Ọdọ
Sísin àwọn Ẹlòmíràn nínú Ìgbàgbọ́
Ààrẹ Uchtdorf sọ fún wa pé ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jọ rìnpẹ̀lú ìṣe.” Ní ìgbà tí ìgbàgbọ́ wa bá dì àjàgà pẹ̀lú ìṣe lemọ́lemọ́, ó ṣe àlàyé pé, ó nkún … ẹ̀mí wa pẹ̀lú àláfíà àti ìfẹ́. Pẹ̀lú ìlérí ìbùkún yí, a lè mú ìyàtọ̀ kan wá, a sì lè rí èyí nínú ìgbé ayé wa tí a bá wá àyè láti ṣe iṣẹ́ ìsìn tí ó kún fún ìgbàgbọ́. Ẹ lè gbàdúrà ní àràárọ́ láti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa fún ìrànlọ́wọ́ ní sísin àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹrẹ, ẹ bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ láti fi hàn yín ní ìgbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá nílò ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ilé kan tàbí ní ìgbàtí ọ̀rẹ́ kan bá nílò oríyìn. Nígbà náà, nígbà tí ẹ bá gba ìṣílétí, ẹ ṣe ìṣe lórí rẹ̀! Tí ẹ bá fi àwọn àdúrà wọ̀nyí àti iṣẹ́ ìsìn yí ṣe ìwà, ní ìgbà náà ìgbàgbọ́ yín,, iṣe lemọ́lemọ́ yíò bùkún ayé yín àti ayé àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Uchtdorf ṣe ìlérí pé a “lè yí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn ẹbí, orílẹ̀ èdè, àti àgbáyé padà.”