Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 7


Orí 7

(Oṣù Kejìlá 1830)

Énọ́kù kọni, ó ṣaájú àwọn ènìyàn, ó ṣí àwọn òkè nídĩ—Ìlú nlá Síónì ni a gbé kalẹ̀—Énọ́kù ríran bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, ẹbọ-ọrẹ ètùtù Rẹ̀, àti àjínde ti àwọn Ènìyàn Mímọ́—Ó rí ìran Ìmúpadàbọ̀ sípò, Àkójọpọ̀ náà, Bíbọ̀ Èkejì, àti ìpadàbọ̀ Síónì.

1 Ó sì ṣe tí Énọ́kù tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, wípé: Kíyèsíi, bàbá wa Ádámù kọ́ni ní àwọn nkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì ti gbàgbọ́ tí wọ́n sì di ọmọ Ọlọ́run, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò gbàgbọ́, tí wọ́n sì ti ṣègbé nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n sì nwò iwájú pẹ̀lú ẹ̀rù, nínú oró, nítorí gbígbóná ìrunú ti ìbínú Ọlọ́run tí a ó tú jade sí orí wọn.

2 Àti láti ìgbà náà lọ Énọ́kù bẹ̀rẹ̀sí sọ̀tẹ́lẹ̀, ní wíwí fún àwọn ènìyàn náà, pé: Bí mo ṣe nrìn ìrìnàjò lọ, tí mo sì dúró ní ibi Máhujah, tí mo sì kígbe sí Olúwa, níbẹ̀ ni ohùn kan jade láti ọ̀run wá, wípé—Yí padà, kí o sì lọ sí orí òkè Símeónì.

3 Ó sì ṣe tí mo yípadà tí mo sì gòkè lọ sí orí òkè náà; bí mo sì ti dúró ní orí òkè náà, mo rí tí àwọn ọ̀run ṣí, a sì wọ̀ mí ní aṣọ pẹ̀lú ògo;

4 Mo sì rí Olúwa; ó sì dúró ní iwájú mi, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mi, àní bí ènìyàn ṣe nsọ̀rọ̀ ní ẹnìkan pẹ̀lú ẹlòmíràn, ní ojúkojú; ó sì wí fún mi: Wõ, èmi yíò sì fi ayé hàn ọ fún àlàfo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrandíran.

5 Ó sì ṣe tí mo ríi ní àfonífòjì Ṣúmù, sì wõ, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ngbé nínú àwọn àgọ́, tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn Ṣúmù.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi Olúwa sì wí fún mi: Wõ; mo sì wo ìhà àríwá náà, mo sì rí àwọn ènìyàn Kénáánì, tí wọ́n ngbé nínú àwọn àgọ́.

7 Olúwa sì wí fún mi: Sọtẹ́lẹ̀; mo sì sọ̀tẹ́lẹ̀, wípé: Kíyèsí àwọn ènìyàn Kénáánì, tí wọ́n pọ̀ ní iye, yíò jade lọ ní ìmúra ogun sí àwọn ènìyàn ti Ṣúmù, wọn yíò sì pa wọ́n tí wọn yíò di píparun pátápátá; àwọn ènìyàn Kénáánì yíò sì pín ara wọn ní ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yíò si jẹ́ aṣálẹ̀ àti aláìléso, kì yíò sì sí àwọn ènìyàn míràn tí yíò gbé níbẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Kénáánì;

8 Nítorí kíyèsíi, Olúwa yíò fi ilẹ̀ náà bú pẹ̀lú ooru púpọ̀, àti yíya àgàn ibẹ̀ yíò wà lọ títí láé; àwọ̀ ara dúdú sì wá sí orí gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì, tí wọ́n di fífi ṣe ẹ̀sín ní ààrin gbogbo ènìyàn.

9 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi: Wõ; mo sì wò, mo sì rí ilẹ̀ Ṣárónì, àti ilẹ̀ Énọ́kù, àti ilẹ̀ ti Ómnérì, àti ilẹ̀ ti Hénì, àti ilẹ̀ ti Ṣémù, àti ilẹ̀ ti Hánérì, àti ilẹ̀ ti Hananníhà, àti gbogbo àwọn olùgbé inú wọn;

10 Olúwa sì wí fún mi: Lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn yìí, kí o sì wí fún wọn—Ẹ ronúpìwàdà, bíbẹ́ẹ̀kọ́ èmi yíò jade wá láti kọlù wọ́n pẹ̀lú ìfibú kan, wọ́n yíó sì kú.

11 Ó sì fún mi ní òfin kan pé kí èmi ó rì bọmi ní orúkọ ti Bàbá, àti ti Ọmọ, èyítí ó kún fún ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó jẹ́rìí ti Bàbá àti Ọmọ.

12 Ó sì ṣe tí Énọ́kù tẹ̀síwájú láti pe gbogbo ènìyàn, bíkòṣe àwọn ènìyàn ti Kénáánì, láti rónúpìwàdà;

13 Ìgbàgbọ́ Énọ́kù sì pọ̀ gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí òun fi ṣíwájú àwọn ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọ̀tá wọn sì wá láti jagun pẹ̀lú wọ́n; òun sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, ilẹ̀ ayé sì wárìrì, àwọn òkè sì sá, àní gẹ́gẹ́bí àṣẹ rẹ̀; àti àwọn omi odò náà ni a yà kúrò ní ipa ọ̀nà wọn; àti bíbú ramúramù àwọn kìnìún ni a gbọ́ láti inú ijù; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì bẹ̀rù gidigidi, kíkún fún agbára púpọ̀ ni ọ̀rọ̀ Énọ́kù, àti títóbi gidigidi ni agbára èdè tí Ọlọ́run ti fi fún un.

14 Bákannáà ni ilẹ̀ kan jade sókè láti inú ibú òkun, púpọ̀ gidigidi sì ni ìbẹ̀rù àwọn ọ̀tá àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí wọ́n sá tí wọ́n si dúró ní ọ̀nà jíjìn wọn sì lọ sí orí ilẹ̀ náà èyítí ó jade sókè láti inú ibú òkun.

15 Àti àwọn òmìrán ilẹ̀ náà, bákannáà, dúró ni ọ̀nà jíjìn; ìfibú kan sì jade lọ níbẹ̀ sí orí gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n nbá Ọlọ́run jà;

16 Àti láti ìgbà náà lọ ni àwọn ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ti wà ní ààrin wọn; ṣùgbọ́n Olúwa wá ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, wọ́n sì gbé nínú òdodo.

17 Ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ní orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, púpọ̀ gidigidi sì ni ògo Olúwa, èyítí ó wà ní orí àwọn ènìyàn rẹ̀. Olúwa sì súre fún ilẹ̀ náà, wọ́n sì di alábúkún fún ní orí àwọn òkè, àti ní orí àwọn ibi gíga, wọ́n sì gbilẹ̀.

18 Olúwa sì pe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nítorítí wọn wà ní ọkàn kan àti inú kan, tí wọ́n sì gbé nínú òdodo; tí kò sì sí tálákà ní ààrin wọn.

19 Énọ́kù sì tẹ̀síwájú ìwàásù rẹ̀ nínú òdodo sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì ṣe ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, tí òun kọ́ ìlú nlá kan tí a pè ní Ìlú Nlá Mímọ́, àní Síónì.

20 Ó sì ṣe tí Énọ́kù sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwa; ó sì wí fún Olúwa: Dájúdájú Síónì yíò gbé ní àìléwu titi láé. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún Énọ́kù; Síónì ni èmi ti súre fún, ṣùgbọ́n ìyókù àwọn ènìyàn ni èmi ti fi bú.

21 Ó sì ṣe tí Olúwa fi gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé han Énọ́kù; ó sì ríi, sì wõ, Síónì, bí ìgbà ti nlọ, a mú un gòkè lọ sí ọ̀run. Olúwa sì wí fún Énọ́kù: Kíyèsí ibùgbé mi títí láé.

22 Énọ́kù sì tún kíyèsí ìyókù àwọn ènìyàn náà tí wọn jẹ́ àwọn ọmọ Ádámù; wọ́n sì jẹ́ àdàlù ti gbogbo irú ọmọ Ádámù bíkòṣe èyí tí ó jẹ́ irú ọmọ Káínì, nítorí irú ọmọ Káínì jẹ́ dúdú, tí wọn kò sì ní àyè lààrin wọn.

23 Àti lẹ́hìn tí a ti mú Síónì lọ si òkè ọ̀run, Énọ́kù ríi, sì wõ, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé wà ní iwájú rẹ̀;

24 Níbẹ̀ ni ìràndíran lẹ́hìn ìrandíran sì wá; Énọ́kù sì wà lókè a sì gbé e ga sókè, àní ní õkan àyà Bàbá, àti ti Ọmọ Ènìyàn; kíyèsíi, agbára Sátánì sì wà ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

25 Ó sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọn nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run; ó sì gbọ́ ohùn ariwo nlá wípé: Ègbé, ègbé ni fún àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.

26 Ó sì rí Sátánì; ó sì ní ẹ̀wọn nlá kan ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo gbogbo ilẹ̀ ayé pẹ̀lú òkùnkùn; òun sì wo òkè ó rẹ́rĩn, àwọn ángẹ́lì rẹ̀ sì yọ̀.

27 Énọ́kù sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, tí wọn njẹrĩ Bàbá àti Ọmọ; Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé ọ̀pọ̀lọpọ̀, a sì gbà wọ́n sókè nípa àwọn agbára ọ̀run sí inú Síónì.

28 Ó sì ṣe tí Ọlọ́run ọ̀run wo ìyókù àwọn ènìyàn náà, òun sì sunkún; Énọ́kù sì jẹrĩ sí i, wípé: Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí àwọn ọ̀run sunkún, tí wọ́n sì ta omi ojú wọn sílẹ̀ bí òjò ní orí àwọn òkè?

29 Énọ́kù sì wí fún Olúwa: Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí ìwọ lè sunkún, ní rírí pé ìwọ jẹ́ mímọ́, àti láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé?

30 Àti pé ìbá ṣeéṣe kí ènìyàn ó lè ka iye ohun kékeré jùlọ ti ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹgbẹ̀rún ilẹ̀ ayé bí èyí, kò lè jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ kan sí iye àwọn ẹ̀dá rẹ; àwọn aṣọ títa rẹ sì nà jáde síbẹ̀; àti síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ wà níbẹ̀, oókan àyà rẹ sì wà níbẹ̀; àti bákannáà ìwọ jẹ́ olódodo; ìwọ jẹ́ aláànú àti onínu rere títí láé;

31 Ìwọ sì ti mú Síónì sí oókan àya tìrẹ, láti inú gbogbo àwọn ẹ̀dá rẹ, láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé; kò sì sí ohun míràn ṣùgbọ́n àlãfíà, òdodo, àti òtítọ́ ni ibùgbé ìtẹ́ rẹ; àánú yíò sì lọ níwájú rẹ kì yíò sì ní òpin; báwo ni ó ṣe jẹ́ tí iwọ fi lè sunkún?

32 Olúwa sì wí fún Énọ́kù: Kíyèsí àwọn arákùnrin rẹ wọ̀nyí; wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ mi, èmi sì fi ìmọ̀ tiwọn fún wọn, ní ọjọ́ tí èmi dá wọn; àti nínú Ọgbà Édẹ́nì, ni èmi ti fún ènìyàn ní òmìnira rẹ̀ láti yàn;

33 Àti fún àwọn arakùnrin rẹ ní èmi ti wí, àti bákannáà mo fún wọn ní òfin, pé kí wọ́n ó fẹ́ràn ara wọn, àti pé kí wọ́n kí ó yàn èmi, Bàbá wọn; ṣùgbọ́n kíyèsíi, wọ́n wà ní àìnífẹ̃, wọ́n sì koríra ẹ̀jẹ̀ ti ara wọn;

34 Iná ìrúnú mi ti rú sókè sí wọ́n; àti nínú gbígbóná àìdunnú mi ni èmi yíò rán ìkún omi sí orí wọn, nítorí gbígbóná ìbínú mi ti ru sókè sí wọ́n.

35 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; Ẹni Mímọ́ ni orúkọ mi; Ẹni Ìmọ̀ràn ni orúkọ mi; Àìlópin àti Ayérayé sì ni orúkọ mi, pẹ̀lú.

36 Nítorínáà, èmi lè na ọwọ́ mi jade kí èmi sì di gbogbo àwọn ẹ̀dá èyítí mo ti dá mú; ojú mi sì lè wọ inú wọn lọ pẹ̀lú, àti lààrin gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi kò tíì sí ìwà búburú púpọ̀ tó bẹ́ẹ bíi ti ààrin àwọn arákùnrin rẹ.

37 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn yíò wà ní orí àwọn bàbá wọn; Sátánì yíò jẹ́ bàbá wọn, àti òṣì ni yíò jẹ́ ìparun wọn; gbogbo àwọn ọ̀run ni yíò sì sunkún ní orí wọn, àní gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi; nítorí kínni àwọn ọ̀run kì yíó ha sunkún, ní rírí pé àwọn wọ̀nyí yíò jìyà?

38 Ṣùgbọ́n kíyèsíi, ìwọ̀nyí tí ojú rẹ nwò yíò parun nínú àwọn ìkún omi; sì kíyèsíi, èmi yíò sé wọn mọ́; túbú kan ni èmi ti pèsè fún wọn.

39 Àti èyíinì tí èmi ti yàn ti bẹ̀bẹ̀ ní iwájú mi. Nítorínáà, òun jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; níwọ̀nbí wọn bá ronúpìwàdà ní ọjọ́ náà tí Àyànfẹ́ mi yíò padà sí ọ̀dọ̀ mi, àti títí di ọjọ́ náà wọn yíò wà nínú oró;

40 Nítorínáà, fún èyí ni àwọn ọ̀run yíò ṣe sunkún, bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi.

41 Ó sì ṣe tí Olúwa bá Énọ́kù sọ̀rọ̀, ó sì sọ gbogbo àwọn ìṣe àwọn ọmọ ènìyàn fún Énọ́kù; nítorínáà Énọ́kù mọ̀, òun sì wo ìwà búburú wọn, àti òṣì wọn, ó sì sunkún ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ọkàn rẹ̀ sì wú ní títóbi bíi ayérayé; inú rẹ̀ sì yọ́; gbogbo ayérayé sì mì tìtì.

42 Énọ́kù sì rí Nóà bákannáà, àti ẹbí rẹ̀; pé kí àtẹ̀lé ti gbogbo àwọn ọmọkùnrin Nóà ó lè di gbígbalà pẹ̀lú ìgbàlà ti ara;

43 Nísisìyí Énọ́kù ríi pé Nóà kan ọkọ̀ kan; àti pé Olúwa yọ́nú síi, tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n sí orí ìyókù àwọn ènìyàn búburú ni àwọn ìkún omi dé tí ó sì gbe wọn mì.

44 Bí Énọ́kù sì ṣe rí èyí, ó ní ìkorò ọkàn, ó sì sunkún ní orí àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún àwọn ọ̀run: Èmi yíò kọ̀ láti jẹ́ títùnínú; ṣùgbọ́n Olúwa wí fún Énọ́kù: Gbe ọkàn rẹ sókè, kí o sì yọ̀; sì wò.

45 Ó sì ṣe tí Énọ́kù wò; àti láti orí Nóà, òun rí gbogbo àwọn ìdílé ti ilẹ̀ ayé; ó sì kígbe sí Olúwa wípé: Nígbàwo ni ọjọ́ Olúwa yíò dé? Nígbàwo ni a ó ta ẹ̀jẹ̀ Olódodo sílẹ̀, tí gbogbo àwọn tí wọ́n nṣọ̀fọ̀ yíó lè jẹ́ yíyàsímímọ́ àti tí wọn yíó ní ìyè ayérayé?

46 Olúwa sì wípé: Yíò jẹ́ ààrin méjì àkókò, ní àwọn ọjọ́ ìwà búburú àti ẹ̀san.

47 Sì kíyèsíi, Énọ́kù rí ọjọ́ bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, àní nínú ẹran ara; ọkàn rẹ̀ sì yọ̀, wípé: A gbé Olódodo sókè, Ọ̀dọ́-àgùtàn náà ni a sì pa láti ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé; àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ èmi wà ní oókan àyà Bàbá, sì kíyèsíi, Síónì wà pẹ̀lú mi.

48 Ó sì ṣe tí Énọ́kù wo orí ilẹ̀ ayé; ó sì gbọ́ ohùn kan láti àwọn inú ibẹ̀, wípé: Ègbé, ègbé ni èmi, ìyá àwọn ènìyàn; èmi ní ìrora, èmi kãrẹ̀, nítorí ìwà búburú àwọn ọmọ mi. Nígbàwo ni èmi yíò sìnmi, àti tí èmi ó di wíwẹ̀mọ́ kúrò nínú ìwà ẹ̀gbin èyítí ó ti jade wá lati inú mi? Nígbà wo ni Ẹlẹ́dàá mi yíò yà mí sí mímọ́, kí èmi ó lè sinmi, àti kí òdodo gbé fún ìgbà kan ní ojú mi?

49 Nígbàtí Énọ́kù sì gbọ́ tí ilẹ̀ ayé nṣọ̀fọ̀, ó sunkún, ó sì ké pe Olúwa, wípé: Olúwa, ìwọ kì yíò ha yọ́nú sí ilẹ̀ ayé? Ìwọ kì yíò ha sure fún àwọn ọmọ Nóà?

50 Ó sì ṣe tí Énọ́kù tẹ̀síwájú nínú igbe rẹ̀ sí Olúwa, wípe: Èmi béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa, ní orúkọ Ọmọ Bíbí rẹ Kanṣoṣo, àní Jésù Krístì, pé kí ìwọ kí ó ṣe àánú fún Nóà àti irú ọmọ rẹ̀, pé kí àwọn ìkún omi má lè bo orí ilẹ̀ ayé mọ́ láé.

51 Olúwa kò sì lè dáa dúró; òun sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú Énọ́kù, ó sì búra fún un pẹ̀lú ìbúra kan, pé òun yíò dá àwọn ìkún omi dúró, pé òun yíò ké pe àwọn ọmọ Nóà;

52 Ó sì fi àṣẹ kan ránṣẹ́ tí a kò le yípadà, pé ìyókù irú ọmọ rẹ̀ kan ni a ó máa rí ní gbogbo ìgbà lààrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, nígbàtí ilẹ̀ ayé bá sì dúró;

53 Olúwa sì wípé: Ìbùkún ni fún ẹni náà nípasẹ̀ irú ọmọ ẹnití Mèssíà yíò wá; nítorí ó wí pé—Èmi ni Mèssíà, Ọba Síónì, Àpáta Ọ̀run, èyítí ó gbòòrò bí ayérayé; ẹnikẹ́ni tí ó bá wọlé láti ẹnu ọ̀nà tí ó sì gun òkè nípasẹ̀ mi kì yíò ṣubú láé; nítorínáà, ìbùkún ni fún àwọn ẹnití èmi ti sọ̀rọ̀ nípa wọn, nítorí wọn yíò jáde wá pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin.

54 Ó sì ṣe tí Énọ́kù sì ké pe Olúwa wípé: Nígbàtí Ọmọ Ènìyàn bá dé nínú ẹran ara, njẹ́ ilẹ̀ ayé yíò sìnmi bí? Mo bẹ̀ ọ́, fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn mí.

55 Olúwa sì wí fún Énọ́kù: wò, òun sì wò ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí a gbé sókè ní orí àgbélẽbũ, bíi ìṣe àwọn ènìyàn;

56 Ó sì gbọ́ ohùn rara kan; a sì bo àwọn ọ̀run; gbogbo àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run sì ṣọ̀fọ̀; ilẹ̀ ayé sì kérora; àwọn àpáta sì fà ya; àwọn ènìyàn mímọ́ sì dìde, a sì dé wọn ní ade ní ọwọ́ ọ̀tún Ọmọ Ènìyàn, pẹ̀lú àwọn adé ògo;

57 Iye àwọn ẹ̀mí tí wọ́n sì wà nínú túbú ni wọ́n jade wá, wọ́n sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; àwọn ìyókù ni à sì fipamọ́ sínú àwọn ẹ̀wọ̀n òkùnkùn títí di ìdájọ́ ti ọjọ́ nla náà.

58 Àti lẹ́ẹ̀kansíi Énọ́kù sunkún ó sì ké pe Olúwa, wípé: Nígbàwo ni ayé yíò simi?

59 Énọ́kù sì rí Ọmọ Ènìyàn tí ó gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá; ó sì ké pe Olúwa, wípé: Ìwọ kì yíò ha wá lẹ́ẹ̀kansíi sí orí ilẹ̀ ayé? Nítorí níwọ̀nbí ìwọ ti jẹ́ Ọlọ́run, tí èmi sì mọ̀ ọ́, ìwọ sì ti búra fún mi, o sì ti pàṣẹ fún mi pé kí èmi ó béèrè ní orúkọ Ọmọ Bíbí rẹ Kanṣoṣo; ìwọ ti dá mi, o sì ti fún mi ní ẹ̀tọ́ sí ìtẹ́ rẹ, kìí sìí ṣe ní ti ara mi, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ tìrẹ; nítorínáà, èmi béèrè lọ́wọ́ rẹ bí ìwọ kì yíò bá wá lẹ́ẹ̀kansíi sí orí ilẹ̀ ayé.

60 Olúwa sì wí fún Énọ́kù: Bí èmi ṣe wà, àní bẹ́ẹ̀ni èmi yíò wá ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, ní àwọn ọjọ́ ti ìwà búburú àti ẹ̀san, láti mú ìbúra ṣẹ èyítí èmi ti ṣe fún ọ nípa àwọn ọmọ Nóà;

61 Ọjọ́ náà yíò sì dé tí ayé yíò sinmi, ṣùgbọ́n ṣaájú ọjọ́ náà àwọn ọ̀run ni a ó mú ṣókùnkùn, ìbòjú ti òkùnkùn yíò sì bo ilẹ̀ ayé; àwọn ọ̀run yíò sì mì tìtì, àti ilẹ̀ ayé pẹ̀lú; àwọn ìpọ́njú nlá yíò sì wà lààrin àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ni èmi yíò pamọ́;

62 Òdodo ni èmi yíò sì rán sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run; àti òtítọ́ ni èmi yíò rán jade lọ láti ilẹ̀ ayé, láti jẹ́rìí Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo; àjínde rẹ̀ láti ipò òkú; bẹ́ẹ̀ni, àti àjínde ti gbogbo ènìyàn bákannáà; àti òdodo àti òtítọ́ ni èmi yíò mú kí wọn ó gbá ilẹ̀ ayé bí ìkún omi, láti kó àwọn àyànfẹ́ mi jọ pọ̀ jade láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, sí ibìkan tí èmi yíò pèsè, Ìlú nlá Mímọ́ kan, kí àwọn ènìyàn mi ó lè di àmùrè wọn, kí wọ́n ó sì máa fi ojú sọ́nà fún ìgbà bíbọ̀ mi; nítorí níbẹ̀ ni àgọ́ mi yíò wà, èyí ni a ó sì pè ní Síónì, Jérúsálẹ́mù Titun kan.

63 Olúwa sì wí fún Énọ́kù: Nígbànáà ni ìwọ àti gbogbo ilú nlá rẹ yíò pàdé wọn níbẹ̀, a ó sì gbà wọ́n sí oókan àyà wa, wọn yíò sì rí wa; a ó sì dì mọ́ wọn ní ọrùn, àwọn ó sì dì mọ́ wa ní ọrùn, a ó sì fi ẹnu ko ara wa lẹ́nu;

64 Ibẹ̀ ni yíò sì jẹ́ ibùgbé mi, yío sì jẹ́ Síónì, èyítí yíò jade wá láti inú gbogbo àwọn ẹ̀dá tí èmi ti dá; àti fún àlàfo ẹgbẹ̀rún ọdún, ilẹ̀ ayé yíò sinmi.

65 Ó sì ṣe tí Énọ́kù rí ọjọ́ bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, láti gbé ní orí ilẹ̀ ayé nínú òdodo fún àlàfo ẹgbẹ̀rún ọdún;

66 Ṣùgbọ́n saájú ọjọ́ náà òun rí àwọn ìpọ́njú púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn búburú; ó sì rí òkun bákannáà, pé a dà á láàmú, tí àyà àwọn ènìyàn sì njá wọn kulẹ̀, tí wọ́n nfojú sọ́nà pẹ̀lú ìbẹ̀rù nítorí àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, èyítí yíò wá sí orí àwọn ènìyàn búburú.

67 Olúwa sì fi ohun gbogbo hàn Énọ́kù, àní títí dé òpin ayé; òun sì rí ọjọ́ ti àwọn olódodo, wákàtí ti ìràpadà wọn, òun sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀;

68 Gbogbo àwọn ọjọ́ Síónì, ní àwọn ọjọ́ ti Énọ́kù, sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́ta àti ọgọ́ta ọdún ó lé márũn.

69 Énọ́kù àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sì rìn pẹ̀lú Ọlọ́run, òun sì gbé ní ààrin Síónì; ó sì ṣe tí Síónì kò sì sí mọ́, nítorí Ọlọ́run gbà á sí òkè sínú õkan àyà ara rẹ̀; láti ibẹ̀ lọ ni ọ̀rọ̀ sísọ náà ti jade lọ wipe, Síónì Ti Sa Lo.