Ọlọ́run ṣe ètò ìdásílẹ̀ ayé àti gbogbo alààyè inú rẹ̀—Àwọn ètò wọn fún ọjọ́ mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá di gbígbé kalẹ̀. Abráhámù 5Àwọn Ọlọ́run parí èrò wọn fún ṣíṣe ẹ̀dá ohun gbogbo—Wọ́n mú Ìṣẹ̀dá wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́bí àwọn èrò wọn—Ádámù fún gbogbo ẹ̀dá alàyè ní orúkọ. Àwòrán 1 Àwòrán 2 Àwòrán 3 Joseph Smith—MatteuJésù sọtẹ́lẹ̀ níti ìparun ti ó nbọ̀ láìpẹ́ ní Jérusálẹ́mù—ó tún kọ́ni ní ẹ̀kọ ní orí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Ọmọ Ènìyan, àti ìparun àwọn ènìyàn búburú. Joseph Smith—Ìwé ìtànJoseph Smith sọ nípa ìran rẹ̀, àwọn ẹbí, àti àwọn ibùgbé wọn ní ìbẹ̀rẹ̀—Ìtara tí kò wọ́pọ̀ gbilẹ̀ nípa ẹ̀sìn ní ìwọ̀ oòrùn New York—Ó pinnu láti wá ọgbọ́n bí Jámésì ṣe darí—Baba àti Ọmọ fi ara hàn, a sì pe Joseph sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí a ti sọtẹ́lẹ̀. (Àwọn ẹsẹ 1–20.) Àwọn Àkòrí Ìgbàgbọ́Àwa gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti nínú Ẹ̀mí Mímọ́.