2018
Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà
January 2018


Àwọn Ọmọdé

Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà

Ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà kìí ṣe ẹ̀bùn kan tí ẹ lè rí tàbí fọwọ́kàn. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹ̀bùn tí ẹ lè mọ̀lára. Èyí túmọ̀ sí pé nígbàtí a bá ṣe àṣìṣe àṣàyàn, a lè ronúpìwàdà kí a sì ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìdùnnú lẹ́ẹ̀kansi.

Bàbá Ọ̀run àti Jésù yíò fi ìgbàgbogbo ràn wá lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà. Ya àwòrán kan láti lọ pẹ̀lú onirúurú ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan ti ìrònúpìwàdà.

À nní ìmọ̀lára ìkáàánú.

A ngbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Un, a sì nbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ láti ṣe àṣàyàn tí ó dára jù ní ìgbà míràn.

A nbẹ̀bẹ̀ a sì ngbìyànjú láti mú un dára síi.

A nní ìmọ̀lára àláfíà a sì nmọ̀ pé a ti gba ìdáríjì.

Tẹ̀