2018
Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà
January 2018


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kínní 2018

Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà

“Ojúṣe wa ní láti dìde kúrò nínú àìjáfáfá sínu ìjáfáfá, kúrò nínú ìjákulẹ̀ sínú àṣeyege,” Ààrẹ Thomas S. Monson ti kọ́ni. “Iṣẹ́ wa ni láti dà bí a ti lè dára jùlọ tó. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run títóbi jùlọ sí wa ni ayọ̀ ìgbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi, nítorí kò sí aṣìṣe kan rárá tí ó níláti jẹ́ òpin.”1

A máa nfì ìgbàkugbà wo bíbọ̀ ọdún titun kan pẹ̀lú àwọn ìpinnu àti àwọn ìlépa. A npinnu láti dára si, láti yípadà, láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi. Bóyá ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a fi lè gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi ni nípa gbígba ohun tí Ààrẹ Monson pè ní “ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà.”2

Nínú àwọn àyọsọ wọ̀nyí láti inú àwọn ìkọ́ni rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti di Ààrẹ Ìjọ, Ààrẹ Monson gbà wá ní ìmọ̀ràn láti “lo ètùtù ẹ̀jẹ̀ Krístì kí a lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti kí ọkàn wa lè gba ìwẹ̀nùmọ́.”3

Ìyanu Ìdáríjì

“Gbogbo wa ni a ti ṣe àwọn àṣàyàn tí kò dára. Tí a kò bá tíì tún àwọn àṣàyàn náà ṣe, mo mu dáa yín lójú pé ọ̀nà kan wà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ètò náà ni à npè ní ìrònúpìwàdà. Mo bẹ̀ yín láti tún àwọn àṣìṣe yín ṣe. Olùgbàlà wa kú láti pèsè ẹ̀bùn alábùkún náà fún ẹ̀yin àti èmí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipá ọ̀nà náà kò rọrùn, ílerí náà jẹ́ òtítọ́: ‘Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n, wọn yíò di funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú’ [Isaiah 1:18]. ‘Èmi, Olúwa, kì yíò sì rántí wọn mọ́’ [D&C 58:42]. Ẹ máṣe fi ìyè ayérayé yín sínú ewu. Tí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe tètè bẹ̀rẹ̀ síí nwá ọ̀nà padà, ni ẹ ó fi tètè rí adùn àláfíà àti ayọ̀ tí ó nwá pẹ̀lú ìyanu ìdáríjì.”4

Ẹ Padà sí Ipá Ọ̀nà náà

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí a máa yàn pẹ̀lú ọgbọ́n, àwọn ìgbà míran wà nígbàtí a ó ṣe àwọn àṣàyàn òmùgọ̀. Ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà, tí Olùgbàlà wa pèsè, njẹ́ kí a ṣe àtúnṣe àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀nà wa, kí a lè padà sí ipá ọ̀nà èyí tí yíó darí wa sí sẹ̀lẹ́stíà ológo tí à nwá.”5

Ọ̀nà Lati Padà

“Tí ẹnìkẹ́ni lára yín bá ti kọsẹ̀ nínú ìrìnàjò rẹ, mo mu dáa yín lójú pé ọ̀nà kan wa láti padà. Ètò náà ni à npè ní ìrònúpìwàdà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipá ọ̀nà náà ṣòrò, ìgbàlà ayérayé yín gbé lé e lórí. Kíni ohun tí ó lè yẹ síi fún àwọn ìtiraka yín? Mo bẹ̀ yín láti pinnu níhĩnyìí àti nísisìnyí láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe dandan láti ronúpìwàdà ní kíkún. Bí ẹ bá ti tètè ṣe bẹ́ẹ̀ sí, ni ẹ ó fi tètè lè ní ìrírí àláfíà àti ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdánilójú tí Ísáíàh sọ̀rọ̀ nipa rẹ̀ [wo Isaiah 1:18].”6

Àwọn Ènìyàn Lè Yípadà

A nílò láti ní ìfaradà nínú ọkàn wa pé ènìyàn lè yípadà. Wọ́n lè gbé àwọn ìwà burúkú wọn ti sẹ́hìn. Wọ́n lè ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ìwà ìrékọjá wọn. Wọ́n lè nífaradà yíyẹ fún oyè àlùfáà. Àti pé wọ́n lè fi taratara sin Olúwa.”7

Dí Mímọ́ Lẹ́ẹ̀kansi

“Tí ohunkan bá wà tí kò tọ́ nínú ayé wa, ọ̀nà àbáyọ kan ṣí ṣílẹ̀ fún yín. Dáwọ́ gbogbo àìṣòdodo dúró. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù rẹ. Ohunkóhun tí wàhálà náà lè jẹ́, ẹ lè ṣiṣẹ́ lée lórí nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà tó yẹ. Ẹ lè di mímọ́ lẹ́ẹ̀kansi.”8

Ipa Pàtàkì ti Olùgbàlà

Kókó sí ètò náà ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Láìsí ètùtù ìrúbọ Rẹ̀, gbogbo ohun yíò sọnù. Kò tó, bákannáà, lásán, láti gbà Á gbọ́ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. A nílò láti ṣiṣẹ́ àti láti kọ́ ẹ̀kọ́, ṣe ìwákiri kí a sì gbàdúrà, ronúpìwàdà kí a sì ṣàtúnṣe si. A nílò láti mọ àwọn àṣẹ Ọlọ́run kía a sì pa wọ́n mọ́. A nílò láti gba àwọn ìlànà ìgbàlà Rẹ̀. Ní ṣíṣe èyí nìkan ni a lè gba, ìdùnnú ayérayé òtítọ́.”9

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Ìfẹ́ Ti Inú,” Ensign, May 1987, 68.

  2. “Àwọn Àṣàyàn,” Liahona, May 2016, 86.

  3. Mòsíàh 27:14

  4. “Àwọn àṣàyàn R mẹ́ta,” Liahona, Nov. 2010, 69.

  5. “Àwọn àṣàyàn,” 86

  6. “Pa àwọn Òfin mọ́,” Amọ̀ná, Oṣù Kọkànlá. 2015, 85.

  7. “Rí Àwọn Míràn bí Wọ́n Ṣe Lè Dà,” Liahona, Nov. 2012, 68.

  8. “Agbára Oyè Alùfáà,” Liahona, May 2011, 67.

  9. “Ọ̀nà pípé sí Ìdùnnú,” Liahona, Nov. 2016, 80–81.

Tẹ̀