Orí 8
(Oṣù Kejì 1831)
Mẹ̀túsẹlà sọ̀tẹ́lẹ̀—Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wàásù ìhìnrere—Ìwà búburú púpọ̀ tànkálẹ̀—Ìpè sí ironúpìwàdà di àìkàsí—Ọlọ́run pinnu ìparún sí gbogbo ẹran ara nípa Ìkún-omi.
1 Gbogbo àwọn ọjọ́ Énọ́kù sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́rin àti ọgbọ̀n ọdún.
2 Ó sì ṣe tí a kò mú Mẹ̀túsẹ́là, ọmọ Énọ́kù, lọ, kí àwọn májẹ̀mú Olúwa ó lè wá sí ìmúṣẹ, èyítí òun bá Énọ́kù dá; nítorí ó dá májẹ́mú pẹ̀lu Énọ́kù nítòótọ́ pé Nóà yíó jẹ́ irú ọmọ inú rẹ̀.
3 Ò sì ṣe tí Mẹ̀túsẹ́là sọtẹ́lẹ̀ pé láti ara irú ọmọ inú rẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba ilẹ̀ ayé yíò ti jade wá (nípasẹ̀ Nóà), òun sì fi ògo fún ara rẹ̀.
4 Ìyàn nlá kan sì jade sí orí ilẹ̀ náà, Ọlọ́run sì fi ilẹ̀ ayé bú pẹ̀lú ìfibú kíkan, púpọ̀ lára àwọn olùgbé inú rẹ̀ sì kú.
5 Ó sì ṣe tí Mẹtúsẹ́là gbé fún ọgọ́sãn ọdún ó lé méje, òun sì bí Lámẹ́kì;
6 Mẹ̀túsẹlà sì gbé ọgọ́rũn méje àti ọgọ́rin ọdún ó lé méjì, lẹ́hìn tí ó bí Lámẹ́kì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin;
7 Gbogbo àwọn ọjọ́ Mẹ̀túsẹ́là sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn àti ọgọ́ta ọdún ó lé mẹ́sãn, ó sì kú.
8 Lámẹ́kì sì gbé ọgọ́sãn ọdún ó lé méjì, ó sì bí ọmọkùnrin kan,
9 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà, wípé: Ọmọ yìí ni yíò tù wá nínú nípa ti iṣẹ́ wa àti lãlã ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi bú.
10 Lámẹ́kì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́fà ọdún ó dín márũn, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin;
11 Gbogbo àwọn ọjọ́ Lámẹ́kì sì jẹ́ ọgọ́rũn méje ati àádọ́rin ọdún o lé méje, ó sì kú.
12 Nóà sì jẹ́ ẹni ọgọ́rũn mẹ́rin àti àádọ́ta ọdún, ó sì bí Jáfẹ́tì; ní ọdún méjìlélógójì lẹ́hìn ìgbà náà ó sì bí Ṣémù nipa ẹni náà tí ṣe ìyá Jáfẹ́tì, àti nígbàtí ó jẹ́ ẹni ọgọ́rũn márũn ọdún ó bí Hamù.
13 Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì fetísílẹ̀ sí Olúwa, wọ́n sì ṣe ìgbọ́ràn, a sì pè wọ́n ní àwọn ọmọ Ọlọ́run.
14 Àti nígbàtí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀sí bí síi ní orí ilẹ̀ ayé, tí a sì bí àwọn ọmọbìnrin fún wọn, àwọn ọmọ ènìyàn ríi pé àwọn ọmọbìnrin wọnnì rẹwà, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ìyàwó, àní bí wọ́n ṣe yàn.
15 Olúwa sì wí fún Nóà: Àwọn ọmọbìnrin ti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti ta ara wọn; nítorí kíyèsíi ìbínú mi ti ru sókè sí àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí wọn kò fetísílẹ̀ sí ohùn mi.
16 Ó sì ṣe tí Nóà ṣọtẹ́lẹ̀, ó sì kọ́ni ní àwọn ohun ti Ọlọ́run, àní bí ó ṣe rí lati ìbẹ̀rẹ̀ wá.
17 Olúwa sì wí fún Nóà; Ẹ̀mí mi kì yíò fi ìgbà-gbogbo bá ènìyàn ṣe, nítorí òun yíò mọ̀ pé gbogbo ẹran ara ní yíò kú; síbẹ̀ àwọn ọjọ́ rẹ̀ yíò sì jẹ́ ọgọ́fà ọdún; bí àwọn ènìyàn kò bá sì ronúpìwàdà, èmi yíò rán àwọn ìkún omi sí orí wọn.
18 Àti ní àwọn ọjọ́ wọnnì àwọn òmìrán wà ní orí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì lépa Nóà láti gba ẹ̀mí rẹ̀; ṣùgbọ́n Olúwa wà pẹ̀lú Nóà, agbára Olúwa sì wà lára rẹ̀.
19 Olúwa sì yan Nóà ní àtẹ̀lé ètò tirẹ̀, ó pàṣẹ fún pé kí ó jade lọ kí ó sì kéde Ìhìnrere rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, àní bí a ṣe fi fún Énọ́kù.
20 Ó sì ṣe tí Nóà ké pe àwọn ọmọ ènìyàn pé kí wọ́n ó ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀;
21 Àti pẹ̀lú, lẹ́hìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n gòkè wá sí iwájú rẹ̀, wípé: Kíyèsí, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run; njẹ́ àwa kò ha ti mú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn sí ọ̀dọ̀ ara wa bí? Àti pé njẹ́ àwa kò ha ti njẹ tí a sì nmu, àti tí a ngbéyàwó tí a sì nfi fúnni ní ìgbéyàwó? Àti tí àwọn ìyàwó wa nbí àwọn ọmọ fún wa, àwọn yìí kannáà sì jẹ́ alágbára ènìyàn, tí wọ́n dàbí àwọn ènìyàn ìgbàanì, àwọn ènìyàn olókìkí nlá. Wọ́n kò sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Nóà.
22 Ọlọ́run sì ríi pé ìwà búburú àwọn ènìyàn ti di púpọ̀ ní ilẹ̀ ayé; olúkúlùkù ènìyàn sì jẹ́ gbígbé sókè nínú àfinúrò ti àwọn èrò ọkàn rẹ̀, tí ó tẹ̀síwájú lati jẹ́ kìkìdá ibi.
23 Ó sì ṣe tí Nóà tẹ̀síwájú nínú ìwàásù rẹ̀ sí àwọn ènìyàn náà, wípé: Ẹ fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi;
24 Ẹ gbàgbọ́ kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín kí a sì rì yín bọmi ní orúkọ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, àní bí àwọn bàbá wa, ẹ̀yin yíò sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, pé kí a lè fi ohun gbogbo hàn síi yín; àti bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí, àwọn ìkún omi yíò wá sí orí yín; ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀.
25 Ó sì mú kí Nóà kábamọ̀, ọkàn rẹ̀ sì ní ìrora pé Olúwa dá ènìyàn sí orí ilẹ̀ ayé, ó sì dùn ún nínú ọkàn.
26 Olúwa sì wípé: Èmi yíò pa ènìyàn ẹnití èmi ti dá run, kúrò ni orí ilẹ̀ ayé, àti ènìyàn àti ẹranko, àti àwọn ohun tí nràkò, àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; nítorí Nóà kábamọ̀ pé èmi dá wọn, àti pé èmi ṣe ẹ̀dá wọn; òun sì ti ké pè mí; nítorí wọ́n ti lépa ẹ̀mí rẹ̀.
27 Báyìí sì ni Nóà rí ore ọ̀fẹ́ ní ojú Olúwa; nítorí Nóà jẹ́ olõtọ́ ènìyàn, àti ẹni pípé ní ìran rẹ̀; ó sì rìn pẹ̀lú Ọlọ́run, bí àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ta Ṣémù, Hámù, àti Jáfẹ́tì ti ṣe pẹ̀lú.
28 Ìlẹ̀ ayé ti díbàjẹ́ níwájú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá.
29 Ọlọ́run sì wo orí ilẹ̀ ayé, àti, kíyèsíi, ó ti díbàjẹ́, nítorí gbogbo ẹran ara ti ba ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ní orí ilẹ̀ ayé.
30 Ọlọ́run sì wí fún Nóà: Òpin gbogbo ẹran ara ti dé níwájú mi, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá, sì kíyèsíi èmi yíò pa gbogbo ẹran ara run kúrò ní ilẹ̀ ayé.