Àwọn Ìwé Mímọ́
Abráhámù 4


Orí 4

Àwọn Ọlọ́run ṣe ètò ìdásílẹ̀ ayé àti gbogbo alààyè inú rẹ̀—Àwọn ètò wọn fún ọjọ́ mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá di gbígbé kalẹ̀.

1 Àti nígbànáà Olúwa wípé: Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ìsàlẹ̀. Wọ́n sì lọ sí ìsàlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀, wọ́n sì, èyíinì ni àwọn Ọlọ́run, ṣe ètò wọ́n sì ṣe àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.

2 Ilẹ̀ ayé náà, lẹ́hìn tí a ti ṣe é, sì ṣófo ó sì jẹ́ ahoro, nítorítí wọ́n kò tíì ṣe ohunkóhun bíkòṣe ilẹ̀ ayé; òkùnkùn sì jọba ní ojú ibú, Ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run sì nrábàbà lójú àwọn omi.

3 Wọ́n (àwọn Ọlọ́run) sì wípé: Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà; ìmọ́lẹ̀ sì wà.

4 Wọ́n (àwọn Ọlọ́run) sì dá ìmọ́lẹ̀ náà mọ̀, nítorí ó mọ́lẹ̀; wọ́n sì pín ìmọ́lẹ̀, tàbí mú kí ó jẹ pípín, kúrò lára òkùnkùn.

5 Àwọn Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ ní Ọ̀sán, àti òkùnkùn ni wọ́n pè ní Òru. Ó sì ṣe pé láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ní wọ́n pè ní òru; àti láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́ ni wọ́n pè ní ọ̀sán; èyí sì ni àkọ́kọ́, tàbí ìbẹ̀rẹ̀, ti èyíinì tí wọ́n pè ní ọ̀sán àti òru.

6 Àwọn Ọlọ́run sì wí bákannáà pé: Jẹ́ kí òfurufú kan kí ó wà ní ààrin àwọn omi, òun yíò sì pín àwọn omi kúrò lara àwọn omi.

7 Àwọn Ọlọ́run sì pàṣẹ fún òfurufú, tí ó fi pín àwọn omi èyítí ó wà ní ìsàlẹ̀ òfurufú kúrò ní ara àwọn omi èyítí ó wà ní òkè òfurufú náà; ó sì rí bẹ́ẹ̀, àní bí wọ́n ṣe pàṣẹ.

8 Àwọn Ọlọ́run sì pe òfurufú náà ní, Ọ̀run. Ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ni wọ́n pè ní òrù; ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́ ni wọ́n pè ní ọ̀sán, èyí sì jẹ́ ìgbà kejì tí wọ́n pe òru àti ọ̀sán.

9 Àwọn Ọlọ́run sì pàṣẹ, wípé: Jẹ́ kí àwọn omi abẹ́ ọ̀run ó wọ́ papọ̀ sí ibì kan, sì jẹ́ kí ìyàngbẹ kí ó wà ní ilẹ̀ ayé; ó sì rí bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe pàṣẹ;

10 Àwọn Ọlọ́run sì kéde ilẹ̀ gbígbẹ ní, Ìlẹ̀ ayé; àti àkójọpọ̀ àwọn omi, ni wọ́n kéde ní, àwọn Omi Nlá; àwọn Ọlọ́run sì ríi pé wọ́n gbọ́ràn sí àwọn lẹ́nu.

11 Àwọn Ọlọ́run sì wípé: Ẹ jẹ́ kí á pèsè ilẹ̀ ayé láti mú koríko jade wá; èso tí nmú ewébẹ̀ wá; igi eléso tí nmú èso wá, bí irú tirẹ̀, èyítí èso rẹ̀ nínú òun tìkára rẹ̀ nmú àfijọ tirẹ̀ wá ní orí ilẹ̀ ayé; ó sì rí bẹ́ẹ̀, àní bí wọ́n ṣe pàṣẹ.

12 Àwọn Ọlọ́run sì ṣe ètò ilẹ̀ ayé láti mú koríko jade wá láti inú èso tirẹ̀, àti ewébẹ̀ láti mú ewébẹ̀ jade wá láti inú èso tirẹ̀, ní síso èso bíi irú tirẹ̀; àti ilẹ̀ ayé láti mú igi hù jade wá láti inú èso tirẹ̀, ní síso èso, irú èyítí ó lè mú èso kannáà irú tirẹ̀ nikan jade wá, bíi irú tirẹ̀; àwọn Ọlọ́run sì ríi pé wọ́n gbọ́ràn sí àwọn lẹ́nu.

13 Ó sì ṣe tí wọ́n ka iye àwọn ọjọ́; láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ni wọ́n pè ní òru; ó sì ṣe, láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́ ni wọ́n pè ní ọ̀sán; ó sì di ìgbà kẹta.

14 Àwọn Ọlọ́run sì ṣe ètò àwọn ìmọ́lẹ̀ ní òfurufú ọ̀run, a sì mú kí wọ́n kí ó pín ọ̀sán kúro ní ara òru; a sì ṣe ètò wọn láti dúró fún àwọn àmì àti fún àwọn ìgbà, àti fún àwọn ọjọ́ àti fún àwọn ọdún;

15 Wọ́n sì ṣe ètò wọn láti wà fún ìmọ́lẹ̀ ní òfurufú ọ̀run láti fi ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé; ó sì rí bẹ́ẹ̀.

16 Àwọn Ọlọ́run sì ṣe ètò àwọn ìmọ́lẹ̀ nlá méjì, ìmọ́lẹ̀ èyí tí ó tóbì jù láti ṣe àkóso ọ̀sán, àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru; pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ tí ó keré ni wọ́n gbé àwọn ìràwọ̀ kalẹ̀ bákannáà;

17 Àwọn Ọlọ́run sì gbé wọn kalẹ̀ ní òfurufú ti àwọn ọ̀run, láti fi ìmọ́lẹ̀ fún ilẹ̀ ayé, àti láti ṣe àkóso ní orí ọ̀sán àti ní orí òru, àti láti mú kí ìmọ́lẹ̀ pín kúrò lára òkùnkùn.

18 Àwọn Ọlọ́run sì ṣọ́ àwọn ohun wọnnì èyítí wọn ti pàṣẹ fún títí tí wọ́n fi gbọ́ràn.

19 Ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ni ó jẹ́ òru; ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣàálẹ́ ni ó jẹ́ ọ̀sán; ó sì di ìgbà kẹrin.

20 Àwọn Ọlọ́run sì wí pé: Ẹ jẹ́kí á pèsè àwọn omi láti mú àwọn ẹ̀dá alààyè tí nrìn jade wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, kí wọn ó le máa fò ní òkè ilẹ̀ ayé nínú òfurufú ọ̀run.

21 Àwọn Ọlọ́run sì pèsè àwọn omi pé kí wọ́n kí ó lè mú àwọn ẹja nlá jade wá, àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí nrìn, èyítí àwọn omi yíò mú jade wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní irú wọn; àti èyíkéyìí ẹyẹ àbìyẹ́ ní irú wọn. àwọn Ọlọ́run sì ríi pé wọn yíò gbọ́ràn sí àwọn lẹ́nu, àti pé èrò àwọn dára.

22 Àwọn Ọlọ́run sì wípé: Àwa yíò súre fún wọn, a ó sì mú kí wọn ó ní èso àti kí wọn ó di púpọ̀, kí wọn ó sì kún inú àwọn omi nínú àwọn òkun tàbí àwọn omi nlá; a ó sì mú kí ẹyẹ ojú ọ̀run di púpọ̀ síi ní ilẹ̀ ayé.

23 Ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ni wọ́n pè ní òrù; ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́ ni wọ́n pè ní ọ̀sán; ó sì di ìgbà karũn.

24 Àwọn Ọlọ́run sì pèsè ilẹ̀ ayé láti mú ẹ̀dá alààyè jade wá ní irú tirẹ̀, ẹran ọ̀sìn àti àwọn ohun tí nrákò, àti àwọn ẹran ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé bíi irú tiwọn; ó sì rí bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe wí.

25 Àwọn Ọlọ́run sì ṣe ètò ilẹ̀ ayé láti mú àwọn ẹranko ìgbẹ́ jade ní irú tiwọn, àti àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn, àti olukúlùkù ohun tí nrákò ní orí ilẹ̀ ayé ní irú tiwọn; àwọn Ọlọ́run sì ríi pé wọn yíò gbọ́ràn.

26 Àwọn Ọlọ́run sì gba ìmọ̀ràn lààrin ara wọn wípé: Ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ kí a sì dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, ní ìrí wa; àwa ó sì fún wọn ní ìjọba ní orí ẹja inú òkun, àti ní orí ẹ̀yẹ ojú ọ̀run, àti ní orí àwọn ẹran ọ̀sìn, àti ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti ní orí olukúlùkù ohun arákòrò tí nrákò ní orí ilẹ̀ ayé.

27 Nítorínáà àwọn Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ lọ láti ṣe ètò ènìyàn ní àwòrán ara wọn, ní àwòrán ti àwọn Ọlọ́run ni wọ́n dá a, akọ àti abo ni wọ́n dá wọn.

28 Àwọn Ọlọ́run sì wí pé: A ó súre fún wọn. Àwọn Ọlọ́run sì wípé: A ó mú kí wọ́n ní èso àti kí wọn ó di púpọ̀ síi, kí wọn ó sì gbìlẹ̀ ní ayé, kí wọn ó ní agbára ní orí rẹ̀, àti láti jọba ní orí ẹja òkun, àti ní orí ẹyẹ inú afẹ́fẹ́, àti ní orí olukúlùkù ohun abẹ̀mí tí ó nrìn ní orí ilẹ̀ ayé.

29 Àwọn Ọlọ́run sì wí pé; Kíyèsíi, a ó fún wọn ní olukúlùkù ewébẹ̀ tí ó nso irúgbìn tí yíò wá sí orí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti olukúlùkù igi èyítí yíò ní èso ní orí rẹ̀; bẹ́ẹ̀ni, èso igi tí ó nso irúgbìn àwa ó fi í fún wọn; yíò jẹ́ fún oúnjẹ wọn.

30 Àti sí olukúlùkù ẹranko ìgbẹ́ ti ilẹ̀ ayé, àti sí olukúlùkù ẹyẹ ojú ọ̀run, àti sí olukúlùkù ohun tí nrákò ní orí ilẹ̀ ayé, kíyèsíi, àwa ó fún wọn ní ìyè, àti pẹ̀lú a ó fún wọn ní olukúlùkù èwébẹ̀ tútù fún oúnjẹ, gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni a ó sì ṣe ètò bẹ́ẹ̀.

31 Àwọn Ọlọ́run sì wípé: Àwa yíò ṣe gbogbo ohun tí a ti wí, a ó sì ṣe èto wọn; sì kíyèsíi, wọn yíò jẹ́ olùgbọ́ràn gidigidi. Ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti àṣálẹ́ títí di òwúrọ̀ ni wọ́n pè ní òru; ó sì ṣe tí ó jẹ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣálẹ́ ni wọ́n pè ní ọ̀sán; wọ́n sì ka ìgbà kẹfà.

Tẹ̀