2017
Ayọ̀ gẹ́gẹ́bí Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì
August 2017


Ọdọ

Ayọ̀ gẹ́gẹ́bí Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì

Njẹ́ ẹ ti ní ọjọ́ búburú kan rí? Kíni ẹ ṣe láti tújúká? Ààrẹ Uchtdorf mọ̀ pé “ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìrora ọkàn wa, ìjákulẹ̀ wa, ìbànújẹ́ wa. Àní a lè ní ìmọ̀lára àìnírètí àti ìbòmọ́lẹ̀ nígbà míràn.”

Ọ̀nà àbáyọ rẹ̀ ni láti gbé ìgbé ayé tí ó pè ní “ìgbé ayé ọmọlẹ́hìn”: “dúró nínú òtítọ́ kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́.” Nígbàtí a bá tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́, a ó lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, kí a sì sin àwọn ẹlòmíràn—kí a sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ nínú gbogbo rẹ̀! Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Uchtdorf ṣe sọ, “Àwọn ẹni tí ó ngbé ìgbé ayé ọmọlẹ́hìn … ni àwọn tí ìṣe wọn kékèké nmú ìyàtọ̀ nlá wá.”

Gbèro ṣíṣe ìto àwọ ọ̀nà tí ẹ lè fi gbé ìgbé ayé ọmọlẹ́hìn. Fún àpẹrẹ, ẹ lè kọ èrò iṣẹ́ ìsìn kan sílẹ̀ bíi “Ríran òbí kan lọ́wọ́ láti pèsè oúnjẹ́ alẹ́” tàbí èrò kan fún pípa àwọn òfin mọ́ bíi “Gbígbàdúrà fún níní sùúrù síi pẹ̀lú àwọn àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n mi.” Ní ìgbà míràn tí ẹ bá ní ìjákulẹ̀ tàbí ìbómọ́lẹ̀, ẹ yọ ìwé yín jáde, mú èrò kan, kí ẹ sì gbìyànjú rẹ̀!