Ọdọ
Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ Wọn
Ààrẹ Monson sọ ìtàn kan nípa ẹbí olùlànà kan nígbà náà ó ṣe àtúsọ ọ̀rọ̀ Ààrẹ George Albert Smith: Njẹ́ ẹ̀yin ó gbé ìgbé ayé òtítọ́ sí ìgbàgbọ́ àwọn bàbáńlá yín? … Ẹ tiraka láti jẹ́ yíyẹ fún gbogbo ìrúbọ tí [wọ́n] ti ṣe fún yín. Bóyá ìwọ ní bàbáńlá olùlànà kan tàbí o jẹ́ ìran-kínní ọmọ Ìjọ, njẹ́ ò nbojú wo àwọn àpẹrẹ ìgbàgbọ́ fún ìtọ́sọ́nà àti okun? , Níhín ni ọ̀nà rere kan tí o fi lè bẹ̀rẹ̀:
1. Ṣe ètò orúkọ àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ràn lẹ́sẹẹsẹ. Wọn lè jẹ́ mọ̀lẹ́bí ti ẹbí ara rẹ (tí wọ́n ti kọjá tàbí tì ìsisìnyí), àwọn ọ̀rẹ́, àwọn Olóyè Ìjọ, tàbí àwọn ènìyàn nínú ìwé mímọ́.
2. Kọ àwọn ìwà tí wọ́n ní tí ó fẹ́ràn sílẹ̀. Njẹ́ ìyá rẹ ní sùúrù nítòótọ́? Bóyá ọ̀rẹ́ rẹ ní inúrere sí àwọn ẹlòmíràn. Bóyá ó nífẹ́ ìgboyà Ọ̀gágun Mórónì.
3. Mú ìwà kan láti inú orúkọ tí ó tò sílẹ̀ kí o sì bi ara rẹ léèrè pé Báwo ni mo ṣe lè jèrè ìwà yí? Kíni mo nílò láti ṣe láti mú irú èyí gbèrú nínú ayé mi?
4. Kọ àwọn ètò rẹ sílẹ̀ fún mímú ìwà yí gbèrú kí o sì fi sí ibìkan tí ìwọ yíò ti máa ri nígbàkugbà, láti rán ọ létí nípa ìfojúsí rẹ. Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run kí o sì bẹ ìlọsíwájú rẹ wò léraléra. Lẹ́ẹ̀kanáà tí ìwọ bá ti ní ìmọ̀lára pé o ti gbèrú tó nínú ìwà yí, o lè mú ìwà tuntun láti ṣiṣẹ́ lé lórí.
Rántí pé bí a ṣe nmú àwọn ìwà nlá gbèrú nínú ara wa, a kò bu olá fún ìgbàgbọ́ àwọn bàbáńlá wa àti àwọn ìrúbọ tí wọn ṣe nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà à lè jẹ́ ipá kan fún rere sí àwọn wọ̃nnì ní àyíka wa.