2017
Igbé ayé Ọmọlẹ́hìn kan
August 2017


Ọ̀RỌ̀ ÀJỌ ÀÀRẸ ÌKÍNNÍ, OṢÙ KẸ́JỌ 2017

Igbé ayé Ọmọlẹ́hìn kan

Ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn ní Ghana, ọ̀dọ́mọdé akẹ́ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì kan tí a pe orúkọ̀ rẹ̀ ní Doe wọ inú ilé ìjọsìn àwọn Ènìyàn Mímọ́ kan fún ìgbà àkọ́kọ́. Ọ̀rẹ́ kan ni ó pe Doe láti wá pẹ̀lú rẹ̀, Doe sì ní iyára láti mọ ohun tí Ìjọ dúró fún.

Àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́ ẹni rere àti oníyãrí tí ó fi jẹ́ pé kò lè ṣàì yàá lẹ́nu pé, “Irú ìjọ wo ni èyí?”

Doe ní ìmọ̀lára ìtẹ́mọ́ra gidi tí ó fi gbèrò pé òun ó kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa Ìjọ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, tí wọ́n kún fún ayọ púpọ̀ jọjọ. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ bí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí nṣe bẹ́ẹ̀, àwọn elérò rere ẹbí àti ọ̀rẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ntakò ó ní gbogbo ọ̀nà. Wọ́n sọ àwọn ohun burúkú nípa Ìjọ wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti yí i lọkàn padà.

Ṣùgbọ́n Doe ti gba èrí kan.

O ní ìgbàgbọ́, o fẹ́ràn ìhìnrere náà, èyí tí ó nkún ìgbé ayé rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. Nítorínáà, ó wọ inú omi ìrìbọmi.

Lẹ́hìnwá, ó gbé ara rẹ̀ sínú àṣàrò àti àdúrà. Ó gba àwẹ̀ ó sì wá agbára Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ayé rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí àbájáde, èrí Doe àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ gbèrú síi ó sì jinlẹ̀ síi. Ní ìgbẹ̀hìn ó gbèrò láti sin ní míṣìon ìgbà-kíkún fún Olúwa.

Lẹ́hìn tí ó padà dé láti míṣọ̀n rẹ̀, ó dọ́rẹ̃ ó sì ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú olùpadàbọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan—èyĩnì gan an tí ó ṣe ìrìbọmi fun ní àwọn ọdún díẹ sẹ́hìn—wọ́n sì ṣe èdidì ìsopọ̀ ní Tẹ́mpìlì Johannesburg South Africa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti kọjá láti ìgbà tí Doe Kaku ti kọ́kọ́ ní ìrírí ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì. Ní igbà náà, ìgbé ayé kò fi ìgbàgbogbo dùn fún un. Òun ti faradà ìpín ìrora ọkàn àti àìnírètí tirẹ̀, nínú èyítí ikú àwọn ọmọ méjì wà—ìbànújẹ́ tí ó jinlẹ̀ nípa àwọn ìrírí wọnnì ṣì tẹ ìwọ̀n wíwúwo púpọ̀ nínú ọkàn rẹ̀.

Ṣùgbọ́n òun àti ọkọ rẹ̀, Anthony, ti tiraka láti súnmọ́ ara wọn àti olólùfẹ́ Bàbá wọn Ọ̀run, ẹnití wọ́n fẹ́ràn pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

Ní òní, ọgbọ̀n ọdún lẹ́hìn tí ó ti wọ inú omi ìrìbọmi, Arábìnrn Kákù láìpẹ́ yìí tún pari ìṣẹ́ ìránṣẹ ìgbà-kíkún míràn—ní àsìkò yí pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ààrẹ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Nigeria.

Àwọn wọnnì tí wọ́n mọ Arábìnrin Kaku sọ pé ohun kan wa tí o jẹ́ pàtàkì nípa rẹ̀. Ó ndán. Ó ṣòro láti lo ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láì ní ìmọ̀lára ìdùnnú púpọ̀ jọjọ fúnra rẹ .

Ẹ̀rí rẹ̀ dájú: “Mo mọ̀ pé Olùgbàlà rí mi gẹ́gẹ́bí ọmọbìnrin àti ọ̀rẹ́ Rẹ̀ (wo Mosiah 5:7; Ether 3:14),” ni ó máa nwí . Èmí náà sì nkọ́ ẹ̀kọ́ mo sì ngbìyànjú kárakára láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Rẹ̀ bákannáà—kìí ṣe nípa ohun tí mo nsọ nìkan ṣùgbọ́n nípa ohun ti mo nṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”

Àwa ni Ọmọẹ̀hìn

Ìtàn Arábìnrin Kaku bá ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn mu. Ó ní ìfẹ́ láti mọ òtítọ́, ó sàn ẹ̀san láti jèrè ìmọ́lẹ̀ ti ẹ̀mí, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run àti ọmọnìkejì rẹ̀ hàn, àti pé ní ojú ọ̀nà ó ní ìrírí ìṣòro àti ìbànújẹ́.

Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí àtakò rí, bí ó ti wù kí ìbànújẹ́ tó, ó tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́. Àti pé gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe pàtàkì tó, ó pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ra. Ó rí ọ̀nà kan kìí ṣe láti faradà ìṣòro ìgbé ayé nìkan ṣùgbọ́n bákannáà láti ṣe àṣeyege ní wíwà pẹ̀lú wọn!

Ìtàn rẹ̀ fi ara pẹ́ ara sí tìrẹ àti tèmi.

Ó ṣọ̀wọ́n kí ìrìnàjò wa lọ tààrà tàbí láìsí àdánwò.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìrora ọkàn tiwa, àwọn ìjákulẹ̀ wa, àwọn ìbànújẹ́ wa.

Àní a lè ní ìmọ̀lára àìnírètí àti ìbòmọ́lẹ̀ nígbà míràn.

Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n ngbé ìgbé ayé ọmọlẹ̀hìn—tí wọ́n dúró lódodo tí wọ́n sì nrìn síwájú nínú ìgbàgbọ́; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tí wọ́n sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́;1 tí wọ́n ngbé ìgbé ayé ìhìnrere lójojúmọ́ àti ní wákàtí-wákàtí; tí wọ́n nfún àwọn tí ó wà ní àyíká wọn ní iṣẹ́ ìsìn bíi ti Krístì, ìṣe rere kan ní àkókò kan—ni àwọn wọnnì tí àwọn ìṣe kéèkèké wọn nmú ìyàtọ́ nlá wá ní ìgbà púpọ̀.

Àwọn wọnnì tí wọn ní inú rere díẹ̀ síi, tí wọn ní ìforíjì díẹ̀ síi, tí wọn sì ní ìfọwọ́tọ́ àánú síi ni àwọn alãnú tí wọn yíò rí àánú gbà.2 Àwọn wọnnì tí wọ́n nmú ayé yí jẹ́ ibi tí ó dára síi, ní ṣíṣe ìtọ́jú àti fífẹ́ni kan ní àkókò kan, àti àwọn tí wọ́n ntiraka láti gbé ìgbé ayé alábùkún, títẹ́lọ́rùn, àti igbé ayé alálàáfíà ti ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì kan ni àwọn wọnnì tí wọn yíò rí ayọ̀ nígbẹ̀hìn.

Wọn yíò mọ pé “ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ó tàn káàkiri ibi gbogbo nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn … ni ó dára ju ohun gbogbo … tí ó sì jẹ́ ayọ̀ tí ó pọ̀ jù sí ẹ̀mí.”3