Ọ̀RỌ̀ ÀJỌ ÁÁRE IKÌNNÌ, Oṣù Kéje Ọdún 2016
Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ ti àwọn Bàbá wa Ìṣaájú
John Linford jẹ́ ogójì ọdún ó lé mẹ́ta nígbàtí òun àti ìyàwó rẹ, Maria, àti pé mẹ́ta lára àwọn ọmọkùnrin rẹ pinnu láti kúrò nílé wọn ní Gravely, England, láti rin ìrìnàjò ẹgbẹgbẹ̀rún máìlì láti darapọ̀ mọ́ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àfonífojì ti Salt Lake Nlá. Wọ́n fi ọmọ wọn kẹ́rin sílẹ̀ lẹ́hìn, ẹnití ó nsìn ní míṣọ̀n, wọ́n ta àwọn ohun ìní wọn, wọ́n sì gba ọ̀nà Liverpool lọ sínú ọkọ ojú omi Thornton.
Ìrìn àjò náà ní orí òkun sí Ìlú Nlá New York, àti pé lẹ́hìnnáà ní orí ilẹ̀ sí Iowa, jẹ́ àíyánilára lásán. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn wàhálà bẹ̀rẹ̀, ní kété lẹ́hìn tí àwọn Linford àti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn míràn tí wọ́n ṣíkọ̀ lórí Thornton. kúrò ní Ìlú Nlá Iowa ní Ọjọ́ Kẹẹ̀dógún Oṣù Kéje, 1856, bíi apákan ọ̀wọ́ kẹ̀kẹ́ ẹrù ọlọ́wọ́ ti James G. Willie tí ó ní ìjàmbá.
Ojú ọjọ́ líle àti ìrìn àjò onínira gba ìpín tiwọn lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọ̀wọ́ náà, tí kò yọ John sílẹ̀. Nígbẹ̀hìn ó ṣe àárẹ̀ àti àìlera tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n níláti máa tìí nínú kẹ̀kẹ́ ẹrù ọlọ́wọ́ kan. Ní àsìkò tí ọ̀wọ́ náà dé Wyoming, ipò àìlera rẹ ti burú gidigidi. Ikọ̀ agbanilà kan láti Ìlú Nlá Salt Lake dé ní Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹ́wàá, ní wákàtí díẹ̀ lẹ́hìn tí ìrìn àjò ayé-ikú ti John parí. Òun ti kú ní kùtùkùtù àárọ́ náà nítòsí bèbè Odò Sweetwater.
Njẹ́ John kãnú pé òun ti ta ìtùnú àti ìrọ̀rùn fún àwọn ìtiraka, àìní, àti ìpọ́njú ti mímú ẹbí rẹ lọ sí Síónì?
Rárá, Màríà, ó sọ fún ìyàwó rẹ̀ láìpẹ́ ṣíwájú ikú rẹ. Inú mi dùn pé a wá. Èmi kò ní wà láyé láti dé Salt Lake, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin náà yíò débẹ̀, àti pé èmi kò kábámọ̀ gbogbo ohun tí a ti là kọjá bí àwọn ọmọkùnrin wa bá le dàgbà tí wọ́n sí ṣe ìtọ́jú àwọn ẹbí tiwọn ní Síónì.”1
Màríà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ parí ìrìnàjò wọn. Nígbàtí Màríà ṣe aláìsí ní bíi ọgbọ̀n ọdún lẹ́hìnáà, òun àti John fi ogun ti ìgbàgbọ́, ti iṣẹ́ ìsìn, ti ìfọkànsìn, àti ti ìrúbọ sílẹ̀.
Láti jẹ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ni láti jẹ́ olùlànà kan, nítorí ìtumọ̀ olùlànà ni ẹni tí ó lọ ṣíwájú láti tún ọ̀nà ṣe tàbí ṣí i sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀lé.”2 Àti pé láti jẹ́ olùlànà ni láti di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ìrúbọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kìí sọ pé kí àwọn ọmọ Ìjọ ó fi ilé wọn sílẹ̀ mọ́ láti rìn ìrìnàjò lọ sí Síónì, wọ́n gbọ́dọ̀ fìgbàkugbà fi àwọn ìwà àtijọ́ àtẹ̀hìnwá, àwọn àṣà tó ti pẹ́, àti àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n sílẹ̀. Àwọn kan ṣe ìpinnu onírora láti fi àwọn ọmọlẹ́bí wọn sílẹ̀ sẹ́hìn àwọn tí wọ́n tako wọ́n lati jẹ́ ọmọ Ìjọ. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhin ntẹ̀síwájú, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ , wọ́n ngbàdúrà pé kí àwọn iyebíye wọ̃nnì ṣì lè ní òye àti ìtẹ́wọ́gbà síbẹ̀síbẹ̀.
Ipá ọ̀nà olùlànà kò rọrùn, ṣùgbọ́n à ntẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ ti Olùlànà níkẹhìn—àní Olùgbàlà—ẹni tí ó lọ ṣíwájú, ti ó nfi ọ̀nà hàn wá láti tẹ̀lé.
“Wá, tẹ̀lé mi,”3 Ó peni.
“Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè,”4 Ó kéde.
“Wá sọ́dọ̀ mi,”5 Ó pè
Ọ̀nà náà lè ní ìgbìyànjú. Ó nira fún àwọn kan láti farada àwọn ọrọ yẹ̀yẹ́ àtí ìbàjẹ ti àwọn òmùgọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n máa npẹ̀gàn ìpa-ara-ẹni-mọ́, ìṣòtítọ, àti ìgbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọrun. Ṣùgbọn láé ní ayé kò ti ka pípa ẹ̀kọ́ ìpìlẹ mọ́ sí. Nígbàtí a pàṣẹ fún Nóà kí ó kọ ọkọ̀ ìgbàlà àwọn òmùgọ èrò wo ojú ọrun tí kò ní ìkùúkùú àti pé nígbà náà wọn ṣe yẹyẹ wọn sì pariwo—títí di ìgbà tí òjò náà dé.
Lórí ilẹ̀ àwọn Ará America ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ́ntúrì sẹ́hìn, àwọn ènìyàn ṣiyèméjì, jiyàn, wọ́n sì ṣe àìgbọràn títí tí iná fi pa Zarahẹ́mlà run, tí ilẹ̀ bo Moroníhàh, àti tí omi bo Mórónì mọ́lẹ̀. Ẹ̀fẹ̀ síṣe, yẹ̀yẹ́, àwàdà líle, àti ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́. Ìdákẹ́rọ́rọ́, òkùnkùn biribiri ti rọ́pò wọn. Sùúrù ti Ọlọ́run ti parí, àkokò ìlàsílẹ̀ Rẹ̀ ti wá sí ìmúṣẹ.
Màríà Linford kò sọ ìgbàgbọ́ rẹ nù láéláé pẹ̀lú àìka inúnibínú ní England sí, àwọn ìnira ti ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí ibi náà èyí tí Ọlọ́run … pèsè sílẹ̀,”6 àti àwọn àdánwò míràn tí ó faradà fún ẹbí rẹ̀ àti Ìjọ.
Níbí ayẹyẹ ẹ̀gbẹ́ ibojì kan ní 1937 tí a yà sọ́tọ̀ fún ìrántí Màríà, Alàgbà George Albert Smith (1870–1951) bèèrè lọ́wọ́ àwọn ìran àtẹ̀lé rẹ̀: Njẹ́ ẹ̀yin yíò gbé ní òtítọ́ sí ìgbàgbọ́ ti àwọn bàbá nlá yín? …Kí ẹ tiraka láti jẹ́ yíyẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ tí [wọ́n] ti ṣe fún yín.7
Bí a ṣe nlépa láti kọ́ Síónì nínú ọkàn wa, nínú ilé wa, nínú àdúgbò wa, àti nínú orílẹ̀ èdè wa, njẹ́ kí a rantí ìpinnu ìgboyà àti ìgbàgbọ́ bíbágbé ti àwọn wọ̃nnì tí ó fi ohun wọn gbogbo sílẹ̀ kí awa lè gbádùn àwọn ìbùkún ti ìmúpadpabọ̀sípò ìhìnrere, pẹ̀lú ìrètí àti ìlérí rẹ̀ nípasẹ̀ Ètùtù ti Jésù Krístì.
© 2016 by Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/16. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/16. Àyípadà Èdè ti Visiting Teaching Message, July 2016. Yoruba. 12867 779