Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwòrán 2


Àwòrán láti inú Ìwé Ábráhámù

Ònkà Kejì

Àwòrán
Àwòrán 2

Àsọyé

Àwòrán 1. Kólóbù, tí ó ntọ́kasí ẹ̀dá àkọ́kọ́, sísúnmọ́ sẹ̀lẹ́stíà jùlọ, tàbí ibùgbé Ọlọ́run. Àkọ́kọ́ nínú ìjọba, èyí tí ó kẹ́hìn ní jíjẹmọ́ òdiwọ̀n àkókò. Òdiwọ̀n ní ìbámu sí àkókò sẹ̀lẹ́stíà, àkókò sẹ̀lẹ́stíà èyítí ó jẹ́ ọjọ́ kan sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Ọjọ́ kan ní Kólóbù jẹ́ deedé ẹgbẹ̀rún ọdún kan ní ìbámu sí òdiwọ̀n ti ilẹ̀ ayé yìí, èyítí àwọn ará Égíptì pè ní Jah-oh-eh.

Àwòrán 2. Dúró tẹ̀lé Kólóbù, tí àwọn ará Égíptì npè ní Ólíbílíṣì, èyítí ó jẹ́ àtẹ̀lé ẹdá pàtàkì tí ó nṣe àkóso ní ẹ̀bá sẹ̀lẹ́stíà tàbí ibití Ọlọ́run ngbé; tí ó ní kọ́kọ́rọ́ agbára bákannáà, tí ó jẹ mọ́ àwọn ohun míràn tí nyípo òòrùn; bí a ṣe fi hàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí Ábráhámù, bí òun ṣe rú ẹbọ ní orí pẹpẹ kan, èyíti òun ti kọ́ sí Olúwa.

Àworán 3. Ni a ṣe láti dúró fún Ọlọ́run, ní jíjókòó ní orí ìtẹ̀ rẹ̀, tí a wọ̀ ní aṣọ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ; pẹ̀lú adé ti ìmọ́lẹ̀ ayérayé kan ní orí rẹ̀; tí ó dúró bákannáà fún àwọn Kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì ti Oyè Àlùfáà Mímọ́, bí a ṣe fi hàn sí Ádámù nínú Ọgbà Édẹ́nì, bíi bákannáà sí Sẹ́tì, Nóà, Melkisédekì, Ábráhámù, àti gbogbo ẹnití a fi Oyè Àlùfáà hàn sí.

Àwòrán 4. Jẹ́ bákannáà sí ọ̀rọ̀ Hébérù Raukeyang, tí ó tọ́kasí òfurufú, tàbí ojú àlàfo ti àwọn ọ̀run; bákannáà àpẹrẹ ònkà kan, ní Égíptì tí ó dúró fún ẹgbẹ̀rún kan; tí ó jẹ́ bákannáà sí wíwọ̀n àkókò ti Ólíbílisì, èyítí ó dọ́gba pẹ̀lú Kólóbù nínú ìyípo rẹ̀ àti nínú síṣe ìdiwọ̀n àkókò.

Àwòrán 5. Ni a pè ní Eníṣ-go-on-doṣì ní èdè Égíptì; èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìràwọ̀ tí nse àkóso pẹ̀lú, a sì wí láti ẹnu àwọn ará Égíptì pé ó jẹ́ Oòrùn, àti pé ó yá ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ láti ara Kólóbù nípasẹ̀ Kae-e-vanrash, èyítí ó jẹ́ Kókó pàtàkì, tàbí, ní ọ̀rọ̀ míràn, àgbára àkóso náà, èyítí ó nṣe àkóso àwọn ohun tí nyipo òọ̀run mẹ̃dógún míràn tàbí àwọn ìràwọ̀ tí wọn kò kúrò lójú kannáà, bíi ti Floeese pẹ̀lú tàbí Òṣùpá, Ilẹ̀ ayé àti Oòrùn nínú àwọn ìyípo wọn ọdọ̃dún. Ìràwọ̀ yìí ngba agbára rẹ̀ nípasẹ̀ ohun èlò ti Kli-flos-is-es, tàbí Hah-ko-kau-beam, àwọn ìràwọ̀ tí òunkà 22 àti 23 dúró fún, tí ó ngba ìmọ́lẹ̀ láti ìbi àwọn ìyípo ti Kólóbù.

Àwòrán 6. Dúró fún ilẹ̀ ayé yìí ní àwọn igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀.

Àwòrán 7. Dúró fún Ọlọ́run ní jíjókòó ní orí ìtẹ́ rẹ̀, ní fífi Kókó àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì ti Oyè Àlùfáà hàn nípasẹ̀ àwọn ọ̀run; bíi, bákannáà, àmì ti Ẹ̀mí Mímọ́ sí Ábráhámù, ní ẹ̀yà àdàbà.

Àwòrán 8. Ó ní àwọn àkọsílẹ̀ tí a kò lè fi hàn sí ayé nínú; ṣùgbọ́n tí a lè ní nínú Tẹ́mpìlì Mímọ́ Ọlọ́run.

Àwòrán 9. Kò yẹ kí ó jẹ́ fífihàn ní àkókò yìí.

Àwòrán 10. Bákannáà.

Àwòrán 11. Bákannáà. Bí aráyé bá lè ṣe àwárí àwọn ònkà wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ni kí ó rí. Àmín.

Àwọn àwòrán 12, 13, 14, 15, 16, 17, 18, 19, 20, àti 21 ni yíò jẹ́ fífúnni ní àkókò tí ó tọ́ lójú Olúwa.

Ìtumọ̀ tí ó wà lókè yìí ni a fúnni bí a ṣe ní ẹ̀tọ́ tó láti fúnnni ní àkókò yìí.

Tẹ̀