2017
Ìbúra àti Májẹ̀mú Oyè-àlùfáà
April 2017


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, oṣù Kẹ́rin ọdún 2017

Ìbúra àti Májẹ̀mú Oyè-àlùfáà

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Relief Society seal

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

Bí àwa gẹ́gẹ́bí arábìnrin bá ṣe nní òye sí pé ìbúra àti májẹ̀mú ti oyèàlùfáà ní ìlò sí wá tìkara wa, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe gba àwọn ìbùkún àti ìlérí oyèàlùfáà mọ́ra sí.

Alàgbà M. Russell Ballard ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá wípé, “Gbogbo àwọn tí wọn ti dá májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Olúwa tí wọ́n sì bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì, ní ẹ̀tọ́ láti gba ìfihàn ara ẹni, láti jẹ́ alábùkún fún nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn àngẹ́lì, láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere, àti, ní ìgbẹ̀hìn, láti jùmọ̀ di ajogún pẹ̀lú Jésù Krístì sí gbogbo ohun ti Bàbá ní.”1

Àwọn ìbùkún àti ìlérí ti ìbúra àti májẹ̀mú oyè-àlùfáà wà fún méjèèjì àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin. Arábìnrin Sheri L. Dew, Olùdámọ̀ràn tẹ́lẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ gbogbogbò, wípé, “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oyè-àlùfáà tó wà nínú àwọn ìlànà tó ga jùlọ ní ilé Olúwa ni a lè gbà nípasẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin nìkan ní àpapọ̀.”2

Arábìnrin Linda K. Burton, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ti fúnni ní ìpè yí, “Mo pe yín láti kọ́ ìbúra àti májẹ̀mú oyè-àlùfáà sórí, èyí tí a lè rí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:33–44 Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣèlérí fún un yín pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò mú òye yín nípa oyè-àlùfáà gbòòrò si yío sì mísí yín àti pé yíò gbé yín ga ní àwọn ọ̀nà ìyanu.”3

Àwọn àṣẹ Joseph Smith sí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ni èrò láti múra àwọn obìnrin sílẹ̀ láti “wá sí níní àwọn ànfàní àti àwọn ìbùkún àti àwọn ẹ̀bùn oyè-àlùfáà.” A ó ṣe àṣeyọrí èyí nípasẹ̀ àwọn ìlànà ti tẹ̀mpìlì.

“Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì [ni] àwọn ìlànà oyè-àlùfáà, ṣùgbọ́n wọn kìí [fi] ipò iṣẹ́ ti ẹ̀sìn ìjọ fún àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin. [Àwọn ìlànà wọ̀nyí mú] ìlérí Olúwa ṣẹ pé àwọn ènìyàn rẹ̀—àwọn obìnrin àti ọkùnrin—yíò gba ‘bíbùnni ní agbára láti òkè wá’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:32].”4

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:19–40; 121:45–46; reliefsociety.lds.org

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. M. Russell Ballard, “Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin àti Agbára Oyè-àlùfáà,” Liahona, Sept. 2014, 36.

  2. Elaine L. Jack, ní Àwọn Ọmọbìrin ní Ìjọba Mi: Ìwé Ìtàn àti Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Ìranlọ́wọ́ (2011), 119.

  3. Linda K. Burton, “Agbára Oyè-àlùfáá—Wà ní Àrọ́wọ́tó sí Gbogbo Ènìyàn,” Ensign, June 2014, 39–40.

  4. Àwọn Àkórí Ìhìnrere, “Àwọn Ìkọ́ni ti Joseph Smith nípa Oyè-àlùfáà, Tẹ̀mpìlì, àti àwọn Obìnrin,” topics.lds.org.