2016
Okun Wa fún Ipò Òbí
OṢù Agẹmọ 2016


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kéje Ọdún 2016

Okun Wa fún Ipò Òbí

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

“O ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run ní ìbí ayé ikú àti ànfàní láti tẹ̀síwájú lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun,” ni Alàgbà Dallin H. Oaks ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá kọ́ni. “Nínú ìmọ́lẹ̀ ti èrò ìgbẹ̀hìn ti ètò ìdùnnú nlá, mo gbàgbọ́ pé ìṣúra ìgbẹ̀hìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run ni àwọn ọmọ wa àti ìran àtẹ̀lé wa.”1

Alàgbà Neil L. Andersen ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá sọ pé:

“A gbàgbọ́ nínú àwọn ẹbí, a sì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọdé. …

“‘… Ọlọ́run sọ fún [Ádámù àti Éfà] , Ẹ máa bí síi, kí ẹ sì máa rẹ̀ síi, kí ẹ sì gbilẹ̀‘ [Genesis 1:28]. …

“Òfin yí kò di ìgbàgbé tàbí gbígbé sí ẹ̀gbẹ́ ní Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.”2

Bí o ti lẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe gbogbo wa ni a di òbí nínú ayé yìí, a lè ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ ní oníruurú ọjọ́ orí. A ngbádùn àwọn ìbùkún ti jíjẹ́ apákan ẹbí ti Bàbá Ọ̀run, àti pé à nní ìrìrí ayọ àti ìpèníjà ti jíjẹ́ apákan ẹbí ti ayé. Àti péfún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ipò òbí ndúró dè wọ́n nínú ayé àìnípẹ̀kún níwájú.

Àfikún ÀwọnÌwé Mímọ

Ìwé Orin Dáfidì 127:3; Máttéù 18:3–5; 1 Nífáì 7:1; Mósè 5:2–3

Àwọn Ìtàn Alààyè

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohùn ní àgbáyé lode òní nṣe ìrẹsílẹ̀ bí níní àwọn ọmọ ṣe ṣe pàtàkì tó tàbí dá àbá ṣíṣe ìdádúró tàbí dídín àwọn ọmọ níní nínú ẹbí kù, ni Alàgbà Andersen sọ. Láìpẹ́ àwọn ọmọbìnrin mi darí mi sí búlọ́ọ̀gì (fèrèsé ayélujára) kan tí a kọ láti ọwọ́ onígbàgbọ́ ìyá kan (kìí ṣe ìgbàgbọ́ tiwa) pẹ̀lú àwọn ọmọ maarún Ó sọ àsọyé: [Dídàgbà] sókè nínú àṣà yí, ó le gidi láti rí èrò bibélì gbà lórí ipò ìyá. … Àwọn ọmọdé dọ́gbá ni kíkéré ju kọ́lẹ́jì. Kéréju ìrìnàjò àgbáyé dájú. Kéréju agbára láti jade lọ síta lálẹ́ ní ìtura rẹ. Kéréju títún ara rẹ ṣe ní ilé ìdárayá. Kéréju iṣẹ́ kankan tí o lè ní tàbí ní ìrètí láti rí. Nígbànáà ó ṣe àfikún pé: ‘Ipò ìyá kìí ṣe ohun ìṣeré, ó jẹ́ ìpè. O kò gba àwọn ọmọ nítorí pé o rí wọ́n bí èyí tí ó jáfáfá ju àwọn òntẹ̀ lọ. Kìí ṣe ohun kan tí ó níláti ṣe tí ó bá lè rún àkokò mọ́ra. Ó jẹ́ ohun tí Ọlọ́run fún ọ ni àkokò láti ṣe.’”3

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Dallin H. Oaks, “Ètò Ìdùnnú Nlá Náà,” Àsíá, Nov. 1993, 72, 75.

  2. Neil L. Andersen, “Àwọn Ọmọdé,” Amọ̀nà, Oṣù Kọkànlá. 2011.

  3. Neil L. Andersen, “Àwọn Ọmọdé,” 28.

Gbèrò Èyí

Ní àwọn ọ̀nà wo ni ẹbí wa ti ayé fi dàbí ẹbí wa ti ọ̀run?

Tẹ̀