2017
Gbígbé ìgbé ayé ìyàsọtọ̀
August 2017


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kéje Ọdún 2017

Gbígbé ìgbé ayé ìyàsọtọ̀

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Àwòrán
Relief Society seal

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

“Láti yàsọ́tọ́ ni láti gbé kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ tàbí ya ohun kan sí mímọ́, fífi sí ọ̀tọ̀ fún àwọn èrò mímọ́,” ni Alàgbà D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. “Àṣeyege òtítọ́ ní ayé yí nwá nínú yíya ayé wa sọ́tọ̀—èyíinì ni, àkokò àti àwọn àṣàyàn wa—sí àwọn èrò ti Ọlọ́run.”1

Alàgbà Neal A. Maxwell (1926–2004) ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá wí pé, “A máa nro pé ìyàsọ́tọ́ jẹ́ yíyọ̀ọ̀da, nígbàtí a bá gba ìdarí ti ọ̀run, àwọn ohun ìní wa nìkan. Ṣùgbọ́n òpin ìyàsọtọ̀ náà ni yíyọ̀ọ̀da araẹni fún Ọlọ́run.”2

Bí a ṣe nya ara wa sọ́tọ̀ sí àwọn èrò Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ yíò pọ̀ si. Bí a ṣe ngbé ìgbé ayé ìyàsọ́tọ̀, a lè di mímọ́ nípa àwọn ìṣe wọnnì.

Carole M. Stephens, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, sọ pé: “Alàgbà Robert D. Hales kọ́ni pé, ‘nígbàtí a bá dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú mọ́, a njáde wá láti inú ayé sí inú ìjọba Ọlọ́run.’

“A di yíyípadà. Ìwò wa á yàtọ̀, ìṣe wa á sì yàtọ̀. Àwọn ohun tí à nfetísílẹ̀ sí àti tí à nkà tí a sì nsọ á yàtọ̀, àti pé ohun tí a nwọ á yàtọ̀ nítorí a di àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run tí a rọ̀ mọ́ Ọ nípa májẹ̀mú.”3

Ìyàsọ́tọ̀ ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run ṣe “pẹ̀lú ilé Ísráẹ́lì; Lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọnnì, ni Olúwa wí, èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọọ́ sí oókàn àyà wọn; èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi” (Jeremiah 31:33). Gbígbé ìgbé ayé ìyàsọ́tọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò Ọlọ́run fún wa.

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ

1 Thessalonians 1:3; Doctrine and Covenants 105:5;

reliefsociety.lds.org

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. D. Todd Christofferson, “Reflections on a Consecrated Life,” Amọ̀nà, Nov. 2010, 16.

  2. Neal A. Maxwell, “Consecrate Thy Performance,” Liahona, July 2002, 39.

  3. Carole M. Stephens, “Wide Awake to Our Duties,” Liahona, Nov. 2012, 115–16.

Tẹ̀