Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwòrán 3


Àwòrán láti inú Ìwé Ábráhámù

Ònkà Kẹta

Àwòrán 3

Àsọyé

Àwòrán 1. Ábráhámù jókòó ní orí ìtẹ́ Fáráò, nípa ìwà àpọ́nlé ọba náà, pẹ̀lú adé kan ní orí rẹ̀, tí ó dúró fún Oyè Àlùfáà, bí àpẹrẹ Àjọ Ààrẹ̀ tí ó ga jùlọ ní Ọ̀run; pẹ̀lú ọ̀pá aládé ti òdodo àti ìdájọ́ ní ọwọ́ rẹ̀.

Àwòrán 2. Ọba Fáráò, ẹnití a fúnni ní orúkọ rẹ̀ nínú àwọn àmì tí ó wà ní òkè orí rẹ̀.

Ǎwòrán 3. Dúró fún Ábráhámù ní Égíptì bí a ṣe fúnni nínú àwòrán 10 níti Àwòrán ònkà 1.

Àwòrán 4. Ọmọ Ọba ti Fáráò, Ọba Égíptì, bí a ṣe kọọ́ sí òkè apá rẹ̀.

Ǎwòrán 5. Ṣúlẹ́mù, ọ̀kan nínú àwọn olórí agbọ́tí ọba, bí wọ́n ti ṣe àpéjúwe rẹ̀ nípa àwọn àmì ní òkè apá rẹ̀.

Àwòrán 6. Olímlà, ẹrú kan tí ó jẹ́ ti ọmọ ọba náà.

Ábráhámù nsọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní orí àwọn ìpìlẹ̀ ẹkọ́ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn ìràwọ̀ àti òfurufú, ní àfin ọba náà.