Orí 1Ábráhámù wá àwọn ìbùkún tí ètò pátríákì—A ṣe inúnibíni sí i láti ọwọ́ àwọn àlùfáà èké ní Káldéà—Jèhófàh gbà á là—Àwọn orísun àti ìjọba Égíptì ni a ṣe àtúnyẹ̀wò wọn. Orí 2Ábráhámù kúrò ní Úrì láti lọ sí Kénáánì—Jéhófàh fi ara hàn án ní Háránì—Gbogbo àwọn ìbùkún ìhìnrere ni a ṣe ìlérí fún irú ọmọ rẹ̀ àti nípasẹ̀ irú ọmọ rẹ̀ sí gbogbo ènìyàn—Ó lọ sí Kénáánì àti síwájú sí Égíptì. Orí 3Ábráhámù kọ́ nípa oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ nípasẹ̀ Úrímù àti Túmímù—Olúwa fi hàn sí i pé àwọn ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀dá ayérayé—Ó kọ́ nípa wíwà ṣaájú ilẹ̀ ayé, ìyàn tẹ́lẹ̀, Ìṣẹ̀dá, yíyàn Olùràpadà, àti ipò ẹ̀ẹ̀kejì ènìyàn. Orí 4Àwọn Ọlọ́run ṣe ètò ìdásílẹ̀ ayé àti gbogbo alààyè inú rẹ̀—Àwọn ètò wọn fún ọjọ́ mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá di gbígbé kalẹ̀. Orí 5Àwọn Ọlọ́run parí èrò wọn fún ṣíṣe ẹ̀dá ohun gbogbo—Wọ́n mú Ìṣẹ̀dá wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́bí àwọn èrò wọn—Ádámù fún gbogbo ẹ̀dá alàyè ní orúkọ. Àwòrán 1 Àwòrán 2 Àwòrán 3