Orí 5
(Oṣù Kẹfà–Oṣù Kẹwã 1830)
Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ—Ádámù rú ẹbọ ó sì sin Ọlọ́run—A bí Káínì àti Ábẹ́lì—Káínì ṣe ọ̀tẹ̀, ó fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ, ó sì di Ègbé—Ìpànìyàn àti ìwa búburú tànká—Ìhìnrere ni a wàásù láti àtètèkọ́ṣe.
1 Ó sì ṣe wipe lẹ́hìn tí èmi, Olúwa Ọlọ́run, lé wọn jade, tí Ádámù bẹ̀rẹ̀ sí ro ilẹ̀, àti láti jọba lórì gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́, àti láti jẹ oúnjẹ rẹ̀ nípasẹ̀ òógùn ojú rẹ̀, bí èmi Olúwa ṣe pàṣẹ fún un. Àti tí Éfà, bákannáà, ìyàwó rẹ̀, ṣe lãlã pẹ̀lú rẹ̀.
2 Ádámù sì mọ ìyàwó rẹ̀, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin fún un, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bí síi àti láti gbilẹ̀ ní ayé.
3 Àti láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Ádámù bẹ̀rẹ̀sí pín ní méjì méjì ní ilẹ̀ náà, àti láti ro ilẹ̀, àti láti tọ́jú àwọn ọ̀wọ́ ẹran, àwọn pẹ̀lú sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.
4 Ádámù àti Éfà, ìyàwó rẹ̀, sì ké pe orúkọ Olúwa, wọ́n sì gbọ́ ohùn Olúwa láti ìhà ọ̀nà Ọgbà Édẹ́nì, tí ó nbá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò sì rí i; nítorí a ti yà wọn nipa kúrò ní iwájú rẹ̀.
5 Òun sì fún wọn ní àwọn òfin, pé wọn yíò sin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọn yíò sì rú ẹbọ àkọ́bí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn, fún ẹbọ-ọrẹ kan sí Olúwa. Ádámù sì ṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa.
6 Àti lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ángẹ́lì Olúwa kan farahàn sí Ádámù, tí ó wípé: Nítorí kínni ìwọ ṣe nrú àwọn ẹbọ sí Olúwa? Ádámù sì wí fún un pé: Èmi kò mọ̀, bíkòṣe pé Olúwa pàṣẹ fún mi.
7 Àti nígbànáà ni ángẹ́lì náà sọ̀rọ̀, wípé: Nkan yìí jẹ́ àfiwé ìrúbọ ti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Bàbá, èyítí ó kún fún ore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
8 Nítorínáà, ìwọ yíò ṣe ohun gbogbo tí o bá ṣe ní orúkọ Ọmọ, ìwọ yíò sì ronúpìwàdà ìwọ yío sì ké pe Ọlọ́run ní orúkọ Ọmọ náà títí láé.
9 Àti ní ọjọ́ náà Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé Ádámù, èyítí ó jẹ́rìí Bàbá àti Ọmọ, wípé: èmi ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Bàbá láti àtètèkọ́ṣe, nísisìyí lọ àti títí láé, pé bí ìwọ ṣe ṣubú kí á lè rà ọ́ padà, àti gbogbo aráyé, àní iye àwọn tí ó bá fẹ́.
10 Àti ní ọjọ́ náà Ádámù fi ìbùkún fún Ọlọ́run ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀sí sọtẹ́lẹ̀ nípa gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ ayé, wípé: Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run, nítorí fún ti ẹ̀ṣẹ̀ mi ni a ṣe la ojú mi, ní ayé yìí èmi yíò sì ní ayọ̀, àti lẹ́ẹ̀kansíi nínú ẹran ara èmi yíò rí Ọlọ́run.
11 Éfà, ìyàwó rẹ̀, sì gbọ gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí inú rẹ̀ sì dùn, ó wípé: Bí kò bá jẹ́ ti ìrékọjá wa, àwa ìbá tí lè ní irú ọmọ láé, àwa kì bá má sì mọ rere àti búburú, àti ayọ̀ ìràpadà wa, àti ìyè ayérayé náà èyítí Ọlọ́run fi fún gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ràn.
12 Ádámù àti Éfà sì fi ìbùkún fún orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn.
13 Sátánì sì wá sí ààrin wọn, ó nwípé: Èmi pẹ̀lú jẹ́ ọmọ Ọlọ́run; ó sì paṣẹ fún wọn, ó wípé: Ẹ máṣe gba á gbọ́; wọ́n kò sì gbà á gbọ́, wọ́n sì fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà náà lọ láti jẹ́ ti ayé, ti ara, àti ti èṣù.
14 Olúwa Ọlọ́run sì pe àwọn ènìyàn nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ní ibi gbogbo Ó sì paṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ó ronúpìwàdà;
15 Iye àwọn tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọmọ, tí wọ́n sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yíò di gbígbàlà; àti pé iye àwọn tí kò bá gbàgbọ́ tí wọn kò sì ronúpìwàdà, yíò di ẹni ègbé; àwọn ọ̀rọ̀ náà sì jade lọ láti ẹnu Ọlọ́run ní àṣẹ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀; nítorínáà wọ́n gbọ́dọ̀ di mímúṣẹ.
16 Ádámù àti Éfà, ìyàwó rẹ̀, kò sì dúró ní kíké pe Ọlọ́run. Ádámù sì mọ Éfà ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí Káínì, ó wípé: Èmi ti gba ọmọkùnrin láti ọwọ́ Olúwa; nítorínáà òun lè má kọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsíi, Káínì kò fetísílẹ̀, ó wípé: Taani Olúwa náà ti èmi yíò fi mọ̀ ọ́?
17 Òun sì tún lóyún lẹ́ẹ̀kansíi ó sì bí arákùnrin rẹ̀ Ábẹ́lì. Ábẹ́lì sì fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa. Ábẹ́lì sì jẹ́ olùsọ́ àgùtàn, ṣùgbọ́n Káínì jẹ́ agbẹ̀.
18 Káínì sì fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ. Sátánì sì pàṣẹ̀ fún un, wípé: Rú ẹbọ sí Olúwa.
19 Àti bí àkókò ṣe nlọ ó sì ṣe tí Káínì mú ẹbọ-ọrẹ kan wá fún Olúwa lára èsò inú ilẹ̀.
20 Àti Ábẹ́lì, òun pẹ̀lú mú lára àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹ̀ran rẹ̀, àti ọlọ́ràá nínú wọn. Olúwa sì ní inú dídùn sí Ábẹ́lì, àti sí ẹbọ-ọrẹ rẹ̀;
21 Ṣùgbọ́n sí Káínì, àti sí ẹbọ-ọrẹ rẹ̀, òun kò ní inú dídùn. Nísisìyí Sátánì sì mọ èyí, ó sì dùn mọ́ ọ nínú. Inú sì bí Káínì púpọ̀, ojú rẹ̀ sì fà ro.
22 Olúwa sì wí fún Káínì: Nítorí kínni ìwọ ṣe nbínú? Nítorí kíni ojú rẹ ṣe fà ro?
23 Bí ìwọ bá ṣe dáradára, ìwọ yíò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Bí ìwọ̀ kò bá sì ṣe dáradára, ẹ̀ṣẹ̀ dúró sí ẹnu ọ̀nà rẹ, Sátánì sì nfẹ́ láti mú ọ́; bíkòṣe pé ìwọ sì fetísílẹ̀ sí àwọn òfin mi, èmi yíò fi ọ́ lé e lọ́wọ́, yíò sì rí fún ọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ rẹ̀. Ìwọ yíò sì jọba ní orí rẹ̀;
24 Nítorí láti àkókò yìí lọ ìwọ yíò jẹ́ bàbá fún àwọn èké rẹ̀; ìwọ ni a ó pè ní Ègbé; nítorí ìwọ ti wà pẹ̀lú ṣaájú ayé.
25 A ó sì wí ní ọjọ́ iwájú—Pé àwọn ohun ìríra wọ̀nyí ni a gbà láti ọwọ́ Káínì; nítorí òun kọ̀ ìmọ̀ràn títóbijù èyítí a gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; èyí sì ni ègún kan èyítí èmi yíò fi sí orí rẹ, bíkòṣe pé ìwọ ronúpìwàdà.
26 Káínì sì bínú, òun kò sì tẹ́tí sí ohùn Olúwa mọ́, tàbí sí Ábẹ́lì, arákùnrin rẹ̀, ẹnití ó rìn ní mímọ́ níwájú Olúwa.
27 Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀ níwájú Olúwa, nítorí Káínì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.
28 O sì ṣe tí Káínì mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ ṣe ìyàwó, wọ́n sì fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ.
29 Sátánì sì wí fún Káínì: Búra fún mi nípa ọ̀nà ọ̀fun rẹ, àti bí ìwọ bá sọ ọ́ ìwọ yíò kú; sì jẹ́kí àwọn arákùnrin rẹ búra nípa orí wọn, àti nípa Ọlọ́run alàyè, pé wọn kì yíò sọ ọ́; nítorí bí wọ́n bá sọ ọ́, wọn yíò kú dájúdájú; àti èyí pé kí bàbá yín kí ó má lè mọ̀ ọ́; ní òní yìí ni èmi yíò sì fi arákùnrin rẹ Ábẹ́lì lé ọ lọ́wọ́.
30 Sátánì sì búra fún Káínì pé òun yíò ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn àṣẹ rẹ̀. Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni wọ́n sì ṣe ní ìkọ̀kọ̀.
31 Káínì sì wípé: Lõtọ́ èmi ni Máhanì, ọ̀gá ti ìkọ̀kọ̀ nlá yìí, pé kí èmi kí ó lè pànìyàn kí nsì gba èrè. Nítorínáà Káínì ni a pè ní Ọ̀gá Máhanì, òun sì ṣògo nínú ìwà búburú rẹ̀.
32 Káínì sì lọ sínú oko, Káínì sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ábẹ́lì, arákùnrin rẹ̀. O sì ṣe pé nígbàtí wọ́n wà ní oko, Káínì dìde sí Ábẹ́lì, arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.
33 Káínì sì ṣògo nínú èyíinì tí ó ṣe, wípé: Mo di òmìnira; dájúdájú àwọn agbo ẹran arákùnrin mi ti bọ́ sí ọwọ́ mi.
34 Olúwa sì wí fún Káínì: Níbo ni Ábẹ́lì, arákùnrin rẹ wà? Ó sì wipe: Èmi kò mọ̀. Èmi há í ṣe olùpamọ́ arákùnrin mi bí?
35 Olúwa sì wípé: Kínni ìwọ ṣe yìí? Ohùn ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ nké pè mi láti inú ilẹ̀.
36 Àti nísisìyí ìwọ yíò di ẹni ìfibú ní orí ilẹ̀ náà èyítí ó ti la ẹnu rẹ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ láti ọwọ́ rẹ.
37 Nígbàtí ìwọ bá sì ro ilẹ̀ òun kì yíò so ẹ̀kún agbára rẹ̀ fún ọ láti ìsisìyí lọ. Ìsánsá àti alárìnkiri ni ìwọ yíò jẹ́ ní ilẹ̀ ayé.
38 Káínì sì wí fún Olúwa: Sátánì dán mi wò nítorí àwọn agbo ẹran arákùnrin mi. Èmi náà sì bínú bákannáà; nítorí ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ni ìwọ tẹ́wọ́gbà àti pé kìí ṣe tèmi; ìjìyà mi pọ̀ ju ohun tí mo lè faradà lọ.
39 Kíyèsíi ìwọ ti lé mi jade ní òní yìí kúrò ni ojú Olúwa, àti kúrò ní ojú rẹ ni èmi yíò jẹ́ fífipamọ́; èmi yíò sì di ìsánsá àti alárìnkiri ní ilẹ̀ ayé; yíò sì ṣe, pé ẹni tí ó bá rí mi yíò pa mí, nítorí àwọn àìṣedédé mi, nítorí àwọn ohun wọ̀nyí kò pamọ́ sí Olúwa.
40 Èmi Olúwa sì wí fún un: Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ọ́, a ó gbẹ̀san ní orí rẹ̀ ní ìlọ́po méje. Èmi Olúwa sì fi àmì sí orí Káínì, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i yíó pá á.
41 A sì mú Káínì kúrò níwájú Olúwa, àti pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ ni wọ́n gbé ní ilẹ̀ Nọ́dì, ní ìhà ìlà oòrùn Édẹ́nì.
42 Káínì sì mọ ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí Énọ́kù, bákannáà òun sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sì kọ́ ìlú nlá kan, ó sì pe orúkọ ìlú nlá náà tẹ̀lé orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀, Énọ́kù.
43 Àti fún Énọ́kù ni a bí Íradì, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin míràn. Írádì sì bí Mahujáẹ́lì, ati àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin míràn. Mahujáẹ́lì sì bí Mẹ̀túṣáẹ́lì, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin míràn. Mẹ̀túsáẹ́lì sì bí Lámẹ́kì.
44 Lámẹkì sì fẹ́ ìyàwó méjì fún ara rẹ̀; orúkọ ọ̀kan ni í ṣe Adá, àti orúkọ èkejì, Síllà.
45 Adá sì bí Jabálì; òun ni bàbá irú àwọn tí ngbé nínú àwọn àgọ́, wọ́n sì jẹ́ olùpamọ́ ẹran ọ̀sìn; orúkọ arákùnrin rẹ̀ sì ni Júbálì, ẹnití í ṣe bàbá gbogbo irú àwọn tí ó nlo hárpù àti dùrù.
46 Àti Síllà, òun pẹ̀lú bí Tubali Káínì, olùkọ́ni ti olúkúlùkù oníṣọ̀nà nínú idẹ àti irin. Àti arábìnrin Tubàli Káínì ni a pè ní Náámà.
47 Lámẹ́kì sì wí fún àwọn ìyàwó rẹ̀, Adá àti Síllà: Ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin ìyàwó Lámẹ́kì, ẹ fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi; nítorí èmi ti pa ọkùnrin kan sí ìfarapa mi, àti ọ̀dọ́mọkùnrin kan sí ìpalára mi.
48 Bí a ó bá gbẹ̀san Káínì ní ìlọ́po méje, lõtọ́ ti Lámẹ́kì yíò jẹ́ ìlọ́po ní ọ̀nà àádọ́rin àti méje;
49 Nítorí Lámẹ́kì tí ó ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Sátánì, gẹ́gẹ́ bí ti Káínì, nípa èyítí òun di Ọ̀gá Máhánì, ọ̀gá ti ìkọ̀kọ̀ nlá èyítí a ti fi fún Káínì láti ọwọ́ Sátánì; àti Iradì, ọmọ Énọ́kù, nítorí tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ wọn, bẹ̀rẹ̀sí fi hàn sí àwọn ọmọkùnrin Ádámù;
50 Nítorí èyí Lámẹ́kì, bínú, ó sì pa á, kìí ṣe bíi ti Káínì, sí arákùnrin rẹ̀ Ábẹ́lì, nítorí ìdí gbígba èrè, ṣùgbọ́n òun pa á nítorí ìbúra.
51 Nítorí, láti àwọn ọjọ́ Káínì, ẹgbẹ́ ìkọ̀kọ̀ wà, àwọn iṣẹ́ wọn sì wà nínú òkùnkùn, wọ́n sì mọ olúkúlùkù ènìyàn mọ arákùnrin rẹ̀.
52 Nítorínáà Olúwa fi Lámẹ́kì bú, àti ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọ́n ti ó ti dá májẹ́mú pẹ̀lú Sátánì; nítorí wọn kò pa àwọn òfin ti Ọlọ́run mọ́, èyí sì bí Ọlọ́run nínú, òun kò sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn, àwọn iṣẹ́ wọn sì jẹ́ ohun ìríra, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tankálẹ̀ lààrin gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn. Ó sì wà ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn.
53 Àti ní ààrin àwọn ọmọbìnrin ènìyàn a kò sọ irú àwọn nkan wọ̀nyí, nítorítí Lámẹ́kì ti sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ sí àwọn ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i, wọ́n sì kéde àwọn nkan wọ̀nyí káàkiri, wọn kò sì ní ìyọ́nú;
54 Nítorínáà a fi Lámẹ́kì ṣẹ̀sín, a sì lé e jade, kò sì wá sí ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, bíbẹ́ẹ̀kọ́ òun yíò kú.
55 Báyìí sì ni àwọn iṣẹ́ òkùnkùn bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀ lààrin gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn.
56 Ọlọ́run sì fi ilẹ̀ bú pẹ̀lú ìfibú kíkan, òun sì bínú sí àwọn ènìyàn búburú, sí àwọn ọmọ ènìyàn ẹnití òun ti dá;
57 Nítorí wọn kò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ̀, tàbí gbàgbọ́ nínú ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo, àní òun ẹnití ó ti kéde pé yíò wá ní ààrin méjì àkókò, ẹnití a ti pèsè sílẹ̀ ṣaájú ìpìlẹ̀ ayé.
58 Báyìí sì ni a bẹ̀rẹ̀sí wàásù Ìhìnrere, láti àtètèkọ́ṣe, tí ó jẹ́ kíkéde nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì mímọ́ tí a rán jade láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti nípa ohùn tirẹ̀, àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.
59 Báyìí ni a sì fi ẹsẹ̀ ohun gbogbo múlẹ̀ fún Ádámù, nípa ìlànà mímọ́ kan, Ìhìnrere sì di wíwàásù, àṣẹ kan di rírán jade, pé kí ó wà nínú ayé, títí di òpin rẹ̀; bẹ́ẹ̀ni ó sì rí. Àmín.