2017
Àwọn Olódodo Yíò gbé nípa Ìgbàgbọ́
April 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, oṣù kẹ́rin ọdún 2017

Àwọn Olódodo Yíò gbé nípa Ìgbàgbọ́

Rabbi náà àti Oníṣẹ́ Ọṣẹ

Ìtàn àtijọ́ ti awọn Júù kan wà nípa o olùṣe ọṣẹ kan tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ní ọjọ́ kan bí ó ṣe nrìn pẹ̀lú rábbi kan, ó wípé, “Ohun kan wà tí èmi kò ní òye rẹ̀. A ti ní ẹ̀sìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ṣùgbọ́n gbogbo ibi tí ẹ bá wo ni ibi wà, ìbàjẹ́, àìṣòótọ́, àìṣòdodo, ìrora, ebi, àti ìwà ipá. Ó fi ara hàn pé ẹ̀sìn kò mú ayé dára sii rárá. Nítorínáà mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kíni ìwúlò rẹ̀?”

Rabbi náà kò fèsì fún ìgbà díẹ̀ ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú ní rírìn pẹ̀lú olùṣe ọṣẹ náà. Ní ìgbẹ̀hìn wọ́n dé ilẹ̀ ìṣeré kan níbití àwọn ọmọ, tí erupẹ̀ bò lára, ti nṣeré nínú ìdọ̀tí.

“Ohun kan wà tí èmi kò ní òye rẹ̀,” ni rabbi náà sọ. “Wo àwọn ọmọ wọ̃nnì. A ti ní ọṣẹ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ọmọ wọ̃nnì dọ̀tí. Kíni ìwúlò ọṣẹ?”

Olùṣe ọṣẹ náà dáhùn, “Ṣùgbọ́n rabbi, kò dára láti dá ọṣẹ lẹ́bi fún àwọn ọmọ dídọ̀tí wọ̀nyí. A niláti lo ọṣẹ ṣíwájú kí ó tó lè mú ìlò rẹ̀ jáde.”

Rabbi náà rẹ́ẹ̀rín ó sì wípé, “Déédé.”

Báwo Ni Kí A Ṣe Gbé Ìgbé Ayé?

Àpọ́stélì Páùlù, ní ṣíṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ wòlíì Májẹ̀mú Láéláé kan, ṣe àkópọ̀ ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ onígbàgbọ́ kan nígbàtí ó kọ pé, “Àwọn olódodo yíò gbé nípa ìgbàgbọ́” (Àwọn Ará Rómù 1:17).

Bóyá nínú gbólóhùn jẹ́jẹ́ yí a ní òye ìyàtọ̀ ní àárín ẹ̀sìn kan tí kò nípọn tí ó sì jẹ́ aláìlera ati ọ̀kan tí ó ní agbára láti yí àwọn ìgbé aye padà.

Ṣùgbọ́n láti ní òye ohun tí ó túmọ̀ sí láti gbé ìgbé ayé nípa ìgbàgbọ́, a gbọ́dọ̀ ní òye ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́.

Ìgbàgbọ́ ju gbígbàgbọ́ lọ. Ó jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run pátápátá ti ó jọ nrìn pẹ̀lú ìṣe.

O ju níní ìfẹ́ inú lọ.

O ju jíjóòkó sílẹ̀ lásán, mími orí wa, àti sísọ pé a faramọ. Nígbàtí a bá sọ pé “Àwọn olódodo yíò gbé nípa ìgbàgbọ́,” ó túmọ̀ sí pé à ngba ìtọ́sọ́nà àti ìdarí nípa ìgbàgbọ́ wa. À nṣe ìṣe ní ọ̀nà tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa—kìí ṣe lati inú ìgbọ́ran àìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n lati inú ìgbẹ́kẹlé araẹni àti ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run wa àti fún ọgbọ́n àìdíyelé tí Ó ti fihàn sí àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ìgbàgbọ́ gbọ́dọ̀ jọ rìn wá pẹ̀lú ìṣe; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kò ní ìyè (wo James 2:17). Kìí ṣe ìgbàgbọ́ rárá. Kò ní agbára láti yí ẹnìkọ̀ọ̀kan padà, kí a tó sọ pé gbogbo ayé.

Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti ìgbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lẹ́ aláànú Bàbá wọn Ọ̀run—àní ní ìgbà àìní ìdánilójú, àní ní ìgbà iyèméjì àti ìpọ́njú ní ìgbàtí wọ́n lè má ríran ní pípé tàbí ní òye kedere.

Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ nfi ìtara rìn ní ipá ọ̀nà ti ọmọ-ẹ̀hìn wọ́n sì nlàkàkà láti tẹ̀lé àpẹrẹ àyànfẹ́ Olùgbàlà wọn, Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ nwúni lórí, nítòótọ́ ó sì nmísí wa láti fi ọkàn wa sí ọ̀run kí a sì nawọ́ jáde pẹ̀lú aápọn, gbé ga, kí a sì bùkún àwọn arákùnrin wa.

Ẹ̀sìn láìsí ìṣe dàbí ọṣẹ tí ó dúró nínú àpótí. Ó lè ní ìwúlò tí ó yanilẹ́nu, ṣùgbọ́n ni òdodo ó ní agbára kékeré láti mú ìyàtọ́ kan wá títí tí yíò fi mú èrò lílò rẹ̀ ṣẹ. Ìhìnrere Jésu Krístì tí a múpadàbọ̀sípò jé ìhìnrere ti ìṣe. Ìjọ Jésù Krístì nkọ́ni ní ẹ̀sìn tòótọ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìrètí kan, ìgbàgbọ́, àti ìfẹ́ àìlábàwọ́n, pẹ̀lú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ọ̀nà ti ẹ̀mí àti ti ara.

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, ìyàwó mi, Harriet, àti èmi wà nínú ìrìnàjò ẹbí kan pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn ọmọ wa ní agbègbè Mediterranean. A bẹ àwọn àgọ́ rẹfugí díẹ̀ wò a sì pàdé pẹ̀lú àwọn ẹbí láti àwọn orílẹ̀ èdè àjàtúká-ogun. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin wa, wọ́n sí nílò ìrànlọ́wọ́ kíákíá. Ọkàn wa ní àfọwọ́tọ́ tó jinlẹ̀ nígbàtí a ní ìrírí tààrà nípa bí aápọn ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ìjọ wa ṣe nmú ìrànlọ́wọ́, ìdẹrùn, àti ìrètí wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará wa nínú àìní, láìka ẹ̀sìn, ẹ̀yà, tàbí ẹkọ́ wọn sí.

Ìgbàgbọ́ tí a bá dì ní àjàgà pẹ̀lú ìṣe lemọ́lemọ́ nkún ọkàn pẹ̀lú inúrere, inú pẹ̀lú ọgbọ́n àti níní òye, àti ẹ̀mí pẹ̀lú àláfíà àti ìfẹ́.

Ìgbàgbọ́ wa lè bùkún ó sì lè fún méjéèjì àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa àti àwa ní agbára lódodo.

Ìgbàgbọ́ wa lè kún inú ayé pẹ̀lú ìwàrere àti àláfíà.

Ìgbàgbọ́ wa lè yí ìríra padà sí ìfẹ́ àti àwọn ọ̀tá sí ọ̀rẹ́.

Àwọn olódodo, nígbànáà, ngbé nípa ìṣe nínú ìgbàgbọ́; wọ́n ngbé nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti rírìn ní ọ̀nà Rẹ̀.

Èyíinì sì ni irú ìgbàgbọ́ tí ó lè yí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn ẹbí, àwọn orílẹ̀ èdè, àti àgbayé padà,

Tẹ̀