Àwọn Ọmọdé
Ìgbẹ́kẹ̀lé
Tiraka ìṣeré yí pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan. Ẹ ó níláti gbẹ́kẹ̀lé áti tẹ̀lé àwọn ìdarí wọn pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
Mú ẹ̀là ìwé mímọ́ kan kí o sì ya obirikiti kan lórí rẹ̀ tí ó dúró fún ìwò ojú kan. Pẹ̀lú bírò tàbí lẹ́ẹ̀dì kan ní ọwọ́ yín, ki ẹ di oju yín. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rẹ́ yín sọ fún yín ibi tí ẹ ó ya ojú, imú, ẹnu, àti irun sí ní orí ìwò ojú yí. Nígbànáà wò ó. Báwo ni ó ti yí padà sí? Ẹ lè kùn un nínú ìwò ojú náà kí ẹ sì ya òmíràn láti ṣeré lẹ́ẹ̀kansi!
Ní ìgbà míràn ó ṣòro láti tẹ̀lé àwọn ìdarí. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá tiraka láti tẹ̀lé Bàbá Ọ̀run nípa fífi etí sílẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́, Òun yíò ràn wá lọ́wọ́. A le gbẹ́kẹ̀lé E nígbàgbogbo.